Iru ajalu iwọde ENDSARS ko tun nii waye nilẹ Yoruba-OPC NEW ERA - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 22 July 2024

Iru ajalu iwọde ENDSARS ko tun nii waye nilẹ Yoruba-OPC NEW ERA



Oodua People Congress, New Era, ti sọ pe iru ajalu to waye lakooko iwọde Endsars, ko nii waye mọ nilẹ Yoruba ati pe awọn ko nii gba rara ni.

Ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Oloye Rasak Arogundade Balogun fọwọ si, eyi ti Ọgbẹni Adeṣina Abiọdun fi sita ni wọn ti sọ pe OPC New era ko niigba ki iru iwọde bẹẹ waye kaakiri ilẹ Yoruba.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe loootọ lawọn ọmọ orileede yii koju ọpọ iṣoro lori ọrọ aje, ti ilu le koko, ti wọn si n fojoojumọ koju ipenija.

Tawọn ọmọ orileede yii si n foju sọna fun ọna abayọ lati ja ara wọn gba lọwọ bi gbogbo ẹ ṣe dojuru.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko tako iwọde nitori lara ẹtọ ọmọniyan iyẹn ti wọn ba ṣee ni ọna ẹtọ.

Ṣugbọn ko yẹ ko waye bi wọn ṣe ṣe ti Endsars, nibi ti wọn ti gba awọn janduku laaye lati gba a mọ wọn lọwọ.

Atẹjade ọhun tun fikun pe gbogbo awọn araalu lo mọ ọsẹ ti wahala iwọde ọhun da silẹ, eyi ti ko tii tan nilẹ titi di akoko yii.

Wọn ni awọn lo anfaani yii lati ke si gbogbo ọmọ ẹgbẹ OPC New Era, lati ma ṣe bawọn da si iwọde tawọn kan n gbero ẹ yii ati pe kawọn to n damọran ẹ gbe e lọ si Abuja, to jẹ ibugbe ijọba apapọ.

Arogundade tun kilọ ninu atẹjae ọhun pe kilọ lati ma ṣe jẹ ki iru iwọde bẹẹ waye nilẹ Yoruba,eyi ti wọn tun le lo anfaani ẹ lati ba awọn dukia jẹ.

Wọn ṣalaye pe ẹtọ awọn ni lati daboobo awọn nnkan ini ati ẹmi awọn eeyan, nitori idi ẹ awọn ko nii fọwọ lẹran kawọn kan waa ma daluru.

Bẹẹ ni wọn tun rọ ijọba lati ṣatunṣe lori bi wọn ṣe n pin paleetifu fawọn araalu, nitori ọpọ ibi to yẹ ko de ni wọn ko pin debẹ, to jẹ pe awọn kan ni wọn tun fi ṣe apapin.

No comments:

Post a Comment

Pages