Laipẹ yii ni Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, rin irianjo lọọ si orileede Brazil, nibi to ti bawọn kopa fun ayẹyẹ ibura aarẹ tuntun yti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, iyẹn Lulla. Bẹẹ lo si kopa ninu awọn eto ti wọn ṣe lọhun. Ni bayii Ọkunrin naa ti pada de si orileede yii, o ba oniroyin wa sọrọ nipa ẹkọ to ri kọ lorileede naa ati aṣepọ to wa laaarin oun ati aarẹ naa.
Bawo lẹ ṣe mọ Lulla?
Eeyan mi ni Lulla, igba to wa lẹwọn mo lọ ri, igba to fẹẹ ṣe ipolongo, o ranṣẹ pe mi pe ki n wa wo o, igba to jawe olubori to di aarẹ, wọn mọ ọn mọ fiwe ranṣẹ pe mi pe ki n wa bawọn ṣe ninu ayẹyẹ wọn. Ki a le jọ sọrọ bi ọjọ ọla yoo ṣe ri,laarin ilu ti wa ati ti wọn. Ati bi ijọba dẹmokireesi yoo tun ṣe fẹsẹ rinlẹ laaarin awa mejeeji.
Iru eeyan wo ni Lulla?
Jagbagba jagbagba ọkunrin ni Lulla, ẹni to jẹ pe gbogbo ọjọ ọla ẹ, bi ọjọ iwaju awọn mẹkunnu yoo ṣe ri, lowa lọkan ẹ, Ohun kan to maa n tẹnu mọ ni pe anfaani kan soso tijọba ni ko ju pe ko maa wa igbe aye irọrun fawọn mẹkunnu. Igbagbọ ẹ ni pe bi ilu ba dara awọn olowo mọ bi wọn yoo ṣe yanju ara wọn, bijọba ko ba sii dara, wọn yoo wa ọna abayọ si ara wọn. Bi o ṣe maa n sọrọ, iru igbesẹ to n gbe ati ifẹ to ni si adulawọ, oun lo jẹ ki ọrọ ẹ bẹrẹ si nii ma wọnu ọkan mi. O si dagba, mo wa lọ ba a pe gbogbo aye ti mọ bo ṣe n lọ o, ṣe awa naa le kọ, ki o la wa loye ati amọran lọdọ ẹ, bo ṣe di pe a di baba ati ọmọ, ọrẹ,ọga ati ẹni to kọ ọmọ ẹ niṣẹ. Inu mi dun gan-an ni
Bawo gan-an ni ẹ ṣe mọ Lulla?
Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ti a padanu ibo,tawọn naa padanu ibo, ibo ti wọn yẹn, bawo lo ṣe pọ to bẹẹ,awọn ni miliọnu lọna aaadọta, awọn igbakeji wọn ni miliọnu mejilelaaadọta, mo wa n beere bawo ni ero to pọ ṣe jade, nnkan to gbe mi delu naa niyẹn.
Nigba ti mo de Brazil, mo kọ lẹta si Brazillian Workers Party, ti wọn dabi alatako nilu ti wọn, awọn ni mo lọ ba pe ki wọngba mi, bawo lawọn eeyan ṣe n tu jade dibo niluu tiyin, tawọn eeyan ki i tu jade niluu tiwa.
Nigba naa lọhun Lulla wa ni ẹwọn, awọn eeyan ẹ wa ni o yẹ ki a le lọ wo ni ẹwọn, awa bẹrẹ si nii kọ lẹta lati jẹ ki a ri amọ awọn ijọba ko fun wa ni esi lati lọọ ri. O wa ran mi si Baba Ọbasanjọ pe ṣe ko ni ki oun ni, nigba ti mo de, mo lọọ jẹ abọ fun baba.
Nigba ti wọn wa fi silẹ, mo tun pada lọ silu yẹn, ibẹ ni a ti wa di baba ati ọmọ. Eyi tun jẹ ki aarin wa ki o gun. Rege, ko si to wọle lawọn eeyan ibẹ wa ta a ti jọ mọ ara wa. Ti ọrọ ba ri bakan lọdọ wọn a beere pe kin ni mo ri si, igba mii-in si wa temi naa maa n beere pe kin ni wọn ri si ọrọ temi naa. Titi Ọlọrun fi jẹ ki aarin wa dun, ko si eeyan kan nibẹ ninu ijọba wọn ti ko ṣe pe o jẹ ọrẹ mi laye ọtọ, ti wọn si tun wa ko sinu ijọba wọn lọhun.
Mo tun ri pe lọdọ wọn, ọna ti wọn gba n to ijọba wọn dun pupọ ju, ṣugbọn ọrọ naa, ọjọ mii in ni, ti mo maa ṣalaye lee lori.Ọjọ ti wọn bura fun aarẹ wọn, ọjọ keji naa ni wọn bura fawọn minisita wọn. Mo wa beere pe bawo ni wọn ṣe tete yan wọn minisita yẹn, idahun wọn ni pe ẹgbẹ to ba ṣiṣẹ, inu ẹ lawọn yoo ti mu awọn ti yoo ba wọn ṣejọba, wọn ko dabi tiwa tawọn oloṣelu maa ṣiṣẹ tan, ta a wa ṣẹṣẹ maa wa awọn kan ti wọn jokoo ninu ile lati wa bawon ṣejọba.
Bawo lẹ ṣe ri awọn iran Yoruba to wa nibẹ?
Iran Yoruba to wa nibẹ pa gan-an ni, niluu naa awọn kan sin Ọlọrun nilana katoliki, awọn mii-in naa n ṣe nilana to yatọ, amọ eyi to fi bẹẹ wọpọ, ti o tobi, , mi o sọ pe o tobi naa o ni ẹsin abalaye. Iyẹn ẹṣin oriṣa, bi Sango, Ọbatala, Ogun, wọn gbe sori gan an ni o, wọn gba pe ọna ti Yoruba n gba sin Ọlọrun ati ti wọn, o tẹ wọn lọrun ju. Wọn nibi kan to jẹ pe awọn Yoruba lo pọ nibẹ, igbagbọ wọn ni pe awọn eeyan wọn to wa da ilu ti wọn wa silẹ ọmọ Yoruba ni wọn.
Bi a ti n jẹ akara lawọn naa jẹ ẹ, bo tilẹ jẹ pe akarajẹ ni wọn pe e lọdọ wọn. Awọn tiẹ n jẹ gaari ju, bi wọn ba jẹ irẹsi, wọn a wọn gaari si, bo jẹ ẹwa ni bakan naa ni wọn a fi gaari jẹ. Iṣe wọn ati iwa wa fẹẹ sunmọ ara wa, iyẹn naa tun wa lara awọn nnkan ti mo lọ wo pe bawo ni wọn ṣe ṣe e.
Ẹkọ wo lẹ wa ri kọ bọ lati Brazil?
Ẹkọ ti mo kọ bọ, ẹ o bẹrẹ si ni rii, mo n bawọn olori wa naa sọ ọ, ti mo ba lọ, ti mo ba bọ, eleyii wọn pe aarẹ, wọn pe oludije aarẹ PDP, ti wọn fiwe pe e, ti wọn palẹmọ gidi,ẹyin naa si mọ akoko ti a wa yii, ọna pọ, amọ mo gbiyanju niwọnba ti ara mi, mo ṣe ojuṣe aarẹ Naijiria, aṣọ kampala ni mo wọ lọ, ti wọn n wo imura mi.
Mo tun sakiyesi pe o ku ọsẹ meji ti wọn yoo bura fun aarẹ wọn, ni wọn ti bura fawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin wọn. Mo wa beere pe ki lo de, wọn ni tawọn ko ba ṣe bẹẹ, iṣẹ wo lawọn aṣofin fẹẹ ṣe silẹ fun aarẹ to yoo fi bẹrẹ iṣẹ.
No comments:
Post a Comment