Idi abajo ni pe gbogbo ero awon kan ni pe omo bibi ilu Ilaro naa ko nii mu nnkan gidi bo ninu ejo kotemilorun to pe naa.
Koda won ti n so aheso kaakiri pe ofo ni oludije yii yoo mu bo pelu awon omo Ile igbimo asofin ti won jo pejo naa.
Sugbon laimo pe riro ni ti eeyan sise ni ti Olorun ati pe eni ti oba oke ba ti daa lare, o soro fun eda lati gbe ebi fun won
Idi niyi to fi je pe lati ojo Aje, to koja yii ni jimnijinni ti de ba awon alatako oselu to si de ba won nibi ti ko dara ni akinyemi ara.
Gbogbo awon araalu ni won duro de ojo idibo lati fi kaadi ibo won le ijoba to wa lode yii danu ki won si gbe Olubiyi Otegbeye wole.
Ohun to si mu ki won se bee ko ju igbe aye inira ti won nijoba to wa lode yii fojoojumo ko won si, ti won si n fi etan tan won je.
Awon alatako oselu yii si ti mo pe Otegbeye kan soso o ju egbeegbeun won lo. Idi niyi ti won fi koko pamopo ti won gbe e lo sile ejo lati fi pa a lenu mo pe ko gbodo jade
Won ro pe nnkan tawon ba mu je nile ejo l'Abeokuta, awon tun le se bee ni Ibadan,ofo nijo keji oja ni won mu bo.
Iduro ko waa si mo bee ni ijokoo ko si mo fun Otegbeye nitori oun ni ireti tawon omo ipinle Ogun n reti bayii.
No comments:
Post a Comment