Oloye Bayọ Dayọ, alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, to ṣẹṣẹ fẹ kogba wọle ti pẹjọ kotẹmillọrun lori idajọ kan to wa ni kootu giga kan niluu Ijẹbu Ode, lọsẹ to kọja nibi ti Adajọ to n gbẹjọ to pe Buruji Kashamu ati igbakeji ọga agba fawọn ọlọpaa ti ẹkun keji ti fagile ẹjọ naa.
Lọjọ Mọnde, ọsẹ yii ni Oloye Bayọ Dayọ gba ileẹjo kotẹmilọrun
to wa niluu Ibadan pe bi Adajọ to gbẹjọ
naa iyẹn O S Olusanya, ṣe fagile ẹjọ toun pe naa ko tẹ oun lọrun, oun si fẹẹ kawọn
Adajo kotẹmilọrun naa wo ẹjọ naa daadaa, ki wọn si ṣe idajọ to yẹ le lori.
Ninu iwe ẹjọ naa ti nọmba ẹ jẹ NCJ/64/2020 ni lawọn ko ti
gba ọna ti Adajọ naa gba fagile ẹjọ naa paapaa ni abala kẹta iwe ipẹjọ ọhun. Ti
wọn si rọ ile ẹjọ naa lati jẹ ki igbẹjọ waye lori ti abala kẹrin iwe naa.
A o ranti pe Oloye Bayọ Dayọ ati ọmọ ẹ lo pe Buruji Kashamu ati igbakeji ọga
ọlọpaa ti ẹkun keji lẹjọ lori ọna meji ọtọọtọ, akọkọ ni lati ma jẹ ki Buruji
Kashamu fọlọpaa mu awọn tabi ti wọn mọle lori ẹjọ to fi sun.
Ẹlẹẹkeji ni pe
olujẹjọ, iyẹn Kashamu fẹẹ lodi si ofin to nii ṣe omininira ọmọniyan ati dukia
ti ko si yẹ ko ri bẹẹ ṣugbon ṣe ni Adajọ naa fagile ẹsun mejeeji, idi niyii ti
Dayọ Bayọ ṣe gba korẹmilọrun lọ pe igbesẹ Adajọ to fagile ẹjọ naa ku diẹ kaato, oun ko gba.
Ni bayii, ileẹjọ kotẹmilọrun to wa ni Ibadan, si ti tẹwọgba
iwe ipẹjọ naa, ti iṣẹ si ti bẹrẹ lori ẹ kiakia.
No comments:
Post a Comment