Ẹ jẹ ka ba Olufẹmi Ajadi ọmọ Oguntoyinbo ṣajọyọ, oni lọjọọbi ẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 19 July 2024

Ẹ jẹ ka ba Olufẹmi Ajadi ọmọ Oguntoyinbo ṣajọyọ, oni lọjọọbi ẹ

Lojumọ to mọ lonii, lara ohun tawọn eeyan kan ka kun lọjọ aye wọn ti wọn ki i fi ṣere ni ọjọ iranti ọjọ ti wọn bi wọn saye, ti wọn sọ pe wọn ṣayẹyẹ ọjọọbi, idi ti wọn si fi kaa kun ni pe wọn gba gẹgẹ bi ọjọ lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun ọba adaniwaye, to da wọn saye, ki wọn si tun fi gbadura fun oore ọfẹ lati fi lo ọpọ ọdun ẹ ni ilẹ alaaye pẹlu alaafia ati ẹmi gigun.

Nitori naa ni ko ṣe ya awọn eeyan lẹnu nigba ti wọn gbọ pe onii ni ayajọ ọjọ ti wọn ki baba ati iya Olufẹmi Ajadi ọmọ Oguntoyinbo ku ewu pe wọn bi ọmọ tuntun sile aye. Lati nnkan bii aago mejila oru, Ogunjọ oṣu yii lawọn afẹnifẹre ti n ba ọkunrin ọhun to tun jẹ ambasedọ fawọn ọdọ ṣajọyọ ọjọọbi ẹ, lori ẹrọ ayelujara, ti wọn si n fi ọpọ adura ranṣẹ sii.

Ko le ṣe ko ma ribẹ nitori Fẹmi Ajadi, to dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP, nipinlẹ Ogun naa ki i ṣe eeyan bẹẹ, ẹlẹyinju aanu top n ṣe fonile, bẹẹ lo tun ṣe fun alejo, ko si sẹni to ba a rin to toṣi, nitori gbogbo ero ẹ ni bi iṣẹ ati iya yoo ṣe di afisẹyin ninu igbe aye ọmọ eeyan.

Titi di akoko taa wa yii ọpọ awọn eeyan lo n jẹ labẹ ọkunrin naa, to si jẹ ọna ipa toun ko ninu aye awọn ẹda kan lati jẹ kawọn naa maa rọwọ mu lọ sẹnu. Bi Oguntoyinbo tọpọ awọn kan tun mọ si Coco Samba, ṣe gbajumọ nidii oṣelu bẹẹ ni ọba oke tun jẹ ko rọwọ mu nidii iṣẹ okoowo, bakan naa nipa amuludun, oun naa bi ki wọn si pese aabo ati dukia,Ọba oke fi ọpọlọ da ọkunrin yii lọla.

Bo tilẹ jẹ pe ko si beeyan ṣe le maa ga to nilẹ alaaye, yoo lawọn ti wọn yoo jẹ ọta, amọ nipa oore ati aanu, o n jẹ ko bori awọn ọta ẹ yii. Nitori idi eyi lo ṣe yẹ ki gbogbo wa parapọ, ka ba ọlọpọlọ pipe ẹda yii ṣajọyọ pẹlu adura pe ibi giga to n lọ, ko nii walẹ lailai.


No comments:

Post a Comment

Pages