Ọgbẹni Olubunmi Olukanni, tọpọ awọn eeyan mọ si Ojiṣẹ Iṣẹdalẹ ti sọ idi pato to fi ṣatupalẹ ewi ti Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka kọ ni ede oyinbo to pe ni Abiku si ede abinibi wa taa mọ si Yoruba.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka jẹ ẹni ti oun wo bi awokọṣe nipa ẹbun ti Ọlọrun fi jinki wọn, to si jẹ pe ko tii si afiwe iru ẹda bi tiẹ nilẹ Afrika.
Ọkunrin ọhun to n gbe ni Califonia,to tun jẹ alukoro fun ẹgbẹ ọmọ Yoruba ati ẹgbẹ ọmọ Ijẹṣa to wa lọhun, tun fi kun ọrọ ẹ pe oun kọ ewi ọhun lati fi ṣapọnle Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, fun ti ayẹyẹ aadọrun ọdun to pe lorilẹ.
O tun sọ pe bi wọn ba pe ori akọni, a fi ida laalẹ bẹẹ lọrọ agba ọjẹ yii jẹ ninu ka kọ itan tabi ewi to fa ọgbọn yọ, to si tun mu ẹwa ba aṣa ilẹ wa.
Ojiṣẹ iṣẹdalẹ toun naa jẹ onkọwe, to fi n gbe aṣa ati ede Yoruba ga, lo ti fi ọgbọn atinuda ẹ ṣagbekalẹ ewi Abiku lọna ti yoo gba ye awọn to ba n ka a.
Bẹẹ lo si tun lo awọn ẹwa ede bi Ọjọgbọn Ṣoyinka, ṣe gbe kalẹ ni oyinbo to kọ. Eyi ni bi ewi ọhun ṣe lọ ni sisẹ-n-tẹle:
""Òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ ni ẹ̀gbà ọwọ yín ńṣe
Oògùn Olobiripo tí ẹ nsọi mọ́ mi lẹ́sẹ́. Èmi ni àbíkú, tí ó ti wá ní ẹ̀ẹ̀kíní àti àwátúnwá
Njẹ́ mo ń sunkún fún ewúrẹ́, tàbí owó ẹyọ ni? Fún epo pupa, tàbí eérú didakiri. Iṣu kii mà ńso itakun láti so ẹsẹ̀ Àbíkú mọ́lẹ̀.
Nítorí náà tí ẹ bá ti sún ìgbín tìkarahun-tìkarahun,
ẹ le fi kọọ́ mi láyà, kí ẹ bàa lè dá àwáàtúńwá Àbíkú mọ̀.
Emi ni eyín ọ̀kẹ́rẹ́, tí tú àdììtú ekùrọ, ẹ ṣe ìrántí èyí, kí ẹ baà lè gbémi sì kòtò jíjìn, ílẹ̀ oòṣà.
Alailọjọ, elebibi arobo ni mí, tí ẹ ba titori eyi rúbọ
ika yín a máa tọ́ka orírun mi, ilẹ̀ tútù, ilẹ̀ olómije.
Ni ibi eji owuro tii pàgọ́ fun ẹyẹ aláìní ìyẹ́. Ibi tí ìrọ̀lẹ́ tii nba Alantakun ṣe ore páńpẹ́ fun eṣiṣin ninu ẹ̀fúùlẹ̀lẹ̀.
Bí alẹ́ bá ti lẹ́, Àbíkú a máa mú epo àtùpà, Ẹyin ìyá, èmi ni ejò adaniloro tíì lugọ̀ sì enú ọ̀nà àbáwọlé, tii fún ní ní ipayínkeke.
Èso pipọ́n julọ ni eso ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. Nínú ìhà ìbẹ̀rùbojo ni Àbíkú tí ń ké mọ̀wuru-mọ̀wuru,
tìi mọ saare òkú láti inú oyún wá.
Ojiṣẹ Iṣẹdalẹ ti waa mu da gbogbo awọn ọmọ kootu- ojiire loju pe oun ko nii figba kan rẹwẹsi nipa gbigbe aṣa ati ede wa larugẹ.
No comments:
Post a Comment