Bo tile je pe erongba awon obi omo min in ni lati wa
owo ti won yoo fi ran awon won ni lesini lakoko isinmi ti won wa yii, sugbon ti
won ko lagbara e, amo bayii,erin ti bere si nii pa eeke won, nitori bi oludije
fun ipo gomina labe egbe oselu UPN, Omooba Rotimi Paseda se seto naa lofee to
si ti bere.
Lojo aje Monde ose yii ni won bere eto eko naa lofe
nibi tawon omoleewe bi egberun lona merin ti n jafaani e kaakiri ipinle Ogun,
bi won si ti n kekoo naa bee ni won tun fun won ni iwe ati ikowe lofee.
Gege bi BO SE RI se gbo, won ni okan lara erongba
Omooba Rotimi Paseda lati rii pe eto eko di irorun fawon omoleewe,gege bi Oloye
Obafemi Awolowo se se nigba to wa laye lo mu koun naa rawole eto bee, Ona meedogun la gbo pe won yara ikekoo awon omoleeewe
naa si lawon bii Abeokuta, Ijebu Ode, Omu Ijebu, Yewa atawon ibo min in, gbogbo
ibe naa si lawon oluko ti won gba lati wa da won lekoo naa wa.

Opo awon omoleewe naa lo so foniroyin wa pe bi Paseda
ba le di gomina lodun 2019 awon mo pe eko yoo di irorun fawon, bee ni won so pe
bawon se je omo kekere to, awon setan lati bere ipolongo fun okunrin naa,
nitori o n fee ilosiwaju rere.
Nigba ti Rotimi Paseda ba oniroyin wa soro, o seleri
pe gbogbo igba tawon omo naa ba ti wa nisinmi niruu eto bee yoo maa waye.
No comments:
Post a Comment