Ọmọọba Adewọle Adebayọ, oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP, ninu ibo ti yoo waye ninu oṣu kẹta ọdun yii ti sọ pe bi Oloye Ọbasanjọ ṣe wa lẹyin Peter Obi, ti ẹgbẹ oṣelu Labour, iyẹn ko sọ pe ki oun ma jawe olubori ninu ibo ọhun.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to pari ipade pẹlu Oloye Ọbasanjọ lẹyin to ṣabẹwo sọdọ ọ, o ni oun ko ri i ro rara ko si di aṣeyọri oun lọwọ.O ni aarẹ orileede yii tẹlẹ jẹ baba gbogbo wọn, idi niyii toun fi wa fun atilẹyin pẹlu iwure lẹnu agba.
O fikun ọrọ ẹ pe o da oun loju pe oun yoo fidi Peter Obi, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati Atiku Abubakar, janlẹ nitori pe ẹgbẹ oṣelu SDP, nikan lo le wa ọna abayọ si isoro to n koju orileede yii lori ijakulẹ eto aabo ati ọrọ aje.
O sọ pe, ‘’ Mo ṣabẹwo wa si ọdọ gẹgẹ bi baba orileede, to ti sin orileede wa fun ọpọ ọdun,koda ka ni ẹnikan wa to yẹ ki wọn maa pe ni Misita Naijiria,baba lo yẹ bẹẹ, Nitori idi eyi, mo waa ba wọn sọrọ nipa ọjọ iwaju, paapaa julọ mo wa si ipinlẹ Ogun, lati ṣe ipade ita- gbangba, bẹẹ ni mo ti ri awọn ọba alaye,ẹyin naa si mọ pe mi o le wa sibi bayii ki n ma foju kan baba, awa la n nilo imọ ati ọgbọn wọn, nipa iṣejọba’’
Oludije aarẹ ọhun to wa pẹlu Tony Ọjẹṣina, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP, nipinlẹ Ogun ati alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ naa, Yinka-Ola Williams, ṣeleri pe oun yoo ri i pe iṣẹ oun iya dopin bi wọn ba foun laaye lati wọle ibo to n bọ naa.
O ni gẹgẹ bi Ọbasanjọ ṣe jẹ olori orileede, to si tun jẹ ọmọ Naijiria, o lẹtọọ lati lọ sibi to ba wuu, nitori idi eyi awọn ko rii ro ati pe idibo si jinna diẹ. O ni ara eto ijọba tiwa-n-tiwa ni lati ba awọn eeyan sọrọ lati yi ọkan wọn pada.
O waa sọ pe bawọn ba tiẹ jawe olubori ninu ibo naa awọn nilati dunadura pẹlu awọn ọmọ Naijiria. Awọn gbọdọ waa awọn eeyan ti wọn ki i ṣe tawọn tẹlẹ pada di ti wọn.
O sọ pe,’’ Ninu ọrọ ti baba Ọbasanjọ ba wa sọ, o ni a nilati jẹ ki ẹgbẹ wa yii tun lagbara si,ọna otitọ la wa, a si mu ninu ero baba pe ẹgbẹ oṣelu to ti tẹlẹ ko le yanju iṣoro wa a fi awọn tuntun, a si ni lati sa agbara wa, toun naa si n fẹ bẹẹ, to si ṣeleri fun wa oun ṣetan lati ṣatilẹyin fun wa, to ba jẹ pe awa naa la wọle ninu ibo ọhun’’K
Ko to to akoko yii, ni Ọmọọba Adewọle Adebayọ, tii sabẹwo lọ sọdọ awọn ọba alaye mẹta nilẹ Ẹgba, awọn naa ni Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, Olowu tilu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla, ati Olubara tilu Ibara, Ọba Jacob Ọmọlade, nibẹ lo ti lọ bẹbẹ fun atilẹyin ati iwure lẹnu wọn.
No comments:
Post a Comment