Wọn ti rọ awọn oloye meje niluu Orile-Ilawọ ti wọn ta ilẹ onilẹ loye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 2 November 2024

Wọn ti rọ awọn oloye meje niluu Orile-Ilawọ ti wọn ta ilẹ onilẹ loye



Awọn oloye meje ti wọn ni wọn ta ilẹ onilẹ niluu Orile-Ilawọ, ni ọba Oluṣẹgun Mac Gregor, ti paṣẹ pe awọn ti rọ wọn loye ati pe ki i ṣe awọn lawọn fi wọn joye tẹlẹ.

Lara awọn oloye tọrọ naa kan ni Samson Oluwọle Dosunmu to jẹ Oluwo, Abraham Adebayọ Adisa Ṣoyọye, to jẹ Balogun ati Fatai Ṣodimu to jẹ Jagunna ni awọn mẹtẹẹta ti Ọba MacGregor loun rọ loye.

 

Iwadii fi ye wa pe o ti pẹ tawọn eeyan ọhun ti gbilẹ lati maa ta ilẹ ilu, to si jẹ ti wahala ba ti ṣẹlẹ ọdọ Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo, ni wọn maa n sa lọ latigba wọn silẹ.

 

Koda a tun gbọ pe lara awọn ilẹ to ti da wahala silẹ lakooko yii ni ilẹ ilu ti wọn tun ta fawọn ọba alaye kan, to si ti da wahala silẹ, nitori bawọn to nii ṣe sọ pe ayederu lawọn to ta ilẹ naa.

 

Ninu ọrọ ọba Orile-Ilawọ,  o sọ pe kayeefi lo jẹ pe ilẹ ọhun to to eeka ẹgbẹrun kan ati ẹgbẹta lawọn eeyan ọhun ti ta danu, to si ni o lodi sofin ilu yii lati ma ta ilẹ paapaa fawọn ajoji.

 

Ọba Mac Gregor sọ pe "Awọn eeyan yii ki i ṣe oloye mi, nitori pe ọba miran ni wọn n ṣatilẹyin, kii ṣe emi, ọdọ ọba naa si ni wọn ti n ṣe ipade wọn, kii ṣe ilu Ilawọ.

 

O ni ọdọ Oṣilẹ Oke-Ọna lawọn ti wọn n pe ara wọn ni oloye Ilawọ ọhun ti joye, ki i ṣe lọdọ oun, ki wọn ye pe ara wọn ni oloye ilu wọn mọ, bi wọn ko ba fẹẹ ki wọn fọwọ ofin gbe wọn.

 

Ọba naa sọ ṣalaye pe  "Ninu igbimọ afọbajẹ, a ni awọn Ologboni, Ologun ati Olorogun. Oluwo ni olori awọn Ologboni. Samson Oluwọle Dosunmu to n pe ara rẹ ni Oluwo kii ṣe Oluwo ilu Ilawọ mọ, Baala Oke-Ọna ni; Abraham Adebayọ Adisa Ṣoyọye to n pe ara rẹ ni Balogun kii ṣe Balogun ilu Ilawọ mọ, Baṣọrun Oke-Ọna ati Akọgun Ẹgba lo jẹ.

 

"Eyi to n pe ara rẹ ni Jagunna, Fatai Ṣodimu ko ri bẹẹ mọ. Awọn olori awọn oloye ree, ati pe wọn tun ṣi ni awọn oloye miran labẹ wọn ti wọn jọ n huwa buruku yii.

 

"Ẹnikan wa to n pe ara rẹ ni igbakeji Oluwo, Olufẹmi Adebayọ Adenaike lorukọ rẹ, o n tan ara rẹ jẹ ni, ko si ẹni to n jẹ Aro Ilawọ ninu iwe akọsilẹ mi. A tun ni ẹnikan to n pe ara rẹ ni Ogboye Ilawọ, Isaac Olubanji Ọlaogun lorukọ rẹ, ko si ninu iwe akọsilẹ mi rara.

 

"Ẹnikan naa tun wa to n pe ara rẹ ni Ẹkẹrin Ilawọ, Oluwọle Ayọrinde lorukọ tiẹ; eyi to n pe ara rẹ ni Bada Ilawọ, Joseph Abiọdun Ṣowunmi; to fi mọ eyi to n pe ara rẹ ni Mayegun Ilawọ, Rilwan Tajudeen Abudu.

 

"Bẹẹ naa la tun ni Ifayẹmi Adisa to n pe ara rẹ ni Baasẹmọ, ati Lawrence Ogunsanya to n pe ara rẹ ni Apagunpọtẹ, gbogbo awọn wọnyi ni mo fẹ ki gbogbo agbaye mọ pe wọn kii ṣe oloye niluu Ilawọ mọ.

 

"Abẹ Oke-Ọna ni wọn n sapamọ si lati ṣiṣẹ ibi wọn yii. Idi ti nko ṣe tete sọrọ sita ni pe mo farabalẹ ṣe iwadii kikun lori wọn, mo si mu wọn lọrun ọwọ, lẹyin ti aṣiri tu sita."

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages