Asiko to lati gbe igbesẹ lori ọlọpaa agbegbe- Aarẹ OPC New-Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 11 July 2024

Asiko to lati gbe igbesẹ lori ọlọpaa agbegbe- Aarẹ OPC New-Era



Aarẹ fẹgbẹ awọn Oodua People Congerss, New-Era, Oloye Rasak Arogundade Balogun, ti rọ awọn gomina lapa ilẹ gusu lati ma ṣe sun asunpara lori eto abo, ki wọn si tete gbe igbesẹ lori ọlọpaa agbegbe ti wọn ti n beere fun tipẹ.

Ninu lẹta kan ti ẹgbẹ naa kọ si Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Gomina ipinlẹ Ogun, to tun jẹ alaga fawọn gomina lapa gusu, ni wọn ti rọ wọn lati tete ṣiṣẹ lori aabo yoo ṣe deba awọn ipinlẹ ti wọn jẹ adari fun.

Wọn kọkọ gboriyin fun wọn fawọn ipa tawọn gomina ọhun ko atawọn igbesẹ wọn gbogbo amọ wọn jẹ ki wọn mọ pe ko yẹ ki wọn maa nawo anadanu lori awọn ẹka ọlọpaa ijọba apapọ, ti ko jẹ itẹwọgba araaalu.

OPC New Era, waa fi ti iṣẹlẹ to tun waye laipẹ yii nipinlẹ Ondo ṣe apẹẹrẹ nibi tawọn Fulani darandaran tun ti gbena woju awọn alaabo tijọba da sile iyẹn Amọtẹkun, eyi to waye ni ibẹrẹ oṣu yii.

Bakan naa eti to tun ṣẹlẹ ni Nimbo, nipinlẹ Ebonyi, nibi tawọn darandaran ọhun tun ti pa awọn eeyan mẹrin nibi isinku kan, ninu oṣu kẹrin ọdun yii. Wọn ni iru nnkan bẹẹ ko yẹ ki wọn jẹ ko tun waye mọ.

Wọn ni awọn Amọtẹkun ti wọndoju ija kọ yii, ẹnu iṣẹ wọn ni wọn wa lati dabobo awọn agbẹ, Akoko ti waa to bayii ti wọn lawọn gomina ọhun gbọdọ gbe igbese ti yoo fopin si idaamu awọn darandaran yii.

Bẹẹ ni wọntun sọ pe bawọn darandarn ọhun ṣe n fojoojumọ fi tipatipa wọnu oko lati fi ẹran wọn jẹ ti wọn si tun doju ogun kọ awọn agbẹ le ma jẹ ki abo wa fawọn ounjẹ fun igba pipẹ.

Wọn ni nnkan ti yoo dara ni bi awọn gomina ipinlẹ gusu wa lọna ti wọn ki wọn si ṣiṣẹ lori awọn aba kan iru eyi ti wọn sagbekọlẹ ẹ ti wọn pe ni ‘Asaba Declaration’ in May 2021’’

Ninu ẹ ni eyi ti wọn sọ pe bawọn darandaran, iwa ọdaran gbogbo ṣe wa lapa ilẹ gusu lorileede yii ti mu ipenija wa, eyi ti ko jẹ kawọn araalu gbe igbe aye irọrun, wọn gbọdọ fopin si lawọn agbegbe naa.

Bẹẹ naa lawọn naa tun mẹnuba pee ki atunto tko waye, ni ọna ti yoo fopin si wahala ati idaamu ojoojumọ, wọn wa rọ awọn gomina ilẹ gusu yii lati sa ipa wọn ki wọn si fi apẹẹrẹ rere lelẹ ti wọn yoo fi maa ranti wọn lọjọ rere, ki wọn si mọ pe ọlọpaa agbegbe nikan lo le tan iṣoro yii.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages