Nibẹ lo ti fi erongba ẹ lati dije fun ipo alaga ijọba ibilẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu New Nigerian Peoples Party, tipinlẹ Ogun, nibi ibo ti yoo waye ninu oṣu kọkanla, ọdun yii. Latigba naa ni ọrọ naa ti n ja rahinrahin nilẹ titi di akoko yii.
Gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ, inu ẹgbẹ oṣelu APC, ni ọkunrin naa ti wa tẹlẹ, ki wahala ọrọ owo ijọba ibilẹ to waye laarin oun ati Gomina Dapọ Abiọdun, ninu eyi ti wọn yọ ọ danu nipo alaga ọhun ti wọn si fi igbakeji ẹ, rọpo ẹ.
Ibeere tawọn araalu paapaa oloṣelu ẹgbẹ ẹ n beere lọwọ ẹ pe latigba naa ni pe ṣe o ṣi wa ninu ẹgbẹ APC, nitori ko sẹni to mọ ibi to n lọ, to si jẹ pe titi di akoko yii lo si maa n pariwo lori ọrọ owo ijọba ibilẹ to ni o yẹ ko maa lọ si oṣuwọn ijọba ibilẹ, amọ to ni ọdọ Gomina Dapọ Abiọdun, lo n de si, eyi ti ko ṣe jẹ kawọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.
Nibi ohun to gbe sita lo ti sọ pe lagbara Ọlọrun, awọn tun ti wọnu ọkọ tuntun, gẹgẹ bi ojulowo ọmọ Afẹnifẹre. Ati pe awọn yoo kọjumọ bi awọn idẹrun yoo ṣe deba awọn ara igberiko, bi oun ṣe pinnu tẹlẹ.
Iwadii wa labẹlẹ tun fi ye wa pẹlu bi nnkan ṣe n lọ, ọpọ awọn oloṣelu kan ni wọn tun ti pinnu lati tẹle ọkunrin naa wọnu ẹgbẹ oṣelu tuntun yii. Lọrọ kan, ohun to daju saka ni pe Wale Adedayọ ti fi APC silẹ bọ sinu ẹgbẹ tuntun.
No comments:
Post a Comment