Olota tilu Ota, Oba Abdulkabir Adeyemi Obalanlege, ati igbimo lobaloba nile Awori ati Yewa, nijoba ibile Ado Odo, nipinle Ogun, ti muu da Seneto Solomon Adeola, loju pe didun ni osan yoo so fun ipo asofin agba ekun Ogun West, ninu ibo to n bo.
Ni Afin Olota ni Idaniloju naa ti waye nigba ti Seneto gbe ipolongo woodu si woodu to n se kaakiri, eyi to pe ojo karun-un.
Gbogbo awon oba to soro to fi mo Olota tilu Ota ni won fi oludije naa lokanbale pe ko sewu loko longe fun un nitori awon ise e ti fihan pe awon Yewa Awori wa leyin e.
Oba Shyllon Adedayo, Alagbado tilu Agbado, ninu oro e so pe iyalenu lo je fawon bi Yayi se jade funra e lati ojule bo si ojule lati maa bawon eeyan soro, tawon araalu si n jade lati gbo nnkan to fe bawon so, o ni eyi tumo sii pe won nigbagbo ninu e.
O so pe awon ise akanse ti oludije naa ti n se kaakiri ekun Ogun West fihan pe o bere daadaa tawon araalu si n gbadun e.
Oba Samuel Ojugbenle,Onilogbo tilu Ilogbo, ninu oro e so pe awon ko tii ri iru eeyan bi ti Seneto Adeola, to soju ekun Lagos West niluu Abuja yii ri, o ni bi o se n se ise akanse ni Ek bee naa ni ko fawon eeyan tie sile ni Ogun.
O so pe ki oludije naa lo fokanbale nitori ko ni alatako kankan rara. O ni bo tile je pe ninu oselu ijoba tiwa-n-tiwa gba were ati asiwin lati jade dupo.
Oba Lukmon Agunbiade, Alagbara ti Agbara, so ni tie pe o tipe ti Yayi ti maa n toju awon oba alaye,ko si wahala fun lojo idibo.
Olota ti Ota, so ni tie pe egbe oselu APC ni yoo jawe olubori lati ori ipo aare titi de Ile igbimo asofin tipinle ni Ogun. O ni gbogbo awon Ogun west lo wa leyin won.
O ni latile ni Seneto Solomon Adeola ko tii doju tawon.
Ko to akoko naa ni Senato Adeola, ti so pe oun mo on mo fi akoko oun sile lati kaakiri awon woodu merindinlogun to wa nijoba ibile lati le mo ipenija ti won loju lori idagbasoke agbegbe won.
Bee lo ran won leti pe bi won ba se dibo foun bee naa ni ki won dibo aare won fun Asiwaju Bola Tinubu ti egbe APC, Gomina Dapo Abiodun atawon oludije egbe naa yooku.
“
No comments:
Post a Comment