Bi ẹgbẹ NNPP yoo ṣe gbajọba ipinlẹ Ogun lo jẹ wa logun- Alaaja Sakirat Idris Arowolo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 19 October 2024

Bi ẹgbẹ NNPP yoo ṣe gbajọba ipinlẹ Ogun lo jẹ wa logun- Alaaja Sakirat Idris Arowolo


Bo tilẹ jẹ pe ariwo tawọn kan pa ni pe wahala to wa ninu ẹgbẹ oṣelu NNPP ipinlẹ Ogun ti fẹẹ ki wọn yọ ọwọ wọn kuro ninu ibo ijọba ibilẹ to bọ, ṣugbọn ni bayii, Alhaaja Sakirat  Idris Arowolo, akọwe fẹgbẹ naa ti sọ pe ko si ootọ ninu ẹ.

Gẹgẹ bi alaye to ṣe, o ni digbi lawọn wa tawọn si ti n murasilẹ. o ni loootọ lọrọ naa wa nile ẹjọ tẹlẹ eyi ti alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Sunday Ọginni gbe wọn lọ.

Amọ lọsẹ to kọja lawọn gba idalare to si mu kawọn ajọ to n ṣeto ibo naa OGSIEC, se ayẹwo fawọn oludije wọn pata.

O fikun ọrọ ẹ pe gbogbo igba ti wọn ba sọ pe ibo ya lawọn ti wa ni imurasilẹ nitori akoko ti wahala naa n lọ lọwọ awọn ko figba kan turasilẹ tawọn ba iṣẹ lọ lọtun losi.

Lori igbesẹ ti ajọ OGSIEC n gbe nipa owo kanpa ti wọn ni kawọn oludije san fun ibo ijọba ibilẹ naa, Arowolo sọ pe oun ko le sọ nnkankan nipa ẹ nitori ọrọ naa ti wa nile ẹjọ, ofin ni yoo si bawọn yanju ẹ.

O sọ pẹlu idunnu pe o fẹẹ jẹ pe awọn obinrin lo pọju ninu ẹgbẹ naa ti wọn si n kopa to jọju lati ojule de ojule lati polongo ẹgbẹ naa fawọn araalu.

O ni ko si nnkan tawọn ọkunrin ṣe ninu ẹgbẹ naa tawọn obinrin ki i figbakgba ninu ẹgbẹ ọhun, gbogbo wọn lo si mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ẹgbẹ.

O waa pari ọrọ ẹ pe gbogbo wahala to n waye ninu ẹgbẹ ọhun lo ti dopin,eyi to si jẹ won logun bayii ni bi NNPP yoo ṣe gbajọba ipinlẹ Ogun lọdun 2027.

1 comment:

Pages