Ẹ jẹ ka sa agbara lati jẹ ki isọkan tubọ mu orileede wa goke agba- Kushimọ
Oludije fun ipo alaga ijọba ibilẹ Ifọ, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Idris Ọlalekan Kushimọ tun ti ran gbogbo ọmọ orileede yii leti pe pataki ni lati sa agbara ati isọkan lati mu orileede yii goke agba.
O sọrọ yii nibi atẹjade to fi ki gbogbo awọn ọmọ orileede yii papajulọ ipinlẹ Ogun ati ijọba ibilẹ Ifọ ku ayẹyẹ ọjọọbi ọdun mẹrinlelọgọta ti ilẹ wa gba ominira.
Kushimọ sọ pe ipa pataki lawọn agbegbe n ko lati mu ilọsiwaju ba orileede nitori naa lo ṣe rọ awọn eeyan igberiko lati ma ṣe fa sẹyin lori idagbasoke awujọ.
O fikun ọrọ ẹ pe erongba yii lo wa lọkan oun toun fi jade dupo alaga ijọba ibilẹ Ifọ, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ninu ibo ti yoo waye laipẹ yii.
Oludije naa tun ṣalaye pe bi ifọwọsowọpọ ba fi le waye, ti wọn si fọwọ wẹ ọwọ,o da oun loju pe idagbasoke ati iṣejọba tuntun yoo waye ti irẹpọ yoo si jọba pẹlu.
O waa rọ gbogbo mutumuwa niyanju lati wo awokọṣe rere awọn to ti kopa pataki fun ominira orileede yii lati fi ṣamulo awọn agbegbe wa.
O gbadura fun ayọ, alaafia ati isọkan to wa ninu ayajọ ayẹyẹ ominira fun gbogbo ọmọ orileede, ipinlẹ Ogun ati ijọba ibilẹ.
No comments:
Post a Comment