Oludije seneto fun ẹkun Lagos West, nipinlẹ Eko, Moshood Adegoke Salvador,ti rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati ṣe suuru fun aarẹ Mohammadu Buhari, fawọn igbesẹ to n gbe lọwọlọwọ yii.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ yii fun igba diẹ ni, ti ko si ni pẹ dopin, ko si si nnkan mii-in bi ko ṣe pe ki eto to n bọ ọhun le lọ nirọwọ rọsẹ.
O fikun ọrọ ẹ pe, Gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ lorileede yii lakooko yii, ko da ibo ti yoo waye ninu oṣu yii duro. nitori ti ilu ko fararọ, ko dun to fawọn araalu, awọn nnkan yii lo mu waa fẹẹ ṣeto idibo lati yan olori tuntun.
''Bi a ba wa n gbadura pe ki ibo maa waye, bi ẹni pe a fara mọ iya to n jẹ wa, ko maa jẹ wa lọ, gbogbo ọna tawa naa ba le gba lati fi ara rọ iya yẹn, ṣebi oṣu kan ni, atni meni ko to atana mọ ana, ko ti ẹ to oṣu kan mọ, ọsẹ mẹta ni, ẹ jẹ ki a fara rọ, ki ibo yẹn fi waye''.
O waa gbadura pe ki Ọlọrun yan ẹni to le ṣe ilu, to ma rọ araalu lọrun, fun wa ni orileede yii.
Bẹẹ lo tun sọ pe, ''Gbogbo alagbara to ba wa ki nnkan bajẹ, Ọlọrun yoo ba ti wọn jẹ. Emi o ni sọ ju bẹẹ lọ, Ọlọrun si ti n ṣiṣẹ ẹ.Ko sẹni kankan to ga ju Ọlọrun lọ. Ọlọrun ti fi agbara han , yoo si ju wọn lọ''.
O sọ pe nipa igbaradi ẹ fun ibo to n bọ lọna, o ni oju lo mọ nnkan to yo inu,awọn o nii sọrọ ki awọn maa bu eeyan, bi ilu yoo ṣe dara, ni awọn yoo maa sọ. o sọ pe nnkan to ti ni loju pupọ ju ni pe awọn ti wọn jẹ alagba fun wa,ti wọn jẹ aṣaaju si wa, ti wọn tun kan sara si wọn pe wọn ti pẹ nidii oṣelu, ti wọn tun sọ pe awọn fẹẹ dije ninu oṣelu dupo aarẹ, wọn ko debi kankan sọrọ to ma hu eeyan lori, ki wọn sọ nnkan ti wọn fẹẹ ṣe ati ọna ti wọn fẹẹ gbe gba. eebu ni wọn bu ara wọn.
Salvador tun sọ pe,''Ṣe ibi ti wọn ba aye awọn ọmọ wa jẹ, ko tii to, to fi jẹ pe eebu ni wọn fi n ṣe ipolongo ibo wọn.won fi jagidijagan dibo, eyi ni Buhari ṣe sọ pe ko le ṣee ṣe fun wọn lati fi owo ra ibo.
''Lati ri owo fi gba awọn ọmọọta, pe ti oun ba si n jẹ aarẹ orileede yii, oun ko nii gba fun wọn. nitori idi eyi, o ti fihan pe awa lo n ṣe gbogbo wahala naa fun. Awa naa ni lati fi ara rọ inira niwọnba.
''Gbogbo ibi to ba ku ki ijọba ṣe, a o nii dakẹ.a maa pariwo fun wọn, nitori owo ti wọn ko jẹ kawọn olowo ri gba, a ti ṣalaye fun wọn pe bi o jẹ ẹgbẹrun marun-un naira ni wọn ri gba, ki wọn sa ti jẹ laarin ọsẹ mẹta to ku, ki ibo waye yii. ẹ jẹ ka ni suuru fun ijọba, ki a gba fun Buhari, nnkan to n ṣe yii.
''Awọn nnkan to n ṣe sẹyin le buru, amọ eyi to n ṣe lakooko yii, to fẹ jẹ ki ibo wa ni apẹẹrẹ, to fẹ ki wọn ka ibo wa, ẹ jẹ ki a fun ni atilẹyin.
''Eeyan ko le maa sọ lakooko yii pe bawo ni aye ṣe wa tabi ko si, nitori pe awọn mẹta ni wọn jẹ gboogi oludije to n bọ yii. awọn meji ni wọn n bu ara wọn,ki lo wa ku, o ti fihan pe awọn meji yii, ki i ṣe ẹni ti wọn le dibo fun.Awọn ni wọn ba iṣẹ ara wọn jẹ, ẹ fi silẹ fun Ọlọrun, Labour lo maa wọle''.
No comments:
Post a Comment