Bolu Owotọmọ, to jẹ kọmiṣanna feto ọgbin, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ojoojumọ nijọba ipinlẹ Ogun n wọna lati fopin si ipenija tawọn araalu n koju lori ọwọngogo to n deba ọja lorileede yii.
Ọkunrin naa sọrọ ọhun lakooko tawọn agbẹ ti wọn sin ẹja nijọba ibilẹ Ado-Odo-Ọta n kore ẹ, pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ Ogun labẹ akoso ẹka akanṣe to n ri si ayipada ọrọ aje.
O ṣalaye pe isakoso ọhun ti bẹrẹ igbesẹ lati maa fatilẹyin wọn han fawọn agbẹ lori ipese ounjẹ pọ si bẹẹ ni adinku yoo si de ba iye ti wọn yoo maa ta lọja.
Iwadii wa fi ye wa pe ẹgbẹrun kan awọn agbẹ ti wọn si ẹja, ni wọn pin si isọri mẹta, ti wọn si ṣe iranwọ fun pẹlu baagi mejilaadọrin ounjẹ ẹja, eyi ti wọn san ida aadọrin ninu ẹ nigba tijọba si n san ida ọgbọn yooku.
Owotọmọ tun fikun ọrọ ẹ pe ijọba n fi atilẹyin yii han sawọn agbẹ ọlọsin ẹja lati le ri pe iye ti wọn ta awọn ẹja laarin ọja dinku si ti tẹlẹ.
O ni eyi jẹ ọkan lara erongba Aarẹ Bọla Tinubu lati le jẹ ki ounjẹ pọ yanturu pẹlu afikun pe awọn agbẹ naa ti ṣeleri pe awọn yoo tẹle igbesẹ yii ki oun gbogbo le fi tubọ lọ bo ṣe yẹ ko lọ.
Ninu ọrọ Oluṣeyi Olugbire, to jẹ alamojuto akanṣe ni ẹka nileeṣẹ ọhun, to ṣoju alakoso akanṣe Mosunmọla Owo-Odusi, o dupẹ pupọ lọwọ awọn agbẹ fun ifarajin wọn bẹẹ lo tun lo anfaani naa lati fi ke si awọn agbẹ yooku lati darapọ mọ anfaani ti ileeṣẹ naa, OGSTEP la kalẹ lati le rii pe ipinlẹ Ogun lawọn ounjẹ to pọ yanturu.
Ninu ọrọ Ọgbẹni Niyi Ọpẹbiyi, to jẹ alakoso fun oṣin ẹja, o gboriyin fun OGSTEP, lori bi wọn ṣe ṣagbekalẹ eto ọhun, eyi to ni o ran awọn agbẹlọwọ kaakiri ipinlẹ naa.
Ebenezer Jinadu, toun jẹ alakoso OGSTEP, nijọba ibilẹ Ado Odo Ọta, dupẹ pupọ lọwọ Gomina Abiọdun fun atilẹyin ẹ fawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ yii.
Bẹẹ lo tun rọ wọn lati ṣiṣẹ lori awọn ọna to bajẹ, ki wọn ṣatunṣe lee lori, eyi to ni yoo tubọ mu irọrun bawọn araalu.
No comments:
Post a Comment