Eto ọhun la gbọ pe ẹgbẹrun kan awọn obinrin to ba kopa lawọn ileewe mẹjọ to jẹ tijọba ti wọn n kọ nipa sayẹnsi ati imọ ẹrọ yoo ti jẹ anfaani ẹkọ ọfẹ nipa kikọ wọn lwọn lawọ iṣẹ bii jorin jorin. Titun mọto ṣe, kafinta, awọn to n tun ina ṣe atawọn iṣẹ mii-ii.
Eto ẹkọ ọfẹ yii la gbọ pe wọn yoo ti fun wọn lawọn iwe ti wọn yoo maa lo, to fi mọ awọn ohun elo fun odidi ọdun mẹta lati le jẹ kawọn ọdọbinrin yii fi le ni awọn ohun alumọni ti yoo wulo fun wọn lọjọ iwaju lati le ṣe aṣeyọri.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, fọwọ si, wọn ti rọ awọn to ba nifẹẹ lati kopa ti wọn niwe ẹri oniwe mẹwaa lati lọ forukọ silẹ fun iṣẹ ti wọn ba fẹẹ yan laayo ọhun lọfẹẹ nileeṣe ‘ Ogun State Education Revitalization Agenda’ (OGSERA), bẹrẹ lati Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, di ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ ọdun yii.
Bakan naa, kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin ati idagbasoke awujọ, Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ, tun ti tẹnumọ lakooko to ṣabẹwo sawọn agbegbe kan niluu Ijẹbu Ode, pe eto ẹkọ ofẹ fawọn obinrin jẹ erongba lati le jẹ ki wọn maa figagbaga pẹlu awọn ọkunrin lori iṣẹ ọwọ ti wọn ba jọ pade lori papa.
Bẹẹ lo ni yoo tun jẹ ki ọrọ aje tun gberu si, ti yoo si mu kawọn naa kopa to jọju fun idagbasoke ipinlẹ Ogun. Ninu ọrọ Arabinrin Mosun Owoodunsi, to ṣoju ọga ni ẹka manija akanṣe iṣẹ ni ẹka idagbasoke olorijori, Ọgbẹni Fatai Ọṣunsanya, lo ti sọ pe gbogbo awọn ile ẹkọ imọ ẹrọ to jẹ tijọba ni atunṣe ti de ba pẹlu awọn ohun elo igbalode to ba ode oni muu.
No comments:
Post a Comment