Igbagbo̩ mi ninu Gomina Dapo̩ Abio̩dun atawo̩n agba e̩gbe̩ os̩elu s̩i duro gbo̩ngbo̩in- O̩lalekan Kus̩himo̩ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 22 September 2024

Igbagbo̩ mi ninu Gomina Dapo̩ Abio̩dun atawo̩n agba e̩gbe̩ os̩elu s̩i duro gbo̩ngbo̩in- O̩lalekan Kus̩himo̩



O̩narebu Idris O̩lalekan Kushimo̩, to̩po̩ mo̩ si Kush, e̩ni to jawe bori fun ipo alaga ijo̩ba ibile̩ Ifo̩, labe̩ e̩gbe̩ os̩elu All Progresive Congress, APC, tun ti fi ẹmi igbagbọ to ni si Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun atawọn agbagba ẹgbẹ oṣelu nijọba ibilẹ Ifọ, gẹgẹ bi eyi to duro gbọingbọn, ti ko si ni yẹ.

 

Ninu atẹjade kan ti ikọ ‘Media Team’ ẹ gbe jade laarọ yii lo ti sọ pe  erongba Gomina lori IṢẸYA lo ti tubọ so eso rere, to ti mu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun, ni eyi ti gbogbo araalu gan-an le jẹri si.

 

Kuṣimọ ṣalaye siwaju pe ‘’ Mo duro ṣinṣin ninu asiwaju rere to ni erongba gidi, to ṣi ṣe daadaa nipinlẹ Ogun, iyẹn Gomina Dapọ Abiọdun. Bẹẹ naa ni mi o tun fọrọ awọn agbagba aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, nijọba ibilẹ Ifọ ṣere, lori bi wọn ṣe duro gbọingbọin pẹlu mi, mo gbọṣuba fun wọn’’.

 

‘’Gbogbo wọn ti jẹ ka mọ pe wọn n fẹ alaafia ati iṣọkan ninu ẹgbẹ wa ni Ifọ lapapọ. Igbagbọ mi ninu wọn kọja ọrọ ẹnu, bi ko ṣe tọkantọkan. O tipẹ ti mo ti maa n gbero bi yoo tubọ ṣe maa dara ninu ẹgbẹ wa APC’’ 

 

‘’ Mo fẹẹ ki ẹ mọ daju pe lati inu oṣu kẹjọ, ọdun 2018, ni mo ti ni ẹmi ifọkantan si Gomina Dapọ Abiọdun, eyi to ti wa ninu akọsilẹ, eyi ti mi ko ni rẹyin lati tẹsiwaju. Eriogba mi lati jẹ ki ijọba ibilẹ Ifọ tubọ gbooro ṣe, ki i ṣe nnkan ti mo le da ṣe bi ko lọla atilẹyin Ọlọrun, ati Gomina Dapọ Abiọdun atawọn agbaagba ẹgbẹ, ti mo ni igbẹkẹle ninu wọn.

 

Ajọṣepọ gbogbo wa ni lati gbe ijọba ibilẹ de ibi to ni apẹẹrẹ rere ti mo si nigbagbọ pe Ọlọrun yoo ran wa lọwọ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages