Bọde George
Baba wa, njẹ e le sọ fun wa ibi ti ẹgbẹ oṣelu PDP wa lakooko yii?
Gbogbo eeyan naa lo n beere pe nibo ni ẹgbẹ a wa wa lakooko yii, a wa laye, bẹẹ la wa laaye, ko sibikibi ni gbogbo agbaye ti Ọlọrun da a ti kii si aawọ, nitori bẹe bi aawọ ba wa, ẹ jẹ ọmọluabi, ki ẹ jokoo lati yanju ẹ.
Boya ẹ si ẹsẹ gbe ni, ki ẹ sọ fun ara yin, bi ẹ ba le sọ ootọ ọrọ, ẹ ẹ fẹ wo ile ara yin ni. Ki i ṣe pe a ko ni aawọ, aawọ to si wa, afọwọfa ni, ni a ṣe sọ fawọn to gbena gori nile ti wọn sọ pe ko si bawọn ṣe jẹ pe ki wọn ṣe suuru, ọjọ kan ṣa ni wọn darapọ mọ ẹgbẹ, awọn kan ti wa nibẹ, ki ẹyin kan to dee, ẹ ẹ ma ba a jẹ.
Onikaluku a ṣe tiẹ, a lọ, ṣe wọn ri ẹni to wa sile aye yii, ti ko lọ ri.ọsẹ to kọja yii ni ọjọọbi baba Awolọwọ, baba ṣe tiẹ, o lọ,ta lo fẹẹ sọrọ nilẹ Yoruba, ti ko nii mẹnuba wọn.
Iṣẹ tọpọ awọn eeyan jẹ anfaani ẹ lonii, nipase ileewe Awolọwọ ni. A bi ṣe iṣẹ agbẹ la a fọrọ ẹ ni, gbogbo koko ti wọn n ta, gbogbo Timba, awọn igi nla ti wọn ge loko, epo pupa, o tun ni ọkan naa ti baba gbe wa nigba naa, wọn a ni ṣinabolẹ, sunnelbole ni o, awa wa nileewe nigba naa.
Ko sibi ti baba ko ti ṣiṣẹ, ṣe o waa ri lati Ibadan,Western Region, Idi-Oro, Mushin, Fadeyi, gbogbo Ṣomolu, lọọ si Idi-Araba, ibi kan tun wa ti wọn pe ni Ajegunlẹ, waa lọ titi de Warri si Ogbomọṣọ de Oke –Ogun, ni baba ṣisẹ sii.
Ṣugbọn nigba ti Eṣu tọwọ bọ ọ, wahala ọdun 1962, mo wa ni ipele kẹrin nileewe girama, aawọ kekere lo wa Baba ti wa si ijọba apapọ Akintọla lo waa n ṣe olori ẹgbẹ Action Group, aawọ diẹ lo wa to yẹ ki a le pari, amọ tawọn kan tọwọ bọ ọ.
Iru yẹn ni aawọ ta a wa ninu ẹgbẹ wa lakooko yii, taa n kilọ fun wọn pe o ti ṣẹlẹ rii, nitori Western Region, o dabi ilu ti Ọlọrun kan mọ ọ mọ da silẹ ni.
Ṣe ọrọ tileewe ni, tabi ti titi, tabi ile iwosan,awọn to tun wa kawe baba ko fi wọn lọrun silẹ, oriṣiriṣi ipade, a fun wọn niṣẹ, pe ki wọn waa lo iwe ti wọn ka, lẹyin tawọn yẹn ba ṣe e tan, lawọn oloṣelu yoo ṣẹṣẹ waa tẹwọgba, nitori bayii la n ṣe niluu wa, eewọ ibo mii-in ni.
Awon ni yoo ṣẹṣẹ waa jokoo lee lori lati mọ nnkan ti Awolọwọ gbe wa ti yoo ṣe dun laduugbo ti wọn. Western Region lo ni tẹlifiṣan akọkọ ni Afrika,Bi Faranse ṣe tobi too ni, awa ti ni tẹlifiṣan ki wọn to ni. Bẹẹ naa ni papa iṣere Liberty, to wa ni Ibadan.
Mo ranti ọjọ kan ti Hogan Bassey fẹẹ ja ẹṣẹ, ni alẹ, ti wọn tan ina, wọn lawọn kan fẹẹ gba bọọlu, awa wa ni kekere, ṣe ni mo bẹ ẹgbọn mi kan ko mu mi lọ.
Iṣẹ meremere bẹẹ ni Baba ṣe, ẹ jẹ ki a wa pada wa si ọdọ wa, mo sọ pe awọn ẹsin, iṣoro meji ni wọn ri mọlẹ, akọkọ ni ẹlẹyamẹya, kin ni iyẹn ṣe pẹlu ijọba? Ṣe eeyan kan kọ lo wa nilẹ Ibo, Yoruba, Hausa tabi Fulani, Ijaw, ẹlẹran ara ni gbogbo wa.
Ajo ko si le dun bi ẹnikan ko ni, nigba ta a ba jokoo, ṣe lawọn ti wọn lawọn lo ni ẹya to pọju, wọn a wa jokoo, won a ni, awọn lawọn ni, kawọn ti ko to nnkan ma wa woo.
Ṣe o tun waa rIi nigba ti wahala tun bẹrẹ lọdun 1962, ti wọn kọkọ bẹrẹ, ariwo Awolọwọ, hee, nibo lo ti rowo to fi n ṣe gbogbo nnkan to n ṣe, igbimọ gbọdọ dide lati ṣe iwadii ẹ.
Latilẹ nijọba ti n fi sibi, ti wọn fi sọhun, nitori wpn ko jokoo re, awọn eeyan wa kan kigbe titi, ijọba federallism taa n lo nigba naa, ṣe awon to kere ninu ẹya , ko si nibẹ?.
Mo sọ pẹlu idunnu pe Awolọwọ atawọn eeyan ẹ nigba naa woo titi, nitori lara iṣoro taa ni lakooko naa ni pe awọn eya to kere ju, wọn yoo wa ọna won, ilu ko lọ,ọrọ wa a dabi ẹni tan ara ẹ bi Iya Jimọ.
Bi ere, wahala ibo bẹrẹ, ẹ dibo fun wa, ẹ ẹ ko dibo fun wa,Adegbenro lawọn tiẹ, Akintọla naa lawọn tiẹ, ibo ti wọn yi latigba naa, bi wọn ṣe de ile aṣofin, ọpa aṣẹ, ṣe ni wọn kii mọlẹ, bawọn agbẹkọya ṣe bọ sita, ti ogun wẹtiẹ ṣe bẹrẹ.
Ka a to wo ogun abẹle wọle, ohun taa roo pe kekere ni, o waa di nla. Ko silu ti ko faragba, ko pe sigba naa, wọn ki Awolọwọ mọleẹ, wọn fi sẹwọn . Wọn lo fẹẹ ditẹ gbajọba.
Nigba ti wọn kọkọ bẹrẹ, pe a fi kawọn fa baba yii ya, igbimọ Coker, ni wọn fi bẹrẹ lati ṣewadii ibi to ti rowo, nigba ti wọn fa a titi, ko si nnkan to tibẹ jade, ohun ti mo fẹẹ fa jade ni pe Awolọwp ẹkun Rẹmo lo ti wa, nitori ẹkun ni wọn fi n ṣe e nigba naa.
Baba Coker, ẹkun Ẹgba lo ti wa, ki ẹ fi le mọ igba ti abosi ti wa laye, ta a ko fi ṣe arikọgbọn o, mo n sọ awọn itan yii ki awọn ọmọ wa le gbọ, ki wọn le mo ibi ta a wa.
Bi ere, wọn ni Awolọwọ fẹẹ gba ijọba o di ile ẹjọ giga julọ, ta ni adajọ nigba naa, ki i ṣe ibo, bẹẹ ni ki i ṣe Hausa, ọmọ Yoruba ni, Ẹgba ni pẹlu, Ṣowẹmimọ ni.
Awa yii wa nibẹ lọjọ naa ta a lọ woran, bi wọn ṣe da kill and go silẹ niyẹn, bi wọn ṣe jade ninu mọto, ẹrin la a n rin gẹgẹ bi ọmọde, bi wọn ṣe dajọ baba tan ti wọn gbe wọn sinu black maaria, ṣe ni wọn le wa lati kootu wọnu ile itẹ, ki wọn to fi wa silẹ.
Nigba ti Shagari tun de, ibo Ajasin ati Ọmọboriowo,abosi tun wọnu ẹ, nigba naa ko si kọmputa awọn eeyan naa ni wọn yoo jokoo, nigba ti Awolọwọ lọọ si kootu, ti wọn da ẹjọkẹjọ ti wọn fẹẹ da, baba ko sọrọ rara.
Ṣugbọn ti Akurẹ lo tun fa ija, eyi ti mo kọ so 1962, Adegbenro pẹlu Akintọla ni, eleyii Ọmọboriowo ati Ajasin ni. Bi ere, igbajọba lo yanju ẹ, to gbe Shagari kuro nibẹ.
Bi a ṣe wa labẹ ijọba oloogun niyẹn,kin ni a mu bọ, ọjọ ti oloogun ti de, emi naa ti ṣe oloogun ri, bi wọn ṣe n ṣisẹ yatọ si alagbada.
A ni ọga, nnkan kikan to ba sọ pe oun fẹ, ni ko ya a baa fẹẹ o, bi o ba sọ pe o o fẹ, kelegbe ẹ ni o.Dẹmokiiresi jẹ ka mọ pe agbara ijọba, awọn eeyan lo nii.
