Gbajumọ oṣeere nni, Alaaji Waheed Ijaduade, tọpọ mọ si Dimeji, ti ṣapejuwe iyawo ẹ, Iyaafin Aderẹmi Wuraọla Ijaduade, to jade laye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2022, gẹgẹ bi aya rere to duro ti ọkọ ẹ, ti ipa ẹ ninu aye oun ko ni ṣe e gbagbe.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lati ilu oyinbo nipa iyawo e to jẹ ipe Ọlọrun naa. Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ko si nnkan to ṣe obinri n naa koda wọn sọ pe o lọ ṣọọbu lọjọ kejidinlogun, iyẹn mọjumọ ọjọ to jade laye ọhun.
Ijaduade gan-an jẹri si i pe ọgbọn iṣẹju to maa dagbere faye awọn si sọrọ lori foonu, nigba to wa ni ṣọọbu, oun loun sọ fun un pe ko maa lọ sile pe ilẹ ti su, nitori oun ti kilọ fun un pe ti ko ba ti gbe mọto jade, ko ma rin irin alẹ.
O ṣalaye siwaju pe, ‘’ Gbogbo bi a ṣe n sọrọ lori foonu, ko fi ami kankan han pe nnkan ṣe oun, ọrọ to ba mi sọ lori foonu gbẹyin ni pe ki n jẹ ki oun wọle, toun ba ti wọ palọ, oun yoo pe mi pada.Bi ọkan ninu awọn ọrẹ mi, iyẹn Ṣeyi Crown, ṣe pe mi niyẹn pe awọn ti gbe iyawo mi lọ si ọsibitu jẹnẹra, pe wọn ko gba a ni ọsibitu Lantoro’’.
Ijaduade waa ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi obinrin rere to duro ti ọkọ ẹ, o ni bo tilẹ jẹ pe bi ala niku ẹ si n jẹ foun, nitori ko sọ pe nnkankan ṣe oun ni gbogbo igba tawọn fi jọ sọrọ, amọ ohun gbogbo ye Ọlọrun.
Ogunjọ, oṣu to kọja yii ni wọn sinku ẹ nilana musulumi nigba ti wọn ṣe adura ọjọ mẹjọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja, nile ẹ to wa ni Abẹokuta. Nibi tawọn ara,ọrẹ ati ojulumọ ti peju pejọ wa nibẹ, ti wọn si sẹyẹ ikẹyin fun-un.
Ọmọ meji, Lateef Ijaduade ati Hassan Ijaduade ni obinrin naa fi silẹ saye lọ. Lọrọ kan Dimeji sọ pe adanu nla niku iyawo ẹ yii jẹ foun.
No comments:
Post a Comment