Wọn ni wọn fẹẹ dabaru ibo pamari APC ni Ifọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 7 September 2024

Wọn ni wọn fẹẹ dabaru ibo pamari APC ni Ifọ


Ọpọ awuyewuye lo ti n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ ifọ, nipinlẹ Ogun lori ibo pamari to waye fun ibo lati yan ẹni ti ẹgbẹ wọn yoo fa kalẹ fun ibo ijọba ibilẹ to n bọ ninu oṣu kọkanla ọdun yii.

Awọn kan ni wọn fẹsun kan olori ile igbimọ aṣofin tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Ọlakunle  Oluọmọ ati kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin, Adijat Motunrayọ Adelẹyẹ pe wọn fẹẹ lo agbara wọn lati dabaru pamari ti wọn ṣe tẹlẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Ọnarebu Idris Ọlalekan Kushimọ, ni wọn mu bi ẹni to jawe olubori nibi ibo pamari tawọn agba ẹgbẹ naa di pẹlu ibo meje.

Tawọn yooku bii Ọnarebu Kọlawọle Ahmed Adeniji ni ibo marun-un, Agbẹjọro Olumide Oduwọle ni mẹrin-in, nigba ti  Dapọ Adebẹsin ati Ṣoyọde ni ibo ẹyọ kọọkan.

Iwadii fi ye wa pe wọn ni bi Kushimọ ṣe jawe olubori ko dun mọ Oluọmọ ati Adelẹyẹ ninu nitori wọn ki i ṣe oludije wọn, ti wọn ni wọn ṣi n wa ọna lati yi orukọ naa pada.

Ẹnikan to ba wa sọrọ sọ pe wọn ti mu orukọ ẹni to jawe olubori naa sọwọ si Gomina Abiọdun ṣugbọn ṣe lawọn gbọ pe wọn ti da orukọ naa pada lati fi orukọ mii -ii ranṣẹ, wọn lawọn si mọ pe Oluọmọ ati Adijat Adelẹyẹ lo n ṣiṣẹ ọhun.

Idi niyii ti wọn fi sọ pe awọn ko nii gba kawọn eeyan ọhun lo agbara le wọn nitori Kushimọ ni gbogbo ẹgbẹ faramọ.

Oniroyin wa ba Ọlakunle Oluọmọ sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan yii, o ni ko si ootọ ọrọ lori nnkan ti wọn sọ ati pe Kushimọ to jawe olubori ọmọ daadaa ni.

O ṣalaye pe oun ati oludije naa ko ja,ṣugbọn ẹni to faa kalẹ lawọn ko jọ wa pọ. Bẹẹ lo ni loootọ oun ko dibo fun lọjọ naa.

Amọ bo ṣe jawe olubori loun ti ki i ku oriire, koda laaarọ ọjọ keji, oun si pe lori foonu toun ki i, to si tun pe oun pada.

Oluọmọ sọ pe awọn ti fi orukọ rẹ ranṣẹ si Gomina, amọ ti wọn da a pada pe orukọ oludije mẹta to ṣe daadaa ni ki wọn fi ranṣe, ipo kin in ni naa lo ni Kushimọ wa, ko si nnkan to n jẹ dabaru, nitori pe ọmọ daadaa ni.

Aṣẹ to ni o wa lati oke lawọn tẹle.Oniroyin wa pe Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ naa, ko gbe ipe wa bẹẹ la tun tẹ atẹjiṣẹ ti koo da pada.

No comments:

Post a Comment

Pages