Ọpẹ o! Ọọdunrun eeyan darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NNPP ni Ijẹbu Ode - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 26 July 2024

Ọpẹ o! Ọọdunrun eeyan darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NNPP ni Ijẹbu Ode



Idunnu ṣubu layọ lanaa niluu Ijẹbu Ode nigba ti ọọdunrun iyẹn 300 darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NNPP nijọba ibilẹ naa.

Ayẹyẹ ọhun to waye lawọn oloye ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun ti gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ọhun wọle loruko alaga wọn nipinlẹ Ogun, iyẹn Amofin John Olufẹmi Aina ati akọwe, Alaaja Ṣakirat Idris Arowolo.

Ninu ọrọ Kọmureedi Ọlayẹmi Ọmọkẹhinde Olowu, to je akọwe olupolongo fẹgbẹ oṣelu NNPP, nipinlẹ Ogun, lo ti ki awọn ẹgbẹ tuntun naa kaabọ lorukọ alaga wọn.

Bẹẹ lo muu da wọn loju pe gbogbo ẹtọ to ba yẹ lati maa ṣe fun wọn gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ lawọn yoo maa ṣe fun wọn.

Bakan naa lo tun sọ di mimọ pe ohun idunnu lo jẹ fawọn bawọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ wọn lojoojumọ, eyi to sọ pe o tumọ sii pe awọn araalu gba ti wọn.

O waa rọ awọn to ti wa ninu ẹgbẹ naa tẹlẹ lati fi ifẹ han sawọn tuntun, ki wọn si gba lati jọ ṣiṣẹ pọ pẹlu idaniloju pe gbogbo wọn yoo jọ ṣe aṣeyọri papọ.

Lara awọn to tun wa nibi ayẹyẹ ọhun ni Ọnarabu Foluṣọ Adekunle, to jẹ olori awọn ọdọ nipinlẹ Ogun, Ọmọọba Micheal Adesanya, alaga NNPP fun ẹkun Ogun East.

Awọn yooku tun ni Oloye Yetunde Aina,igbakeji olori awọn obinrin, Ajihinrere Sodiji ati Ọnarebu Adeleke, toun jẹ alaga ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ Ijẹbu Ode.

No comments:

Post a Comment

Pages