Onísọkúsọ ni Bọ̀dé George, ó yẹ káwọn ọlọ́pàá ti gbé e- Ọ̀túnba Ṣẹ́gun Ṣówùmí - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 11 February 2023

Onísọkúsọ ni Bọ̀dé George, ó yẹ káwọn ọlọ́pàá ti gbé e- Ọ̀túnba Ṣẹ́gun Ṣówùmí



Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe o ti yẹ kawọn agbofinro ti gbe ọkan lara awọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP, nilẹ Yoruba, iyẹn Oloye Bọde Ọlayinka George, lori awọn ọrọ kan to sọ, ti wọn lo fẹsun ẹgbẹ oṣelu ẹ, pe awọn kan ninu wọn mọ nipa bi wọn ṣe n tẹ owo tuntun jade.

Ọsẹ to kọja lo sọrọ yii nibi ipade to ṣe pẹlu awọn alatilẹyin ẹ nipinlẹ naa, o sọ pe ti ọrọ ti Bọde George ba sọ ba da a loju, ko mu awọn ẹri sita fun araaye ri, nitori ẹgbẹ oṣelu PDP, ko lọwọ si rara. o ni bi a ba n ja bii ki a ku kọ.

Ṣowumi sọ pe awọn ti ẹni to pe ara ẹ ni Atọna fẹsun kan  yii, ṣe awọn ni wọn wa nidii owo ilẹ wa, ṣe awọn ni wọn n ṣọ owo, abi awọn ni ile ifowopamọ agba iyẹn CBN ni ki wọn wa ni ikawọ owo, o waa sọ pe pẹlu gbogbo nnkan ti agba oṣelu ọhun sọ yii, ofo patapata lo mu, o si ti yẹ ko wa nibi tawọn agbofinro yoo ti maa fọrọ wa lẹnu wo.

O waa sọ pe bi awọn agbofinro ko ba tii ṣe bẹ, oun fi akoko naa pe wọn lati gbe agba oṣelu PDP, nilẹ Yoruba ọhun lati le waa fidi ẹri ọrọ to sọ lelẹ. O ni gbogbo eeyan lo ti mọ pe ẹgbẹ oṣelu APC, ti kuna patapata lori ipo aṣaaju, iṣejọba.

O ni ko yẹ ki Bọde George wa maa ṣe oṣelu ẹtanu, o ni bi inu awọn agba oṣelu kan ninu ẹgbẹ ọhun ko ba tiẹ dun si nnkan to lọ ni PDP, nipasẹ ibo pamari to waye, nipa iha ti alaga ẹgbẹ naa lapapọ naa kọ, ṣugbọn nnkan toun fẹẹ ki wọn mọ ni pe lati dari ẹgbẹ  nigba ti wahala ba n waye, o  lagbara, amọ lsati dari ara eeyan gan-an lo ṣe pataki.

O waa rọ gbogbo awọn alatilẹyin ẹ pe ki wọn wa ni isọkan ati pe ẹnikan ṣoṣo tawọn ṣiṣẹ fun gẹgẹ bi aarẹ orileede yii ninu ibo aarẹ to n bọ ninu oṣu yii ni Alaaji Atiku Abubakar,nitori oun mọ pe oun lo lu da isọkan pada wa si Naijiria.

O sọ pe '' Mo rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii nipa ibo gbogbogboo ti yoo waye lọdun yii, a mọ pe yoo lagbara, nitori bi nnkan ṣe n lọ lakooko yii atawọn iṣoro ta n koju lọwọlọwọ, ohun to ṣe pataki fun wa bayii ni ki wa ni isọkan''

Bakan naa lo tun sọ fawọn eeyan ẹ pe ki wọn ma ṣe feti si awọn ọrọ ahesọ tabi isọkusọ to n lọ nigboro pe oun ti jawọ ninu ẹjọ to n lọ lọwọ nipa ti ipo gomina, o sọ pe ọwọ ile ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ni aṣẹ wa ati pe pẹlu awọn ẹri toun ni, oun yoo jawe olubori, igba diẹ lo sọ pe o ku bayii.


No comments:

Post a Comment

Pages