Baba mi o le wa lori oye aarẹ ki iya maa jẹ awọn araalu bayii, ki n wa sọ pe ọrọ ati jẹ gomina lo kan-Gbadebọ Rhodes-Vivour - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 9 March 2025

Baba mi o le wa lori oye aarẹ ki iya maa jẹ awọn araalu bayii, ki n wa sọ pe ọrọ ati jẹ gomina lo kan-Gbadebọ Rhodes-Vivour


Ki i ṣe pe  Gbadebọ Rhode-Vivour ṣẹṣẹ bẹrẹ oṣelu ṣugbọn ọdun 2023, ni okiki e jade gan-an nigba to jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Eko.

Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko, ko le gbagbe ọkunrin yii lakooko ibo gomina ọhun, nitori o fii lakalaka nigba naa lọhun.

Bo tilẹ jẹ pe titi di akoko yii igbagbọ awọn ẹgbẹ oṣelu Labour ni pe Gbadebọ lo wọle amọ ajọ INEC gbe e fun Sanwo- Olu ni. 

Ni bayii, Gbadebọ ti jade sita, o ba ikọ iroyin Yoruba,League of Yoruba Media Practitoiners, sọrọ lori iriri ẹ nipa ibo to kọja naa, ọjọ iwaju ẹ nidii oṣelu atawọn nnkan tawọn kan sọ nipa ẹ, ṣugbọn to tan imọlẹ si. Ọrọ to ba wa sọ niyii:


Orukọ mi ni Ayaworan-ile Gbadebọ Rhodes-Vivour, mo jẹ oludije sipo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo to kọja, iyẹn 2023. Bi mo ṣe jẹ ayaworan ile, bẹẹ naa ni mo tun jẹ oniṣowo, mo si tun ni imọ nipa imọ ẹrọ tẹkinọlọji, bẹẹ ni mo tun jẹ aarẹ fun ajọ Rhodes Vivor, eyi to da lori aabo lori ẹmi fun oriṣiriṣi agbegbe nipinlẹ Eko.

Ọpọ awọn eeyan lo jẹ pe bi wọn ba n ṣaisan, agbo ni wọn yoo lọ gbe mu, to ba si ya, wọn maa sọ pe awon ni aisan ọkan ati kidinrin. A fẹ ki awọn eeyan bẹrẹ sii lo oogun nipa ayẹwo ti wọn ba ṣe, ki wọn si gba itọju lati ọdọ awọn dokita. Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti jẹ anfaani, o si maa n mu ori mi wu.

Agbegbe Isalẹ Eko ni ẹbi Rhodes Vivor ti wa, ojule kejidinlogoji, agbegbe Igboṣere ni ile wa, ibẹ ni wọn fi kọ City Hall lonii, nitori pe mọlẹbi fun ijọba ipinlẹ Eko ni ilẹ naa. Bi mo ṣe jẹ ololufẹ ipinlẹ Ekoo naa ni mo jẹ ololufẹ Naijiria, ati ọmọniyan lapapọ.

*Bawo ni igbe aye yin lẹyin eto idibo ọdun 2023?

Mo dupẹ lọwo Ọlọrun wi pe a tun ṣi le duro lori ẹsẹ wa, a ja fun ẹtọ wa titi de ile ẹjọ agba lorileede yii, a si rii daju pe a ko panumọ, a n jẹ ki ijọba mọ awọn aṣiṣe wọn lori igbesẹ ti wọn n gbe. A tun jẹ ki awọn eeyan mọ pe ijọba nlo awọn owo wa lati fi ṣe ariya ẹgbẹ oṣelu APC, ati iye owo ti wọn n na lori awọn ọkọ, eyi to goke ni ida mẹta iye ti wọn n ta awọn ọkọ naa lọja.

A ti sọ nipa ọpọ ohun tijọba n ṣe, eyi ti kii ṣe nipa ifẹ tabi anfaani araalu, a ko lọ sun rara gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n sọ pe awọn oloṣelu to ba padanu maa lọ jokoo jẹ ni, ti temi ko ri bẹẹ rara.

Bakan naa la tun n ṣiṣẹ ilu, ti a si n ba awọn araalu sọrọ ilanilọyẹ, bakan naa la tun ti n ṣagbeyẹwo awọn aṣiṣe ti a ti ṣe sẹyin lati rii pe a tẹsiwaju. A si tun maa rii daju pe a jade daadaa lasiko ti oṣelu miran ba tun wọle de.

*Nipa jijẹ ọmọ Eko pataki, njẹ ẹ tiẹ n gbiyanju lati kọ awọn ọmọ yin nipa aṣa ati iṣẹṣe Yoruba?

Bẹẹ, dajudaju. Aṣa Yoruba jẹ ọkan pataki lara awọn iwa Ọmọluabi, eyi to nii ṣe pẹlu orukọ rere, eyi to tunmọ si diduro lori ọrọ ẹni, ati jijẹ eeyan daradara lawujọ.

Yatọ si eyi, o tun jẹ nipa kikọ ede, mimọ ede. Eyi si jẹ ohun ti ọpọlọpọ wa, iyẹn awọn iran mi, koda titi di oni, pupọ awọn ọmọde ti wọn jẹ Yoruba ni wọn ko le sọ ede Yoruba.

Idi ni pe wọn ko sọ ede naa si wọn bi wọn ṣe n dagba, tabi ko jẹ pe ile-ẹkọ ti girama ti wọn ti n pe ede Yoruba ni fanakula ni wọn lọ, ti wọn yoo si jiya rẹ niru ile-ẹkọ bẹẹ. Fun idi eyi, a ni ojuṣe lati jẹ ki awọn eeyan bẹrẹ si kọ ede Yoruba, ti emi naa si n kọ awọn ọmọ mi ni ede Yoruba, ko ma lọ di pe wọn yoo koju iṣoro ti mo koju, eyi to jẹ pe agbalagba ni mo fi n kọ ede Yoruba.

O rọrun lati kọ ede Yoruba lati kekere, iyẹn ni ọmọ ikoko titi ti wọn yoo fi dagba pẹlu rẹ. A si dupẹ pe oriṣiriṣi ikanni ayelujara lo wa, ati awọn iwe lo wa ti a le lo lati fi kọ ede Yoruba. Bakan naa lo tun ṣe pataki lati mọ itan wa. Ẹ si mọ pe itan Yoruba jẹ ọkan lara awọn itan to lagbara julọ.

Awọn eeyan lẹnubode Naijiria, ede Yoruba, aṣa ati Ifa, awọn nnkan wọnyi tobi ju Naijiria lọ lọdọ wọn. Bi ẹ ba lọ si awọn orileede bii Cuba, South Amerika, koda wa si ilẹ Egypt, gbogbo awọn nnkan wọnyi lo tan mọ aṣa Yoruba. Idi ree to fi jẹ pe kii ṣe aṣiṣe bi wọn ba sọ pe apa Ila Oorun ni Oduduwa ti wa. Bi ẹ ba wo awọn ọrọ kan lede Yoruba ati ni Kemetu, eyi to je ede Egypt, ẹ maa rii pe pipe wọn ko yatọ sira wọn.

Fun idi eyi, a ni lati wo itan wa jade kuro lorileede Naijiria, ka si tan an lọ si awọn ile Afrika, o jẹ nnkan ti mo fẹran daadaa.

Njẹ ẹ ṣo fun wa pe bi ẹ ba de ipo, ẹ maa ṣoju ẹsin Yoruba daadaa?

Ko si nnkan to buru nibẹ. Ohunn to jẹ isoro nile aye yii ni pe iroyin buburu lo maa n sare tan ju iroyin gidi lọ. Njẹ o yee yin? Bi a ṣe n sọrọ yii, beeyan ba ṣe nnkan ti ko dara, loju ẹsẹ lo ti maa sare de ọdọ awọn eeyan ko lero; ṣugbọn teeyan ba ṣe nnkan gidi, o le gba to ọsẹ kan tabi ọsẹ meji ko to di pe awọn eeyan bẹrẹ sii gbọ.

Ohun ti Ifa jẹ, Odu, eyi to dara ati eyi ti ko dara, ipilẹ rẹ lo bi ẹrọ kọmputa ti a n lo lonii, koda, ohun naa lo bi foonu ti a gbe dani, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko mọ. Nigba ti awọn oyinbo alawọ funfun de, ti wọn si kẹkọọ nipa gbogbo ohun ti Yoruba ni, eyi lo jẹ ki awọn naa lo bẹrẹ sii ṣe oriṣiriṣi ti wọn fi aṣiri rẹ pamọ. Nigba ti wọn sọ analọọgi (analog) de, wọn ni ohun to n jẹ bainari (binary) naa wa, eyi to jẹ aṣiri. Awọn nnkan wọnyi ni wọn ṣe kọmputa, ẹ si wa wo ibi ti a wa lonii.

Bi awọn iya kan lo jẹ pe bi ọmọ wọn ba gbọ pe oun fẹ lọ ko Ifa, niṣe ni yoo bẹrẹ sii gbadura, ti yoo bẹrẹ sii sunkun, ti yoo maa sọ pe ọmọ naa nilo lati lọ fun adura itusilẹ, ṣugbọn awọn nnkan wọnyi ṣe pataki, ti a si gbọdọ ṣamulo rẹ. Ọpọ wa ni Naijiria, bi awọn ọmọ wa ba sọ pe awọn fẹẹ lọ ile aworan lati wo sinima ‘Thor’, ko sẹni to maa sọrọ sii, ṣugbọn wọn ti gbagbe pe ko si iyatọ ninu fiimu ti wọn fẹẹ lọ wo ati Sango.

Nigba ti eto idibo 2023 pari, mo koju ọpọ iṣoro pẹlu orunkun mi, to jẹ pe nko le gun akaba lọ soke. Mo ni lati lọ siluu oyinbo fun itọju, ibẹ ni wọn ti sọ pe maa MRI, ti mo si ṣe e. Wọn ni wọn maa paarọ orunkun mi, ṣugbọn mo sọ pe nko le ṣe e. Bi mo ṣe n jade kuro lọsibitu naa bọ sita, mo ri ogun ibilẹ China kan nibẹ, mo si sọ pe ki n gbiyanju rẹ wo, niṣe lo dabi ẹni pe Jesu fọwọ kan mi.

Loju ẹsẹ nibẹ ni mo kuro lẹni to n tamurege, ti mo si bẹrẹ sii rin daadaa. Mo ni lati ronu pe ki ni awa n jẹ ara wa niya fun ni Naijiria, nigba ti a ba n lo oogun lati fi ba ọkan ati kidinrin wa jẹ. A ni lati nnkan ibilẹ wọ ilana eto ilera wa ni Naijiria, nitori pe awọn China n lo nnkan ibilẹ wọn lati fi wo ara wọn san pẹlu eto ẹkọ.

A ko le sọ pe awọn nnkan ti a ni ko to di pe awọn oyinbo alawọ funfun de ko dara, a wa nilo lati ko gbogbo rẹ danu. Mo ni ọkunrin kan to sọ fun mi lọsẹ diẹ sẹyin wi pe oun ti pada si fasiti lati kọ Ifa. Awa naa nilo lati gbaruku ti awọn nnkan ibilẹ ati aṣa wa.

Njẹ ẹni iba ṣe pọ pẹlu awọn oloye tabi ọba alaye?
Bẹẹni, mo ni ibaṣepọ pẹlu oloye ati ọba to pọ. Bii baba ni Ọọni Ile-Ifẹ jẹ si mi, a ni ibaṣepọ to dan mọnran, ti wọn si tun fun mi ni aami-ẹyẹ bakannaa ni mo tun ni ibaṣepọ pẹlu Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams.

Ko tan sibẹ, mo ni ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu Ọba Akran ti ilu Badagry, ti mo si ni ibaṣepọ pẹlu ọpọlọpọ oloye oni fila funfun nipinlẹ Eko pẹlu.

Mi o si ti jawọ, mo si ma ba wọn ṣe siwaju si nitori mo ni lọkan pe ti mo ba de ori oye gẹgẹ bi gomina, iṣakoso mi yoo faaye gba awọn ọba ati oloye lati wa ninu awọn ti wọn yoo maa ṣagbekalẹ eto ati ilana, paapaa eyi to ba nii ṣe pẹlu agbegbe wọn. A ma maa bere ohun ti wọn ba fẹ ka ṣe fun wọn, nitori awọn ni wọn mọ nnkan ti wọn n fẹ. A ko le sọ pe a fẹẹ ṣe opopona lai ba awọn ọba agbegbe naa sọrọ lati mọ bi wọn ṣe fẹẹ si, tabi nnkan ti wọn fẹ. Awa le sọ pe a fẹẹ ṣe opopona fun wọn, ko lọ jẹ ile-ẹkọ lo n je wọn niya.

Wọn sọ pe ipinlẹ Eko ni awọn igbimọ apaṣẹ ti a mọ si ‘Governor’s Advisory Council, GAC; ẹ beere pe njẹ awọn ọba alaye ni aṣoju ninu igbimọ naa. Mo si fẹẹ sọ fun un yin pe kii ṣe gbogbo awọn to wa ninu igbimọ naa ni wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Eko, ida marundinlọgọrin wọn ni kii ṣe ọmọ Eko. Gomina le sọ pe awọn n ṣiṣẹ, ṣugbọn awọn araalu ko ni imọlara awọn iṣẹ naa, ko yẹ ko ri bẹẹ, nitori pe wọn ko fi to wọn leti.

Ki lo de ti Ọba Eko ko ni aṣoju ninu igbimọ GAC, ko bojumu to. Wọn ro pe nitori to ti jẹ ọrọ oṣelu, ṣugbọn igbimọ GAC ko yẹ ko jẹ ti oṣelu rara, nitori pe igbimọ igbanimọran ni wọn pe e. Ipa to pọ ni igbimọ ọba yoo ko ninu igbimọ GAC naa, nitori pe ọna ti wọn n gba lati ji ilẹ awọn eeyan jẹ eyi to n kọni lominu. Bi apẹẹrẹ, Dangote jade sita wi pe oun san biliọnu lọna igba lati ra ilẹ to fi kọ ileeṣẹ rẹ to wa ni Ibẹju Lẹkki, ṣugbọn awọn eeyan ko gbọ nnkankan, wọn ko si jẹ anfaani nibẹ, bẹẹ si ni ko si idagbasoke kankan ti wọn  jẹ anfaani rẹ bii opopona, ile-ẹkọ ati awọn miran.

Lori wahala to n ṣẹlẹ lẹgbẹ oṣelu Labour lasiko yii, ki ni erongba yin fun idibo ọdun 2027?


Pẹlu ogo Ọlọrun, mo maa dije dupo gomina ni ọdun 2027. Ki ṣe pe mo padanu si ọwọ Sanwo-Olu tẹlẹ naa, awọn ni wọn fi ọwọ ọla gba wa loju, ẹ sọ pe ẹ bori idibo, ṣugbọn awọn araalu ko ṣe idaraya lati ṣajọyọ. Nibo ni awọn ẹẹdẹgbẹrin ti wọn dibo naa wa. Wọn mọ oṣelu ti wọn ṣe lọjọ idibo, abi bawo ni oro yoo ṣe ma jade ni ọjọ idibo.

Ọmọ idile Oro ni mi, orukọ Rhodes ti a n jẹ ni wọn yọ lati inu Orobiyi. Awọn oyinbo ni wọn yi orukọ wa, Orobiyi si Rhodes. Ọpọ awọn mọlẹbi ni awọn oyinbo yi orukọ wọn si ti oyinbo. Oṣelu ni wọn n fi Oro ṣe lasiko yii, kii ṣe lati fi fọ ilu mọ, gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe e laye atijọ. Oṣelu lo n jẹ ki awọn ọba wa padanu ipo wọn ati ọwọ ti wọn ni. To ba wa ya, a maa sọ pe awọn ọmọ wa ko bọwọ fun aṣa ati iṣẹṣe, ṣugbọn bi a ba wo buruku ti wọn n fi ipo ọba wa ṣe nkọ.

Laye atijọ, Ifa la fi n yan ọba, ṣugbọn lasiko yii, oloṣelu lo n yan ọba fun wa, ko yẹ ko ri bẹẹ. Ni ti erongba lati jade du ipo gomina ni 2027, mo ṣi maa jade, ati pe ko ṣija tabi wahala lẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko, ọkan ṣoṣo ni wa.

Awọn kan n sọ pe awọn obi yin ko wa lati Eko, ṣe loootọ ni?


Mo dupẹ awọn obi mi ṣi wa laye, ka ni wọn ko si laye mọ ni, boya nnkan miran ni ko ba ti ṣẹlẹ. Bawo ni nko ba ti ṣe ara mi, ọpọlọpọ ifọrọwerọ ni awọn obi mi ti ṣe lati fi ṣalaye fun awọn eeyan pe awọn ni wọn bi mi, ati ibi ti wọn bi mi si.

Ki ni erongba yin lori rogbodiyan to ṣẹlẹ nile igbimọ aṣofin Eko laipẹ yii?

Ohun to ba ni lọkan jẹ ni rogbodiyan to ṣẹlẹ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, idi ni pe Eko yatọ si awọn ipinlẹ yoo. Lọdun 1900, ki wọn too da Naijiria silẹ, ko sibi ti ọrọ oṣelu ti n ṣẹlẹ to kọja ilu Eko. Gbogbo oṣelu to n ṣẹlẹ ni Naijiria lo jẹ pe Eko lo ti n ṣẹlẹ, koda gbogbo eeyan yoo gbe oṣelu wọn wa sipinlẹ Eko ni, itan ilu Eko niyẹn. O wa ba ni lọkan jẹ lati rii pe awọn aṣofin ti wọn dibo yan l’Ekoo yẹyẹ ara wọn nita gbangba.

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa bi wọn digun wọ ile igbimọ aṣofin Eko, awọn wo wa ni wọn gbe wọbẹ. Wọn sọ pe wọn ri ibọn ni ọfiisi Ọbasa, iwadii wo ni wọn ṣe lori ẹ. Ki lo de ti wọn n tọju awọn nnkan ija ogun sile igbimọ aṣofin, ko sẹni to le dahun rẹ. Ọpọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ni wọn sọ pe wọn ko fẹ Ọbasa lori ẹsun ikowojẹ, ẹni to fi biliọnu mẹtadinlogun ṣe geeti ẹnu ọna abawọle.

Awọn ohun to n ba ni lọkan jẹ ni awọn nnkan wọnyii, wọn tun wa pada gbe sori ipo naa, o ti jẹ ka mọ pe awọn kii ṣe ara ile-igbimọ aṣofin, oṣiṣẹ Aare Bọla Ahmẹd Tinubu ni wọn.

Awọn ni Bola Ahmed Tinubu fi n ṣe alakoso ipinlẹ Eko, ki aṣiri gbogbo owo to n ko jẹ ma baa tu sita, ati pe ko le tubọ maa ni ikapa lori ilu Eko. Tinubu wa niluu Abuja, o n paṣẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ l’Ekoo.

A nilo ijọba ti yoo da eto ẹkọ gidi pada wa fun wa. Ẹ jẹ ka dibo fun ẹni to ma fi wa lọkan balẹ, a ni lo ijọba ti yoo fun awọn ọmọ wa ni ounjẹ ọfẹ nile-ẹkọ. Awọn nnkan wọnyi ni mo gbero lati ṣe ti mo ba ti dori ipo.

*Bawo ni igbaradi yin fun 2027, paapaa bi a ṣe n gbọ pe Ṣeyi Tinubu naa fẹẹ jade du ipo ọhun?*


Ọdun 2016 ni mo bẹrẹ oṣelu, nigba ti du ipo alaga ijọba ibilẹ Ikẹja, lẹyin yẹn ni mo tun dije du ipo aṣofin agba lọdun 2019. Bi awọn ọdọ ṣe jade fun idibo lọdun 2023 jẹ eyi ti ko ṣẹlẹ ri, paapaa l’Ekoo, kii ṣe pe nitori owo ti wọn gba, ṣugbọn nitori wọn n fẹ ayipada, ati ijọba miran. Awọn eeyan fi gbogbo ara si eto idibo to kọja yii kan ni níitori wọn fẹ ikan to yatọ ti mo dẹ ni idaniloju pe bi yi 2027 ṣe ma ri nìyẹn. Adura mi ni pe ki àwọn obi wọn naa ti oun ti awọn ọmọ wọn ti, pe anilo ìjọba ti yoo ṣe oun ọtun fun wa nipinlẹ Eko.

Lori ọrọ Seyi Tinubu, lotitọ to ba jẹ nipa ka fi ọdọ ṣe e, o ni ẹtọ lati dije ṣugbọn ṣe ko yẹ ki oju tii ni, ati pe ni asiko yii, awọn ara ilu Eko fẹ ọmọ Eko ni ori ipo gẹgẹ bi gomina.

Baba mi o le wa lori oye aarẹ ki iya maa jẹ awọn araalu bayii, ki n wa sọ pe ọrọ ati jẹ gomina lo kan mi kan, ki lo fẹ wa ṣe? O tunmọ si pe nko nifẹ araalu niyẹn, o tunmọ si pe nko bikita iya to n jẹ araalu niyẹn. Ṣe o fẹ tẹsiwaju ijiya ti baba rẹ fi n jẹ araalu lati oke ni? Mo ranti igba ti Aarẹ tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ wa lori ipo, gbogbo asiko naa lawọn to wa loke okun n sa wa sile, nitori pe Naijiria n dun lasiko yii, mo ranti daadaa. Ti ọmọ baba Ọbasanjọ ba sọ pe oun fẹẹ di gomina ipinlẹ Ogun lasiko naa, ki lo de ti ko le ṣe e, nitori pe awọn eeyan yoo fẹ ko tẹsiwaju iṣẹ rere ti baba rẹ n ṣe lati oke wa si isalẹ.

Ni akoko yii ko yẹ ki Seyi ronu ipo gomina naa rara, emi o le ronu bẹẹ, bawo ni aarẹ yoo ṣe maa kọja laaarin ilu, ti awọn araalu yoo si maa pariwo ‘ebi n pa wa’, iwa alainitiju ni, o yẹ ki oju ti Seyi Tinubu ni, ebi n pa awọn araalu ni abẹ iṣakoso baba rẹ, ọrọ ipo gomina lo ba. Ko si oloṣelu to nigbagbọ pe eto idibo to dara wa l’Ekoo.

Bi Ṣeyi Tinubu ranṣẹ pe yin lati wa di igbakeji oun fun ipo gomina lọdun 2027, njẹ ẹ ṣetan lati gba?


Ọrọ wi pe ko si ọrẹ tabi ọta to lọ titi ninu oselu yẹn, ọrọ ati fi ya jẹ mekunnu ni, ọrọ iwa imọtara-ẹni nikan ni. Bi ẹgbẹ oṣelu APC ba sọ pe ki n wa gba tikẹẹti lati dije du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ naa, nko nii lọ, ẹ gbagbe nipa ipo igbakeji, idi ni pe bi mo debẹ, mo maa wa owo lati fi ran awọn akẹkọọ ati olukọ lọwọ. Ibo ni mo si ti fẹẹ ri owo naa kọja Alpha Beta, fun idi eyi, ọjọ keji ni wọn yoo yọ mi nipo, ki wa  ni eredi ti maa fi maa tan ara mi jẹ? Ọpọ owo ni wọn n kojẹ nipinlẹ Ekoo. 

Nko sọ pe bi mo ba de ipo naa, ma maa le awọn eeyan kaakiri o, rara. Ohun ti mo n sọ ni pe o ti lẹ ni ogun ọdun tawọn eeyan ti n gbadun, asiko igbadun si ree, ṣugbọn ko ri bẹẹ. Awọn eeyan n pọ si l’Ekoo lojoojumọ ni, niṣe lo yẹ ka maa wa iṣẹ fun wọn. Niṣe lo yẹ ka wa ọna irolagbara fun wọn, ka lo owo naa fun araalu lọna to yẹ.

Mi o kii ṣe olowo ṣugbọn mi o ni iwa ọkanjua. Iwa ọkanjua lo n jẹ ki awọn ti wọn bu Tinubu tun ma yin lẹyin to ba ti fun wọn lowo. Emi fẹ jẹ gomina ki n si lapa ire ni, iṣakoso asia APC ko si le fun mi ni nnkan ti mo fẹ.

Lasiko idibo 2023, ariwo ‘ebi n pa mi’ ni araalu n pa, pẹlu bi nnkan ṣe ri lasiko yii, njẹ ẹ ro ebi ṣi n pa araalu?


Mo ro pe ọpọ awọn eeyan lo tiẹ ti wa sọ ireti nu patapata, idi ree ti ẹ fi n ri ọpọ awọn eeyan ti wọn n sa kuro ni Naijiria, wọn ti JAPA. Ijọba yii n fi ara ni awọn eeyan, wọn si n binu. Ẹ wo iye ti wọn n ta jaala epo bayii, ọpọ ileeṣẹ ni wọn ti le awọn oṣiṣẹ wọn danu, kii ṣe nitori pe awọn oṣiṣẹ wọn ko le ṣiṣẹ, rara, ṣugbọn nitori pe wọn ko le san owo oṣu mọ ni. Airiṣẹṣe ti wa n pọ si, bẹẹ si ni owo ounjẹ n lọ soke, atiẹ dupẹ pe baagi irẹsi ti n lọ silẹ bayii, ṣugbọn sibẹ, owo naa ṣi pọ. Ebi n pa awọn araalu, ọpọ wọn lo si n binu.

Idibo to n bọ, awọn eeyan yoo jade daadaa, nitori pe oṣelu ti bẹrẹ, gbogbo igba ni awọn oloṣelu n ṣe ipade loriṣiriṣi lori eto idibo 2027. ẹ ko le ri oloṣelu kan to maa rin irin ajo lọ soke okun mọ, igbaradi 2027 ni wọn n ṣe, mo ro pe iyẹn yoo fun awọn ọdọ Naijiria ni igboya lati jade du ipo ati lati dibo.

Awọn ọdọ lawọn oloṣelu n lo lasiko idibo, ki lẹ ri sọrọ awọn agbero?


Nko le pe wọn ni agbero, nitori pe mo ni ọjọ afojusun rere fun wọn Kii ṣe erongba wọn ni lati di agbero, ṣugbọn ipo ti wọn ba ara wọn niyẹn. Oriṣiriṣi ipenija lo gbe wọn de ibi iṣẹ agbero, nitori pe wọn si fẹẹ ṣiṣẹ ni. Nko sọ pe gbogbo wọn ni wọn fẹẹ ṣiṣẹ, awọn kan wa lara wọn to jẹ pe egboogi oloro mimu lo gbe wọn debẹ, a si nilo lati tọju wọn, ka si ṣe idanilẹkọọ fun wọn.

Ti mo ba di gomina l’Ekoo, a maa kọ ileeṣẹ ẹkọṣẹ fun wọn, nibi ti wọn yoo ti maa lọ kọ iṣẹ, iyẹn si gbogbo wọọdu patapata to wa nipinlẹ Eko. Awọn nnkan to yẹ ka maa lo owo wa fun niyẹn. Ounjẹ ọfẹ yoo tun wa nibi ti wọn ti n kọ iṣẹ. Awọn ileeṣẹ to ba tun wa ni wọọdu naa, wọn gbọdọ gba lara awọn eeyan yii sẹnu iṣẹ nigba ti wọn ba pari. Oriṣiriṣi ẹkọ lawọn eeyan le kọ, ti yoo si wulo fun wọn.

Sebi awọn ọdọ orile-ede China ni wọn ṣe gbogbo awọn foonu bii ‘Apple’ ti a n lo yii. Ti a ba kọ awọn eeyan wa, anfaani ijọba naa ni, wọn maa tun maa san owo ori wọn daadaa.

Ki ṣe pe ki a kan ma gba ọwọ ni awọn ọja wa nikan, ki ni a n fi awọn owo naa ṣe? O yẹ ka maa ṣe eto idanilẹkọ fun wọn ni igba gbogbo. Mẹkunnu n san owo ju awọn to n ṣiṣẹ loju mejeeji, ti wọn gba owo oṣu. Iya alata n san owo ori ju oṣiṣẹ banki lọ. Ẹ wo iye owo ti ẹgbẹ awakọ NURTW n pa wọle, ko si seto ilera ọfẹ fun awọn oṣiṣẹ to n pa owo ọhun, awọn ohun to yẹ ka fi owo ṣe niyẹn, kii ṣe ki baba kan jokoo sibikan, ko si maa duro de owo lai ṣiṣẹ kankan.

Pẹlu bi nnkan ṣe ri l’Ekoo lasiko yii, njẹ o ṣee ṣe ki ẹyin ati oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, Jandor ṣiṣẹ papọ lọdun 2027?

Bii baba ni Oloye Bode George ṣe jẹ si mi, ọrẹ baba mi si ni wọn jẹ, ti wọn si jẹ ololufe ipinlẹ Eko naa pẹlu. Baba si jẹ ẹni to n wa ilọsiwaju ipinlẹ Eko. Ọlọrọ ati oludamọran mi ni wọn jẹ pẹlu. Mo sunmọ Jimi Agbaje naa daadaa, nitori pe emi pẹlu ọkan lara awọn ọmọ wọn la jọ jẹ ọrẹ.

Nko fẹẹ sọrọ lori Jide Adediran, ṣugbọn nipa wi pe Labour ati PDP yoo ṣiṣẹ papọ, a wa lẹnu ajọsọ lọwọ lati rii pe a gba Ekoo kuro lọwọ APC.

Ki ni aṣiri to wa ninu fila funfun ti ẹ maa n de ni gbogbo igba, abi ẹyin naa ti darapo mọ awọn oloye onifila funfun l’Ekoo ni?

Rara o, ifẹ ti mo ni si nnkan funfun lo jẹ ki n maa de fila funfun, nitori pe funfun tunmọ si alaafia ati ọwọ. Nko si lara ẹgbẹ oloye onifila funfun. Mo nifẹ nnkan funfun nitori pe o ba ẹmi mi lọ, o si jẹ idanimọ mi, funfun duro fun nnkan mimọ, o si maa n fun mi ni iranti wi pe nko gbọdọ fi ara yi idọti. Oriṣiriṣi lo maa n wu mi lati fi fila mi da.

Iyawo yin, bawo lẹ ṣe pade, ati pe ki lo wu yin lara rẹ?


Fasiti Nottingham to wa ni Amẹrika lemi pẹlu iyawo mi ti pade. Ọdun bii mẹfa la fi ṣe ọrẹ ko to di pe a bẹrẹ sii di ololufẹ, lẹyin igba naa la ṣẹṣẹ ṣegbeyawo. Obinrin to rẹwa ni, ati pe yatọ si ẹwa, o tun jẹ obinrin to ni ọgbọn ati imọ kikun, to si ni imọ ẹkọ bii mẹfa, to si tun jẹ Ọmọwe, bẹẹ naa lo tun jẹ Ọjọgbọn ni fasiti Redeemers to wa nipinlẹ Ọṣun. Iyawo mi jẹ ẹnikan to maa n ni agbekalẹ. Mo nifẹ iru eeyan bẹẹ nitori pe yoo jẹ ki eeyan tete de ibi to n lọ.

Nipa bi awọn ẹbi yin ṣe yi orukọ pada, njẹ ẹyin naa n gbero lati yi orukọ yin pada si Orobiyi?


Rara o. Orukọ mọlẹbi meji ni mo n jẹ papọ, akọkọ ni Rhodes, ẹlẹẹkeji ni Vivour, mejeeji ni mo papọ. A ti ṣe ọpọ nnkan pẹlu orukọ Rhodes-Vivour, bo tilẹ jẹ pe a ko le yi itan pada.

Ki ni erongba yin lati ni agbekalẹ awọn ọmọ ẹgbẹ ni Labour, ati pe ki lẹ n ṣe sọrọ awọn ọdọ ẹgbẹ yii ti wọn ko mọ ju eebu lọ, eyi to n ṣakoba fun ẹgbẹ yin?

Laipẹ yii la ba gbogbo awọn aṣoju obinrin lẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko ṣe ipade, a si ba wọn ṣajọyọ. Ọpọ iforukọsilẹ la n ṣe lati rii pe a n mu awọn eeyan tuntun wọnu ẹgbẹ oṣelu Labour. 

A ti gbajumọ igbesẹ lati mu ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle sinu Labour. Lasiko yii, a ti n mọ pataki nini agbekalẹ ọmọ ẹgbẹ, nitori pe o ṣe pataki. Kii ṣe lati ni ọmọ ẹgbẹ nikan, bi ko ṣe lati ni awọn ojulowo ọmọ ẹgbẹ.

Bo ṣe n ṣẹlẹ ni Labour naa lo n ṣẹlẹ lawọn ẹgbẹ oṣelu bii APC. Nko le gbagbe awọn irọ ti wọn pa mọ mi, eyi ti wọn pin kaakiri ori wasaapu. Nitori orukọ mi, niṣe ni wọn n gbe e kaakiri wi pe ọmọ Igbo ni mi, ti ko si ri bẹẹ. Bi ẹni to fẹran mi tẹlẹ ba gbọ pe ọmọ Igbo ni mi, niṣe ni yoo korira mi loju ẹsẹ, to si jẹ pe ọmọ Yoruba ni mi, ṣugbọn orukọ naa ni wọn n lo lati fi tako mi. Ọlawale Rhodes-Vivour ni orukọ baba mi, bẹẹ naa ni baba-baba mi. Irọ nla ni wọn n pa mọ mi.

Ewo iru irọ to pa mọ emi tọ ni ọmọ ibo ni mi, ni gba to hẹ pe Sanwo-Olu fun rarẹ ki ṣe ọmọ Eko. Kii ṣe emi nikan ni wọn ṣe iru nnkan bẹẹ fun. Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan naa ko le gbagbe irọ ti wọn pa mọ ọn. Ọkan ṣoṣo ni wa, ka maa bu ara wa  ko sọ pe ki owo nnkan wa silẹ. Eebu ko yi nnkan pada, ẹ jẹ ka jokoo, ka si jọ sọ asọyẹpọ. Ẹ jẹ ka dẹkun iwa ibanilorukọjẹ.

Ki lerongba yin lori atunto ti wọn n fẹ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, ati pe taani baba isalẹ yin?

Naijiria nilo atunto, idi ree ti mo fi fẹran agbekalẹ Amọtẹkun. Eyi nko nigbagbọ ninu rẹ ni pe ka pada si ijọba ẹlẹkun-o-jẹkun. Niṣe lo yẹ ka maa n da nnkan ara wa ṣe, kii ṣe pe ka maa reti ohun ti baba kan to jokoo siluu Ibadan maa sọ fun wa lati ṣe, a ti kọja bẹẹ. 

A ko tun nilo lati boju wo ẹyin mọ, bo tilẹ jẹ pe a le maa boju wo ẹyin diẹdiẹ, ṣugbọn kii ṣe bi Aarẹ Tinubu ṣe tun da wa pada si orin ogo Naijiria atijọ, eyi to jẹ pe awọn oyinbo lo kọ ọ.

Ọpọ orin ogo lawọn eeyan ti kọ, eyi ti yoo mu wa tẹsiwaju. A ni lati ro ipinlẹ ati ijọba ibilẹ wa lagbara fun anfaani ọtun. A nilo agbekalẹ ti yoo mu wa tẹsiwaju. Ẹ jẹ ṣamulo awọn agbekalẹ iṣejọba ni Switzerland. A nilo awọn ti yoo jokoo lati ṣe agbeyẹwo ohun ti yoo mu Naijiria tẹsiwaju.  

Ni ti baba isalẹ mi, mo ranti oludije kan to sọ pe Faṣọla ni baba isalẹ ti yoo ṣagbatẹru oun nigba kan, ṣugbọn ti Faṣọla funra rẹ jade sita lati sọ pe ayaworan oun lasan ni oludije naa jẹ. Wọn mọ nnkan to n ṣẹlẹ laarin wọn. 

Emi ko ni baba isalẹ, nitori pe mo nigbagbọ ninu awọn eeyan mi ati Ọlọrun, idi niyẹn ti mo fi le rin laarin ilu lai foya. Iṣẹ mi ko la owo rẹpẹtẹ lọ, agbekalẹ lasan ni. Ọdọ ni mo jẹ, mi o kii ṣe olowo, agbekalẹ mi ni mo n polongo fawọn eeyan, nitori pe mo nigbagbọ ninu wọn.


No comments:

Post a Comment

Pages