Ẹ gba mi, ẹ ma jẹ ki wọn pa mi bi wọn ṣe pa baba mi- Ọmọọba Adekọya Adefowora - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 9 February 2025

Ẹ gba mi, ẹ ma jẹ ki wọn pa mi bi wọn ṣe pa baba mi- Ọmọọba Adekọya Adefowora




Ọmọọba Adekọya Babajide Adefowora, to jẹ ọmọ bibi Ọba Adeyemi Adedayo Adefowora, Alaketu, tiluu Ẹpẹ, to waja lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun 1999, ti ke si gbogbo awọn ọmọ orileede yii ki wọn jọ ki wọn gba oun lọwọ awọn to fẹẹ da ẹmi oun legbodo, nitori ọrọ oye ọba.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ọkan oun ko balẹ, nitori bawọn kan niluu ṣe n dunkoko mọ oun,latigba ti wahala ipo ọba naa ti wa nile ẹjọ.

 

O sọ pe wọn fẹẹ maa lo ọwọ agbara lati maa fi pa awọn ti wọn le ṣoootọ lẹnu mọ, bẹẹ lo ni wọn tun dunkoko mọ wọn pẹlu, nitori wọn ti mọ pe ẹyin oun ni awọn araalu wa.

 

Ọmọọba Adekọya tun fi kun ọrọ ẹ pe idile kan ṣoṣo lo n jọba niluu Alaketu Ẹpẹ iyẹn Ọṣọkeji Atẹsimara bẹẹ lawọn ko gbọ pe awọn ti wọn pe ara wọn ni Adeọna jọba ri.

 

Ọkunrin naa waa fi iṣẹlẹ to waye lẹnu ọjọ mẹta yii fi ṣe apẹẹrẹ nibi gti wọn lobinrin kan ti lọ ka ọkan lara afọbajẹ ilu naa, Oloye Lateef Bello mọ afin, to si fẹẹ okun fun lọrun pa, ko to di pe ọwọ tẹ.

 

Adekọya ṣọ pe ka ni aṣiiri obinrin naa ko tu, to si gba ẹmi baba agbalagba ẹni ọgọrin naa lojiji ni ọtọ ni nnkan ti wọn kọ ba maa wi, to si le jẹ akoba nla foun.

 

Ọmọọba yii wa rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii ki wọn ma jẹ kawọn eeyan yii gbẹmi oun lojiji, nitori ẹru n ba oun lati wale nibi toun wa, nitori oun ko mọ iṣẹ ibi to wa lọwọ oun, ti wọn le ṣe.

 

O waa sọ pe oun nigbagbọ ninu igbẹjọ to n lọ lọwọ naa, toun si mọ pe idajọ ododo yoo waye nipa gbigba ẹtọ ọba ilu Keru Ẹpẹ le oun lọwọ.

No comments:

Post a Comment

Pages