Awon egbe odo kan nile Yoruba lawon ti
setan lati sise po peluu egbe oselu UPN fun ti ibo to n bo lodun 2019.

Atejade yii jade nibi ipada tawon odo
naa se niluu Eko eyi ti eni to je alakoso fegbe awon odo naa to tun je aare
egbe fegbe awon odo lorile ede yii iyen YYCN, Ogbeni Oluwole Eric gbe jade
lakoko ti won ba oniroyin soro.
O ni ipinnu tawon fi gbe akori pe
egbe odo fee gba ile igbimo asofin ni lati koja ija sawon ipenija to ti wa nile
nidi oselu ati lati satunse eto oselu nile Nigeria.
Aare egbe naa tun so pe awon pinnu
lati sise po peluu egbe oselu UPN, nitori awon gba gege bi egbe oselu to ni
nnkan se peluu awon odo.
Ati pe ilana ti Oloye Obafemi Awolowo
fi sile ninu egbe naa lakoko to koko da sile,si wa sibe,tawon to wa nibe ni
ipinnu lati maa tele.
Awon nii eto eko ofe, ilera ofe,ipese
ise fawon ti ko nise,ati idagbasoke lawujo. Bakan naa lo tun gboriyin fawon omo
ile igbimo asofin niluu Abuja lori awon abadofin tuntun ti won sese gba
wole,eyi to ni se peluu awon odo.
Lara awon to tun soro nibi ipade
oniroyin naa ni Otunba Soji Adeyemi ninu oro e lo ti bu enu ate lu awon
oloselu orile ede yii fun bi won ko se faye gba awon odo lati kopa to joju,eyi
to si n mu ifaseyin ba eto oselu wa.
O so pe ise pupo lo wa niwaju awon
odo ti won ba setan lati gbakoso oselu lowo awon ti won korin bamu bamu lawon
yo, awon ko mo pe ebi n pa omo enikan.
Gbogbo ara lo ni awon odo fee fi
satileyin ati ifowosopo peluu egbe oselu UPN lorile ede yii, bee lo tun lawon
ti seleri lati sise po peluu odo to ba nifee lati dije fun ipo ninu IBO odun
2019.
Nigba toun soro nibe,alaga fegbe
oselu UPN lorile ede yii, Ojogbon Bankole Okuwa gboriyin fawon odo fun igbagbo
ti won ni si egbe oselu naa lati bawon sise po.
O wa seleri lati gbakoso egbe naa le
won lowo niwongba ti won ba pinnu lati sakoso e lorile ede yii.
O wa kede pe ofe lawon odo to ba wa
labe egbe odo fee gbakoso ile igbimo asofin yoo gba tikeeti ti won ba fee dije
fun ibo to n bo yii.
No comments:
Post a Comment