Sikirulae Ogundele, ti wọn dibo yan pada wọle gẹgẹ bi alaga igun kan ni ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe awọn ti wọn si wa lẹyin Ladi Adebutu, lawọn to n sanwo fun, bẹẹ lo ni ile ẹjọ lo ma sọ ojulowo alaga ẹgbẹ laipẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko ti wọn ṣe ipade gbogbogboo ti igun wọn to waye lanaa, niluu Abẹokuta. O sọ pe ko si ibẹru fun ọmọ Ọlọrun oun, nitori oun mọ pe awọn gan-an ni ojulowo tawọn si tẹle gbogbo ilana ti ẹgbẹ lapapọ la kalẹ.
O sọ pe ipade gbogbogboo ti wọn ṣe lọdọ wọn ni wọn ti ran awọn agba ẹgbẹ lati Abuja lati waa sakoso ẹ. O ni awọn kọle lori ofo, idi niyi tawọn fi ṣe nnkan ti ko ni mu abuku wa lọjọ iwaju.
Ogundele sọ pe iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ lawọn ṣe eyi ti ẹgbẹ lapapọ fọwọ si, o ni eyi to fi awọn aṣoju han lati wọọdu titi de ijọba ibilẹ titi de ipinlẹ tawọn fi ṣe eto tawọn ṣe ọhun.
O ni ipade gbogbogboo naa lo lọ bo ti yẹ nibi ti wọn dibo yan oun gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa fun igba keji. O ṣalaye siwaju pe lati oke nile ti daru wa, bawọn kan ṣe wa sọdọ ti wa lawọn kan naa gba ibi igun keji lọ.
O ni igbẹjọ to n lọ lọwọ nipa ipo aṣaaju ẹgbẹ ni yoo sọ ojulowo ninu awọn mejeeji. O waa ni kawọn ọmọ ẹgbẹ fọkanbalẹ lori ohun to n waye lakooko yii ninu ẹgbẹ naa pẹlu idaniloju pe oun gbogbo yoo yanju laipẹ yii.
No comments:
Post a Comment