Ẹ dibo yin fawọn aṣaaju to ni ibẹru Ọlọrun-Ọba Odugbemi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 4 January 2023

Ẹ dibo yin fawọn aṣaaju to ni ibẹru Ọlọrun-Ọba Odugbemi

           
           


           
             

Olu tiluu Lisa, Ọba Ọladele Odugbemi, ti rọ gbogbo ọmọ orileede yii pe bi eto idibo lati yan awọn aṣaaju tuntun ṣe n sunmọ, ki wọn rii pe wọn dibo wọn fun awọn to ni ibẹru Ọlọrun

Kabiyesi gba wọn nimọran ninu iṣẹ ọdun to fi ki gbogbo awọn eeyan fun ti ọdun tuntun ta a ṣẹṣẹ wọnu ẹ yii. O ni ki wọn dibo wọn fẹni ti wọn ba mọ pe o le mu ayipada rere ba orileede yii, ti yoo si gba wa kuro ninu aburu to n fojoojumọ koju wa, bẹẹ lo tun rọ wọn ki wọn ma ṣe tori owo dibo lakooko yii.

O ran awọn araalu leti pe ọwọ wọn ni ọjọ iwaju orileede yii nipa ibo gbogbogboo ti wọn fẹẹ di na, nitori akoko ta a wa yii nnkan ti orileede n wa bayii ni awọn aṣaaju rere ti wọn yoo mu igba rere wa, ti yoo wa atunṣe si bi ọrọ aje wa ṣe dẹnukọlẹ.

Bakan naa lo tun rọ ijọba lati ori ijọba ibilẹ de apapọ lati wa iyanju si eto aabo to mẹhẹ ati ọwọngogo ti ounjẹ gbowo lori lakooko yii paapaa julọ epo pẹtiroolu, ti ko jẹ ki igbe aye rọrun fawọn araalu.

Bẹẹ lo gbawọn ni amọran lati rii pe wọn ṣe awọn eto ti yoo mu irọrun bawọn araalu, ti yoo si fi wọn lọkanbalẹ lori idokjukọ ti wọn koju lori aabo ati ọrọ aje. Bẹẹ lo tun gba awọn oloṣelu nimọran lati yẹra fun oṣelu ẹtanu, ki wọn si sa fawọn nnkan to le da rogbodiyan nigba ti ipolono ba n lọ lọwọ.

  Ọba Odugbemi tun wa kesi ajọ eleto idibo INEC, lati ma ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan ki wọn si ṣeto ibo lọna ti yoo mu irọrun wa. Bẹẹ lo tun gba awọn oniroyin nimọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi ofin ba ṣe laa ṣilẹ fun wọn.

Olu tiluu Lisa wa rọ gbogbo awọn eeyan ẹ,lati maa gbadura fun idagbasoke ilu naa, o ni adura wọn ṣe pataki lakooko yii ati fun orileede Naijiria lapapọ o wa mu dawọn loju oun yoo tẹsiwaju lati maa tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ idagbasoke toun ṣe siluu naa.

Bẹẹ lo rọ ijọba ipinlẹ Ogun lati ran wọn lọwọ lori atunṣe ọna Ijoko- Oluke- Oyero- Lisa, eyi ti wọn ti n pe akiyesi wọn si lati bi ogun ọdun sẹyin.

 

 

 

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages