Aṣọbode Ògùn fa apo igbó le ajọ to n gbogun ti oogun oloro lọwọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 6 March 2025

Aṣọbode Ògùn fa apo igbó le ajọ to n gbogun ti oogun oloro lọwọ




Lati le jẹ kawọn araalu mọ nipa akitiyan lori fayawọ atawọn to n ko awọn ayederu ọja wọlu, aṣọbode nipinlẹ Ogun ti fa apo to kun fun igbo, eyi to jẹ ẹgbẹrun mẹta ati ọọdunrun le marundinlọgọrin ati paali oogun kodiini tiyẹn jẹ mejidinlọgọrin le ajọ to n gbogun ti oogun oloro iyẹn NDLEA lọwọ.

Ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun, Mohammed Shuaib, lo n fa awọn ayederu ọja ọhun le ọga NDLEA, eyi ti Alexander Nyigide, toun naa jẹ ọkan lara ọga ajọ naa ṣaaju ikọ mẹfa, to wa ṣoju ọga wọn yii, Tijani Rabe, lakooko ti wọn ṣafihan awọn ọja tawọn fayawọ fi ọna ẹburu ko wọ orileede yii.

Shuaib ṣalaye pe igbo ati oogun kodiini yii jẹ ọkan lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn fayawọ laarin ọsẹ meji sẹyin lẹyin ti wọn jọ ṣe ipade pọ, nibi ti wọn ti ṣeleri pe awọn ṣetan lati gbogun tawọn to n gboogun oloro wọlu.

O fikun ọrọ ẹ pe nnkan tawọn ṣe yii ni wọn fi paroko ranṣẹ sawọn ti mu iṣẹ ọhun lọkunkundun, ti wọn ko niṣẹ mii-in ju ki wọn maa ko awọn oogun oloro yii wọlu lati le jawọ, nitori bi wọn ba kọ, awọn naa ko ni dẹyin lati gbena ija ko ju wọn.

O sọ pe gbogbo nnkan tọwọ wọn tẹ latọdọ awọn fayawọ ni owo ẹ to miliọnu lọna ọrunlenigba abọ naira. Lara awọn ọja ti ko bofinmu ọhun ni apo irẹsi, aṣọ tokunbọ, aloku taya,epo pẹntiroolu atawọn nnkan mii-in.

Shuaib tun sọ pe owo tawọn pa wọle le ni miliọnu mẹsan an naira ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le diẹ. o tun tẹnumọ pe ifasẹyin lawọn nnkan yii mu ba ọrọ aje wa ati pe ọwọ yoo tẹ awọn to n ṣiṣẹ ọhun atawọn onigbọwọ wọn.

O waa ni awọn ko ni rẹwẹsi tabi fa sẹyin lati koju awọn oniṣẹ ibi ọhun. O rọ awọn araalu lati jọ ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn lati gbogun tawọn onifayawọ.

No comments:

Post a Comment

Pages