Aṣeyọri nla ni aṣọbode ti ṣe lati mu ajọṣepọ okoowo ba Idiroko- Shuaib - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 13 February 2025

Aṣeyọri nla ni aṣọbode ti ṣe lati mu ajọṣepọ okoowo ba Idiroko- Shuaib



Ọga agba fun ajọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Salisu Mohammed Shuaib, ti sọ awọn aṣeyọri to lapẹẹrẹ ti ẹnu bode ilu ni Idiroko ti mu ba okoowo ọrọ aje, eyi to sọ pe ko ṣe e fẹnu royin.

O sọrọ ọhun nibi eto kan to waye to nii igbelarugẹ aṣa ati iṣe, eyi ti wọn pe ni ayajọ aṣa ati iṣe fun idagbasoke ọrọ aje, ẹlẹẹkẹrin iru ẹ, to waye ni Idiroko, nipinlẹ Ogun.

Akọle nnkan ti wọn jiroro le lori lọdun yii ni 'Ẹnu-Bode, ki lo jẹ ati ki lo de to fi ṣe pataki' Nibi tọrọ kan lorileede Naijiria ati Benin, ti jọ jiroro lori ipa ti okoowo n ko ninu idagbasoke aṣa.

Ọga agba asọbode naa ṣakiyesi pe okoowo ki i ṣe nipa ọja nikan bi ko ṣe pe o tun jẹ ki ajọṣepọ to danmọran wa laarin orileede, bẹẹ lo ni o tun mu agbọye wa, to si n jẹ ki alaafia jọba pẹlu.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, Dokita Bonny Abisogun Botoku, to jẹ ọga fawọn to ṣeto naa sọ pe o gboriyin fawọn aṣọbode atawọn alabojuto ẹnu aala lori ọna ti wọn gba lati jẹ ki aabo to peye wa lori ọrọ okoowo lawọn agbegbe naa.

O ṣapejuwe ẹnubode gẹgẹ bi ibi towo n gba wọle, to n pese iṣẹ ati ibi ọja ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin. Lara awọn nnkan to waye lọjọ naa ni idanilẹkọọ to waye nibi ti igbakeji ọga kọsitọọmu  C Amaweh, ti sọ nipa ipenija ti wọn koju ati ọna abayọ bẹẹ lo tun mẹnuba ọna igbooro laye ode oni.


No comments:

Post a Comment

Pages