Idaamu Taye Currency; Ojoojumọ lawọn oloolufẹ ẹ pada lẹyin ẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 20 October 2024

Idaamu Taye Currency; Ojoojumọ lawọn oloolufẹ ẹ pada lẹyin ẹ



-Wọn lọkan oun gan-an ko balẹ mọ

Asiko ta a wa yii ki i ṣe eyi to dara fun gbajumọ onifuji nni, Alaaji Taiwo Akande Adebisi, tọpọ mọ si Taye Currency, latigba ti wọn lo ti huwa arifin si ẹni ti wọn gba gẹgẹ bi ọga ẹ nidii iṣẹ fuji, Iyẹn Alaaji Wasiu Alabi Pasuma.

Bo tilẹ jẹ pe Currency ti tọrọ aforiji, to ti fi ẹnu gbolẹ lati ko gbogbo ọrọ to sọ jẹ, to si ni ki Pasuma atawọn agba onifuji  mii-ii to forin bu bii Ṣẹfiu Alao ki wọn dariji ji oun fun gbogbo awọn nnkan to ka gẹgẹ bi aṣiṣe to forin gbe e jade, sibẹ ṣe lawọn oloolufẹ fuji  sọ pe ko tii tan ninu wọn.

Wọn sọ pe ki i ṣe iru Currency lo yẹ ko forin bu Pasuma nita gbangba, to si fi n gba irawọ kaakiri pẹlu iha tiyẹn kọ si latilẹ, ti wọn si jọ wa ninu ẹgbẹ Arabanbi, ko to di pe Pasuma di ọga nla, ti Currency si gba ipo Ọga nla.

Bẹẹ lo ṣe je pe ipasẹ Pasuma yii lo jẹ ki aye mọ Currency, ṣugbọn ti wọn lo ti gbagbe gbogbo ajọṣepọ to wa laarin wọn, to fi gba ẹṣu laye lati maa tabuku, to si fẹẹ ma gberaga si aṣiwaju ẹ. Koda wọn ni gbogbo ẹbẹ to n bẹ yẹn, ko tii tan ninu wọn wọn, ayafi toun ba gba ọja lọ, ko lọ bẹbẹ lọja.

Iwadii fi ye pe ọpọ awọn oloolufẹ ni wọn ti n pada lẹyin ẹ bayii tawọn kan si n leri pe ko gbọdọ wa si Eko, ko di Ibadan ẹ mu. Bẹẹ la gbọ pe ọkan oun naa ko balẹ mọ nitori iwa arifin to hu.

 

No comments:

Post a Comment

Pages