Oludije gomina labe egbe oselu ADC, nipinle Ogun, Byi Otegbeye ti fesun kan Gomina Dapo Abiodun pe o mo on ba awon ise akanse nile Egba, to si tun mu ifaseyin ba awon idagbasoke aarin gbungbun Ogun iyen Ogun Central.
O soro yii lakooko ti won gbe ipolongo egbe oselu ADC lo si ijoba ibile Odeda.
Nigba to n soro ni afin Olu Odeda, Oba David Olusola, oludije naa seleri pe gbogbo awon ise apati naa loun yoo pada dawole, ti won ba le fi ibo won gbe oun Wole.
O so pe lara awon ise naa ni papako ofurufu to wa ni Wasinmi, ti won ti ba ise lo nibe tele amo ti won ti pa a patapata ti won ko si so idi e di oni.
Otegbeye so pe ise akanse papako ofurufu naa je eyi tijoba apapo n se, ti ko si ye ki won da a duro sugbon ti won se bee nitori won fee se min-in
"
Bee lo tun fesun kan isejoba to wa lode nipinle Ogun lori bi won se pa osibitu oni beedi aadotalenigba ti ijoba Ibikunle Amosun ko ti.
O so pe, "Bi igba teeyan ba mo on mo so di asa bee naa ni ko je ki osibitu to wa no Okemosan, Abeokuta.
Gege bo se wi, a ko gbodo fowo yepere mu eto ilera ati pe nnkan to ye kijoba se ni lati ri pe won se awon nnkan to ye sawon ile iwosan kaakiri, ko si se dun in wo, ki i se ki won ma da apa kan si.
"
Otegbeye wa so pe," Nnkan ti mo ri ninu e ni pe Abiodun mo on mo fee da awon ise akanse to wa nile Egba, paapaa julo Abeokuta duro, to je oluulu ipomle Ogun,to si je pe gbogbo awon to ba n sejoba gbodo ponle.
O waa mu dawon loju pe gbogbo e ni atunse yoo ba leyin to ba ti gbajoba lojo kokandinlogbon, osu karun un, odun yii.
"
No comments:
Post a Comment