Ko sẹni to lẹnu nibẹ ninu awọn ta a jọ dupo aṣoju-ṣofin fẹkun Abẹokuta South- Ọnarebu Micky Kazzim - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 29 January 2023

Ko sẹni to lẹnu nibẹ ninu awọn ta a jọ dupo aṣoju-ṣofin fẹkun Abẹokuta South- Ọnarebu Micky Kazzim



Ọnarebu Micky Kazzim, to ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin, to tun wa n dije fun ipo aṣoju-ṣofin, labẹ ẹgbẹ oṣelu Allied People's Movement (APM), fun ẹkun Abẹokuta South, ti sọ pe ọrọ ti ẹnu kọ, bẹẹ oun ko fi ṣe igberaga, oun loun koju oṣuwọn ju ninu gbogbo awọn ti wọn jọ jade dupo naa ni ẹkun naa.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ lopin ọsẹ to kọja, o sọ pe loootọ loun ko dipo kankan mu ninu oṣelu lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, sibẹ ọpọ awọn eeyan ni Ọlọrun ti lo oun fun lagbegbe wọn lati ran wọn lọwọ, to si tun jẹ pe bi wọn ba lọ wo awọn akọsilẹ oun atawọn iriri toun ti ni, awọn eleyii gan –an ti to foun lati dupo ọhun.

 

Ọkunrin to jade iwe ni yunifasiti Stirling, niluu oyinbo, tun ṣalaye pe gbogbo iriri oun nile igbimọ aṣofin to kọja, tun foun lanfaani lati jẹ kawọn to siyemeji tẹlẹ gbagbọ pe oun kọja gbogbo nnkan ti wọn n ro.

 

Ẹni to ti figba kan jẹ aṣoju fuun ẹkun Abẹokuta North/Ọbafẹmi Owode ati Ọdẹda,tun fikun ọrọ ẹ pe bi oun ṣe jade ni Abẹokuta South, lọtẹ yii ni lati le jẹ kawọn ohun idagbasoke tun gbooro si fawọn eeyan ẹ.

 

O sọ pe, ‘ Bi mo ṣe waa dije ni Abẹokuta South, jẹ bawọn eeyan mi ṣe ni ki n wa jade lati fi le tun mu igbega ba ṣiṣe ofin, imuayedẹrun koda idagbasoke,ipese ọrọ ati fawọn ọdọ niṣẹ ti wọn yoo fi wulo fun ara wọn’’

 

Lati le jẹ kawọn eeyan agbegbe Abẹokuta South le mọ pe loootọ ni igbe aye awọn eeyan ẹ jẹ oun logun, o ti fọwọ si ọpọ awọn iṣẹ akanṣe kan ti yoo mu inu awọn eeyan dun lagbegbe naa. Labala idagbasoke awọn ọdọ, ileewe alakọọbẹrẹ mẹfa ọtọọtọ lo sọ ọ di mimọ pe oun kọ, ti atunṣe si ba awọn mi-in ninu wọn. Awọn ileewe naa ti di lilo bi Micky ṣe wi,ni Guusu Abẹokuta yii naa si ni.

Awọn mi-in to tun gba ọwọ Kazzim waye ni yara ikawe mọkanla ti wọn kọ si Our Lady of the Lords Primary School, Onikoko, l’Abẹokuta. Bẹẹ lo kọ si Methodist Primary School, Imọ, Oke-yẹkẹ, l’Abẹokuta. O kọ mẹfa mi-in, bẹẹ ni yara ikawe mẹwaa ti wọn ti wo lulẹ tẹlẹ dohun ti Micky kọ pada, awọn ọmọ si ti n kẹkọọ nibẹ lọ ni pẹrẹwu.

Ko tan sibẹ o, Ọnarebu Micky Kazzim ṣalaye boun ṣe ri i pe yara ikawe mẹfa mi-in tun di kikọ fawọn akẹkọọ nileewe alakọọbẹrẹ St Augustine to wa l’Adatan, l’Abẹokuta. Bẹẹ lo ri ni ti St James Primary School, Idi-Aba naa. Ọnarebu Micky lo mọ bi wọn ṣe kọ yara ikawe mejila ti wọn n lo lasiko yii pẹlu awọn mi-in.

