Dapọ Abiọdun ṣeleri atilẹyin ọgbin irẹsi ti yoo maa mu owo wọle - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 21 August 2024

Dapọ Abiọdun ṣeleri atilẹyin ọgbin irẹsi ti yoo maa mu owo wọle



Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, ti ṣeleri atilẹyin bi ọgbin irẹsi to wa ni Magboro yoo ṣe maa mu owo to to biliọnu lọna ọgbọn wọle fawọn agbẹ onirẹsi.

O sọrọ yii nibi eto ṣiṣi ikore awọn irẹsi onigba eeka ti wọn ti gbin eyi ti ajọ agbaye pẹlu ifọwọsowọpọ ileeṣẹ to n ri si iṣẹ akanṣe ayipada ọrọ aje nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun.

Abiọdun ṣakiyesi pe ni bayii ipinlẹ Ogun ti darapọ mọ awọn ipinlẹ yooku bii Eko, Kebbi ati Bayelsa ti wọn ti n gbin irẹsi jade.

O sọ pe " Eeka ilẹ onigba ti wọn fi gbin irẹsi yii lo jẹ pe kikida awọn obinrin atawọn ọdọ agbẹ ni wọn wa kaakiri orileede yii ki i ṣe ipinlẹ Ogun nikan"

 O fikun ọrọ ẹ pe ẹnikọọkan wọn ni fun ni eeka ilẹ kọọkan, to si tumọ si pe awọn agbẹ igba ni wọn kopa nibi ọgbin ọhun.

O ṣalaye pe inu oṣu kẹrin ni wọn bẹrẹ iṣẹ akanṣe ọhun, nigba ti yoo si fi di oṣu karun un ọdun yii wọn ti bẹrẹ ọgbin ti wọn waa kore ẹ bayii. O ni eyi to tumọ sii pe a le maa ṣee lẹẹmẹta lọdun.

Abiọdun waa sọ pe eto yii wa lara eyi ti isakoso ijọba Tinubu la silẹ lati fopin iṣẹ ati iya lawujọ. Bẹẹ ni yoo tun jẹ ki ounjẹ pọ lorileede yii.

O fikun ọrọ ẹ pe Ọlọrun fi ohun alumọlẹ ati isagbara da ipinlẹ Ogun lọla nitori idi eyi lawọn ṣe gbọdọ mu iṣẹ ọgbin ni pataki, nitori o n faye ipese iṣẹ silẹ.

Ninu ọrọ kọmiṣanna feto ọgbin, Bolu Owotọmọ, o ni eto ọhun wa lara agbekalẹ ijọba Abiọdun lati jẹ ki ounjẹ wa niluu.
 
Nigba to n sọrọ nibẹ, kọmiṣanna feto isuna, Dapọ Okubadejọ, o gboriyin fawọn agbẹ bẹẹ lo sọ pe lara ati pese ounjẹ lọpọ yanturu ni eto ọhun.

Arabinrin Mosun Owo-Odusi, to jẹ alakoso fun iṣẹ akanṣe ọhun sọ pe awọn ṣee lati fi gbe irẹsi to to gbangba sun lọyẹ jade, ti yoo kopa to jọju ninu aye awọn eeyan bẹẹ lo wa dupẹ lọwọ Gomina fun atilẹyin ti wọn ri gba.

No comments:

Post a Comment

Pages