Egbe oselu African Democratic Congress, ADC, tipinle Ogun ti so pe ohun abuku ati itiju nla ni nnkan ti Gomina Dapo Abiodun n se lori bo se fee maa fowo ra Ibo.
Gege bi atejade ti Agbejoro Olumide Onabajo, to je alukoro egbe naa fi sita lori fonran kan ti won fi sita lati ojo Aiku, Sannde, nibi to ti safihan bawon eeyan ijoba kan se n pin owo to ti di atijo bayii fáwọn araalu, owo naa to je egberun marun un si mewaa lo wa ninu apo iwe ijoba, ti won si n mu dawon eeyan naa loju pe won si n na owo yii.
Agbenuso egbe naa so pe ki i se nnkan to dara ki won maa ba Gomina bi iru ipo bee,won lo fi n doju tipinle Ogun.
Gege bo se wi, "Egbe oselu ADC rii nibi ti won ti pin fidio nibi tawon eeyan ijoba ti fáwọn eeyan lowo kaakiri ipomle yii, Ohun itiju lo je pe ti won ba fee se iru nnkan bee ko ye ko je apo iwe ti onte ijoba wa lara e ni won yoo ma a pin nita gbangba."
O tun so pe awon eeyan ipinle Ogun tun sakiyesi pe gbogbo awon iroyin idagbasoke ti won n gbe jade lawon iwe iroyin lakooko yii fihan pe ijoba to wa lode yii ti mo pe awon ti Luna, ti won si waa to pe ona abayo fáwọn ni lati maa fowo ra Ibo.
O salaye pe edun okan lo je pe egberun kan Naira ti won ko gba mo ni Abiodun waa pin kaakiri fáwọn eeyan.
Onabajo waa so pe ki siyemeji nibe rara pe Dapo Abiodun ti toju bilionu Naira to je owo atijo yii pamo to fee lo lati fi ra Ibo ati na fun won laaarin ose meta ti Ibo yii yoo waye.
ADC ipinle Ogun, waa ro awon araalu lati ma se fun egbe APC, ti won ti jin laaye, ki won si ko won patapata. Pelu Ibo ti yoo waye lojo kokanla, osu keta, odun yii.
O ni, ""Nnkan ti ijoba tuntun labe Agbejoro Biyi Otegbeye, seleri ni lati se atunse gbogbo awon nnkan tijoba to wa lode yii ti baje.
No comments:
Post a Comment