Oga ajo eleto idibo INEC nipinle Eko fee gbabode, e yo o danu- Salvador - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 8 February 2023

Oga ajo eleto idibo INEC nipinle Eko fee gbabode, e yo o danu- Salvador



Onarebu Moshood Adegoke Salvador, to je oludije fun ipo asofin fun ekun Lagos West, fegbe oselu Labour, nipinle Eko, ti ke gbajare sita pe oga ajo eleto idibo INEC nipinle Eko, Ogbeni Olusegun Agbaje, ti fee ma gbabode, ki won si tete yo o danu bayii, ko ma ba a da wahala sile fun idibo to n bo yii.

Oludije naa soro yii lakooko to n bawon oniroyin soro, o fesun kan oga eleto idibo naa lori bo se lo n sise tako awon Ibo ti won n gbe nipinle Eko.

O so pe to ba je pe loooto ni orileede setan lati je eyi to se fi se awokose rere, awon eeyan gbodo mu okan won kuro ninu iwa itanje.

Salvador so pe edun okan lo je lori iwa ti oga INEC Eko naa hu iyen to ba je pe esun ti won fi kan an je oooto.

O ni to ba le je bee okunrin naa ko se e nigbagbo ninu e fun eto ibo to n bo naa.O ni ki i se nnkan to bojumu kawon kan maa soro eleyameya nigba ta a ba n soro nipa isokan orileede.

O so pe, "Bi a lo si oke okun,won yoo se bi omo Nigeria, won yoo huwa bi ojulowo omo Nigeria rere.  Bi a ba setan pe ki orileede yii dara, a gbodo mu eleyameya kuro"

" Ti Ogbeni Olusegun Agbaje,oga agba INEC, nipinle Eko, ba n sise tako awon Ibo gege bi esun ti won fi kan an, ko si nnkan meji mii in ju ki won yo nipo lo, nitori a ko fe iru iwa bee.

O salaye siwaju pe to ba se awon esun toun menuba yii, a je pe ko si igbagbo ninu e fun ibo to n bo naa. 

Bakan naa ni Salvador tun so pe Idaniloju wa pe egbe oselu Labour ni yoo jawe olubori ninu Ibo to n bo, nitori won ti gbaradi lati mu orileede yii de Ile ileri.



No comments:

Post a Comment

Pages