Nibi ti ẹkọ awọn ọmọ jẹ ẹ logun de, Ọnarebu Kazzim tun pese yara ikawe mejila mi-in fawọn ileewe meji ti wọn wa laarin Guusu Abẹokuta, awọn naa ni C.A.C Primary School, Lantoro, Abẹokuta, ikeji si ni A.N.L.G Primary School to wa ni Ilugun Asalu, ilu ti i ṣe aala laarin Guusu Abẹokuta ati ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.

Iṣẹ rere ti Micky la kalẹ ko kuku tan sibẹ, oloṣelu ọmọ Abẹokuta naa loun gbagbọ pe oju ki i ti ẹni to ba tanna, awọn oṣika to ba pana loju maa n ti. O ni eyi loun ṣe pese ẹrọ apinnaka ti wọn n pe ni ‘Transfomer’ fawọn eeyan Guusu Abẹokuta labala ẹsẹkuku, ti wọn n pe ni CDC.

Ẹrọ nla ti agbara rẹ jẹ 500 KVA/11 KVA lo pe e, meji si ni wọn.

O tẹsiwaju pe wọn ti ko awọn ẹrọ naa lọ saduugbo Oke-Arẹgba ati Abiola Way tipẹ. O ni ọdun meji gbako lawọn eeyan awọn adugbo yii fi wa lokunkun koun too fi transfọma ṣe wọn looore imọlẹ.

Micky ko ti i dakẹ ninu alaye awọn iṣẹ rere rẹ to ni wọn n fọhun titi dasiko yii, o tun jẹ kawọn akọroyin mọ pe nibi ti omi ti n jẹ iṣoro gidi fun wọn ni Guusu Abẹokuta, oun gbẹ kanga igbalode ti wọn n pe ni borehole mẹta fun wọn lati koju iṣoro airomi lo.

O ni akọkọ rẹ loun gbẹ sagbegbe Iyana-Mortuary, lẹyin ọfiisi ajọ INEC to n ri si eto idibo. O ni kanga igbalode keji wa ni Kutọ, ladojukọ gareeji kutọ gan-an, nigba ti ikẹta wa ni agbegbe Ake, nibi ti wọn n pe ni Ita-Faji gangan, l’Abẹokuta.

To ba si jẹ nipa ti ironilagbara ni, ko din ni pako itaja (kiosk) mẹẹẹdọgbọn (25 POS Kiosks) ti Ọnarebu Micky Kazzim ti ko fawọn ọdọ ti wọn n ṣe POS.

Iyẹn banki kereje teeyan ti le fi kaadi pelebe ti wọn n pe ni ATM card gbowo, teeyan si tun le fowo ranṣẹ sibikibi lai si wahala kan.

Micky loun ṣe eyi kawọn ọdọ to n gbiyanju aje naa le maa wa labẹ iboji nigba ti oorun ba n mu, tabi ti ojo ba n rọ bi wọn ba n ṣiṣẹ wọn.

Bakan naa, pako itaja yii ṣee ti lagadagodo bii ẹni ti ṣọọbu, o si tun ṣee lo lapa kan fun ọja pẹẹ-pẹẹ-pẹ bii worobo.

Fun idi eyi ati pupọ rẹ, Ọnarebu Micky Kazzim ni kawọn eeyan Guusu Abẹokuta dibo foun ninu idibo to n bọ yii, ki wọn jẹ koun tun ṣoju wọn lẹẹkan si i ju tatẹyin wa lọ.

O ni ẹkuuṣẹ ni i mori oṣiṣẹ ya, ibo ti wọn ba fi gbe oun wọle lọ sile igbimọ aṣofin agba l’Abuja yoo jẹ koriya foun lati sin wọn si i ni, oun ko ni i ja wọn kulẹ, oun yoo ṣoju wọn dọba labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM ni.

Micky ni ko sẹni to kunju oṣunwọn toun lasiko yii, kawọn eeyan Guusu Abẹokuta fika to tọ romu o.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages