Gbajumọ sọrọsọrọ nni, Oloye Ọlalekan Alex Shoyinka, tọpọ mọ si Ayinla Ẹgba, lo ti jade patapata lati dupo alaga ijọba ibilẹ Abẹokuta South labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, nibi ibo ijọba ibilẹ to yoo waye nipinlẹ Ogun, ninu oṣu kọkanla, ọdun yii.
Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe ahesọ lawọn kan pe ọrọ naa tẹlẹ ṣugbọn ni bayii, ọkunrin naa ti sọ pe ko si ahesọ kankan nibẹ oun ti jade, bẹẹ lo si da oun loju pe pẹlu agbara ti Ọlọrun, oun yoo jawe olubori.
Lakooko to kede ara ẹ sita, gẹgẹ bi oludije fun ipo alaga ọhun, Ayinla Ẹgba sọ pe jijade oun ki i ṣe fun ere rara bi ko ṣe o ni awọn nnkan pataki.
O sọ pe erongba oun lati jade yii ki i ṣe fun imọtara ẹni nikan tabi fun anfaani oun nikan bi ko ṣe lati fi ran awọn araalu lọwọ fun awọn idagbasoke.
Gẹgẹ bi ẹni to mọ nipa awọn eeyan igberiko, toun naa ti jade wa, oun mọ ibi ti bata ti ta oun lẹsẹ, gbogbo irora awọn araalu loun yoo rii pe oun sa agbara oun lati wa iyanju si.
Ayinla Ẹgba tun fikun pe bawọn ara agbegbe Abẹokuta South, ba le fi ibo wọn gbe oun wọle, oun ṣetan lati dojukọ ipenija ti wọn ni nipasẹ ijọba to wa lode.
Bẹẹ lo ni oun ti ṣagbekalẹ wọn eto toun ni lọkan fawọn araalu, toun yoo si bẹrẹ iṣẹ le lori, loju ẹsẹ ti wọn ba ṣebura foun gẹgẹ bi alaga naa. O wa rọ awọn araalu lati lo kaadi idibo wọn fi dibo foun. Pẹlu ileri pe oun ko nii doju ti wọn.
No comments:
Post a Comment