Ile ejo giga nipinle Ogun ti da
Oba Nojeemdeen Alani Eyiowuawi Alani-Adebari, Ilufemiloye Obayemi Arolu 1,
Oniro of Iro-Egbaland pada sori oye e gege bi Oba ilu naa nijoba ibile
Obafemi Owode nipinle Ogun
Bakan naa loba naa tun sayeye odun
keta to dori oye nibi tawon araalu naa ti forin soko oro sawon olote.
Koda titi di akoko yii ni inu awon
eeyan naa si dun peluu bi won se da oba naa pada sori ite awon baba e.
Ninu leta ti Adewumi Dolapo to je
alakoso foro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun fowo si loruko akowe ijoba
fun ileese naa lojo kejidinlogbon osu keta odun yii lo ti so pe peluu ase ile
ejo giga ti Onidajo Mobolaji A. Ojo ati peluu amoran lati ileese eka eto
Idajo, eyi to pa lase lati odo komisanna wa lati da Oba naa pada gege
bi Oniro tiluu Iro titi idajo yoo fi waye lori awon esun to wa nile naaa lori
oro oloba de.
Sugbon Oba Oniro naa
ti so di mimo pe idajo naa waye fun ifokanbale ati itelorun koun fi le te
siwaju ninu ise idagbasoke toun se siluu naa lowo.
Oba Nojimu Eyiowuawi tun so pe oun
ko ni ikunsinu kankan peluu awon omo ilu naa bo tile je pe oun mo pe awon
alagbara kan lo fee maa lo owo agbara won, amo ti Olorun ju won loo.
O wa ro awon araalu e lati je ki
won jo maa gbe ni irepo ari isokan nitori ote ki n tun nnkan se,o maa n balu
je ni.
Nibi ayeye odun keta naa lawon
eeyan jakanjakan lawujo ti wa ba sayeye naa.
|
Wednesday, 22 November 2017

Home
Unlabelled
Oba Oniro sayeye odun keta lori oye,ni won ba fawon ota se yeye
Oba Oniro sayeye odun keta lori oye,ni won ba fawon ota se yeye
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Author Details
Je gbajumo oniroyin lorileede Naijiria, o ti ko ipa ribiribi lagboole iroyin, paapaa l'eka ede Yoruba.
No comments:
Post a Comment