Lọsẹ to kọja yii ni ẹgbẹ apapọ oṣelu nipinlẹ Ogun, IPAC, ṣepade pọ pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, nibi ti wọn ti rọ wọn lati kesi ajọ to n ṣeto ijọba ibilẹ iyẹn OGSIEC, lati yọ owo kanpa ti wọn sọ pe awọn oludije fun ipo alaga ati kanselọ yoo san fun ibo ijọba ibilẹ to n bọ ninu oṣu kọkanla.
Ọnarebu Sanyaolu Abayọmi, to jẹ alaga ẹgbẹ ọhun lo ko awọn yooku ẹ ṣodi lọ sibi ipade ti wọn si sọ pe dandan ki wọn fagile owo ọhun to ba jẹ pe ifẹ gbogbo ẹgbẹ oṣelu ni wọn ni, ti wọn ko fi sibi kan ji ibi kan.
Alaga IPAC tun ṣalaye pe owo ti wọn sọ pe kawọn ẹgbẹ oṣelu kọọkan yii san yii ti pa wọn, bi wọn ba ni ki wọn ro bi nnkan ṣe n lọ si lorileede yii ti gbogbo ẹ ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ.
O tun tẹnumọ pe ko si ẹgbẹ oṣelu naa to lagbara lati san owo ọhun.Bẹẹ lo sọ pe idunnu awọn ni yoo jẹ bi wọn ba le rọ ajọ eleto idibo OGSIEC, bi wọn ba le sun ọjọ idibo ọhun kuro lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii ti wọn fi si tẹlẹ
Lakooko ipade naa, nibẹ ni olori ile igbimọ aṣofin, nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Daisi Ẹlẹmide, ti rọ awọn eleto idibo OGSIEC, lati rii pe wọn gbe igbesẹ to tẹle ilana ati ofin pẹlu idaniloju pe ile igbimọ aṣofin ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati rii pe ibo naa lọ nirọwọ-rọsẹ.
Bakan naa ni Ọnarebu Lukman Adelẹyẹ, to jẹ olori ọmọ igbimọ to kere ju ati Yusf Amosun, toun wa alti Ewekoro pe awọn OGSIEC nija lati tẹle ohun ti ofin sọ ki wọn ma ba a da wahala silẹ lakooko ati lẹyin igba ti ibo ijọba ibilẹ ba pari. Wọn sọ pe ile igbimọ aṣofin ti ṣetan lati ṣe awọn atunṣe nibi to ba ku si.
Ninu ọrọ Ọgbẹni Tunji Akọni, to ṣoju ajọ eleto idibo ọhun nibi ipade yii lo to sọ pe awọn naa n gbiyanju lati rii pe ohun gbogbo n lọ letoleto ati pe laipẹ laijinna, ohun gbogbo yoo lọ, ti ko si ni si wahala kankan laarin ẹgbẹ apapọ oṣelu atawọn naa.
No comments:
Post a Comment