Ibo ijọba ibilẹ Ifọ; Awọn araalu fi atilẹyin wọn han si Kuṣhimọ gẹgẹ bi alaga wọn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 14 September 2024

Ibo ijọba ibilẹ Ifọ; Awọn araalu fi atilẹyin wọn han si Kuṣhimọ gẹgẹ bi alaga wọn



 

Bo tilẹ jẹ pe oju Gomina Dapọ Abiọdun lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun n wo bayii lori awọn oludije fun ipo alaga fun ti ibo ijọba ibilẹ to yoo waye ninu oṣu kọkanla yii sibẹ awọn araalu ijọba ibilẹ Ifọ ti n fi atilẹyin wọn han si Ọnarebu Idris Ọlalekan Kushimọ tọpọ awọn eeyan mọ si Kush.

 

Ninu atẹjade kan to tẹ wa lọwọ lati gbọ pe awọn araalu tiṣetan lati fi ibo wọn gbe ọkunrin naa wọle niwọngba ti Gomina ba fi le faa kalẹ gẹgẹ bi oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ṣapejuwe oludije naa gẹgẹ bi ẹni to kaju ẹ, to si bọwọ fun awọn agbalagba, to si tun tun jẹ ẹlẹyinju aanu, eyi ti gbogbo ọmọde atagba fẹẹ tiẹ laarin ilu.

 

Wọn ṣalaye siwaju pe ka fi ti oṣelu silẹ, odu ni Kush, ki i saimọ foloko, wọn ni ọpọ awọn agba ninu oṣelu nijọba ibilẹ naa ni wọn si jẹri si pe ọmọ daadaa ni, ti ki i wo awọn eeyan loju bẹẹ ni ki i tun yaju si agba,

 

Idi niyii ti ko ṣe ya wọn lẹnu nigba ti wọn sọ pe oun lo gbe ipo kin in ni ninu ibo pamari ti wọn di ni Ifọ, wọn mọ pe o ni ọgbọn inu ti wọn fi n ṣakoso ijọba ibilẹ.

 

Awọn araalu naa sọ pe bi wọn ba fẹẹ ki idagbasoke ba ọrọ aje ati ohun gbogbo nijọba ibilẹ Ifọ, Kushimọ lawọn nigbagbọ ninu ẹ pe o le ṣe nitori ala to ti n la tipẹ, ti awọn si mọ pe akoko ti to fun Ọlọrun la mu erongba ala naa ṣẹ.

 

Bẹẹ ni wọn rọ Gomina Dapọ Abiọdun atawọn agba ẹgbẹ nijọba ibilẹ naa, ki wọn fi mọ sọkan, ki wọn fawọn ni Kushimọ lati jade dupo fun alaga ijọba ibilẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni Ifọ.

No comments:

Post a Comment

Pages