Oludije fun ipo gomina labe egbe
oselu APC to tun je okan lara awon omo ile igbimo asofin niluu Abuja, Seneto
Solomon Adeola tinagije e n je Yayi ti so pe Yewa kii se eya to kere julo gege
bawon kan se maa n wi pe won ko po, o ni aimokan lo n se iru awon to ba n so
bee.

O soro yii lakoko to n se idanilekoo
lopin ose to koja nibi apero tawon omo Yewa se niluu London, eyi ti akori e da
lori idagbasoke ile Yewa,
isiro ipa tisejoba n ko.
O ni igbimo ote to n waye lagbaye ti
je ki adinku maa de ba awon omo Yewa, topo won si n file won sile nipinle
Ogun
Yayi tun so pe " Bi a ba ka wo
opo awon omo Yewa ni won wa nile Benin,nibi ti Ipokia, Yewa South,Yewa
North ati Imeko Afon ti ba won paala po.Bee lawon kan tun ba awon bi ipinle Oyo
naa paala. Ewekoro, Ifo ati ijoba ibile Ado Odo
Ota tun wonu ara won."
O tun so pe peluu eto ikaniyan to
waye lodun 2006,o ni orisirisi lawon abajade ti won gbe jade nipinle
Ogun, eyi to da lori awon Ekun ti won pin in si.
Adeola tun so di mimo pe iha tawon
isejoba n ka nipa ipinpo tun je okan lara awon nnkan to mu ifaseyin ba
idagbasoke soke ile Yewa,ti ko si ye ko ri bee.
O ni idagbasoke to n de ba Ogun East
ati Ogun Central ko se leyin awon to ti se gomina lati odo won wa peluu awon
ise akanse ti won se sibe.
Nigba to n fi aidunnu e han, Seneto
Adeola so pe bi Yewa ko se tii je gomina lati bi odun mejilelogoji seyin je eyi
to ba ni lokan je, o ni bi won ba le fun won laye lati di gomima lodun
2019,anfaani nla ni o so pe yoo je ti idagbasoke yoo si de bawon.
Aare egbe Yewa Descendants Union ti
won wa niluu Oyinbo ti won tun sagbateru apero naa so pe akori won lodun yii ni
lati so n fawon to wa loke okun pe ki won fowosowopo peluu awon to n sejoba
lati wa abayori sawon nnkan to ba n sele.
Lara awon to wa nibe lojo naa Ogbeni
Suraj Adekunbi Isola, olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, Alaaji Gboyega
Nasir Isiaka, Ojogbon Rahaman Bello, Ojogbon Tope Popoola, Oba Kehinde
Olugbenle, olu Ilaro ati Oba ile Yewa atawon min in.
![]() |
No comments:
Post a Comment