Ọjọgbọn Iwu, oun ni alaga ajọ eleto idibo tẹlẹ, lo kọkọ sọ fun wa pe a le fi kọmputa fi dibo lọna igbalode, gbogbo awọn alabosi, ajẹun loju onile, ki wọn le bara wọn da sita, ṣugbọn ọrọ Naijiria
Nnkan ta a lo, ta a ra ni owo gọbọi yii, ni Ghana naa lo ti wọn fi dibo, ko si wahala kankan nibẹ , ko si abosi nibẹ o, ohun tawọn eeyan yẹn di lo jade ninu kọmputa.
Amọ ni orileede wa yii, a ti mọ bi wọn ṣe maa n ṣe, ṣebi wọn ni ta a ba ti dibo tan nile idibo, onikaluku a ti mọ, wọn a waa daunloodu ẹ, kọmputa yen lo maa ṣe e, igba taa ma gbọ ti ibo taa di kọja, ṣe ni ọjọgbon to di alaga sọ pe wahala kan waye, onimọ ẹrọ ni mi, ti mo si mọ nipa kọmputa daadaa.
Mo mọ nnkan to n sọ, o ni pe nnkankan daru, to ba a jẹ, awọn to ta maṣiini fun wa sọ pe irọ ni ẹ n pa o, ẹ ẹ ma ba iṣẹ wa jẹ o, ẹyin lẹ pa kọmputa yin o.
Ẹ wo ti iru ibo Edo ti wọn di lakooko yii, akara ti tu si epo, awọn ti wọn gbe wa gẹgẹ bi ẹlẹri sọ pe iwe ti ẹ gbe wa yatọ si ti kọmputa, Ọlọrun a gba wa, o ti waa di alaboorun bayii.
Lara awọn nnkan to n ba ẹgbẹ wa ja niyii, ka ma wọ ibi ti ko yẹ ki wọn ba ọmọluabi, awọn baba yẹn ti wọn ba wa ṣe, wọn ti lọ sile aṣofin nigba ijọba ati ẹlẹẹkeji, wọn rii pe gbogbo ẹ, awọn ẹya to pọ lo wa nibẹ. Iran lawọn ti ko pọ maa n wo nibẹ.
Alex Ekwueme, waa pe gbogbo awọn eeyan pataki ti wọn dijọ ṣe ijọba, ki i ṣe tawọn ẹgbẹ ẹ nikan, o pe Oloye Bọla Ige, Jim Nwobodo, o lọ soke ọya, o pe Rimi, Ciroma, Solomon Lar, o ṣaa pe gbogbo wọn, ti wọn jọ jokoo pọ.
O ni nnkan toun ri ree, bawo la ṣe ma ṣee, to fi jẹ pe ọrọ ẹlẹyamẹya, ko nii ma da nnkan ru, nitori ko sẹni to bẹbẹ lọdọ Ọlorun pe ibi bayii loun fẹẹ lọ.
Bawo lawọn ṣe fẹẹ maa ṣe ti yoo mu ilu dẹrọ, nitori nnkan tawọn n ri yii lo n fọ ilu, nitori bi ẹnikan ba n jẹ, ti ẹnikan ko jẹ.
Wọn waa jokoo, wọn pin Naijiria si ọna mẹfa, North West, North East, North Central,majority, majority, minority, South West, South East, South South. Majority, Majority, Minority.
Wọn waa da awọn ipo mẹfa to ṣe pataki, iyẹn aarẹ, Igbakeji aarẹ, aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, olori ile igbimọ aṣofin, akọwe ijọba apapọ ati alaga ẹgbẹ lapapọ.
Awọn ipo yii lo jẹ pe ọkọọkan ninu ẹ a lọ si ẹkun mẹfẹẹfa yii. Ohun ni wọn fi gunlẹ ni PDP. Nigba taa bẹrẹ ẹ bi ere ni, bi wọn si ṣe to o, nomba 1 ati 2 ko le lọ sibikan naa.
To fi jẹ pe ninu gbogbo yin, ko sẹni ti ko ni ripo mu, ani ajo ko dun, bi ẹnikan ko nii.
Iyẹn ni mo ṣe maa n sọ fawọn eeyan wi pe ẹgbẹ wa PDP, ko siru ẹ nilẹ Naijiria. Nigba ta a bẹrẹ ẹ, bi ere ni wọn tun wa sọ pe bi wọn ṣe to yẹn 1 ati 2, wọón ko ni wa lati ibi kan naa, ki 1 ba lọ si oke ọya, 2 a waa silẹ, ti 3 naa ba lọ soke 4 naa a walẹ bẹẹ naa ni 5 ati 6.
To ba di ọdun mẹjọ ti wọn ti lo, ti wọn fi bọ gbogbo eyi to wa loke yoo wa si isalẹ, eyi to wa ni isale yoo lọ si oke.
Bi wọn ṣe sọ ilu dẹrọ niyẹn, nitori igba akọkọ ree ti ẹ maa ni ẹgbẹ oṣelu to dara, igi iroko ni ẹgbẹ wa, ko si adugbo ti mi o tii lọ fun ipolongo lorileede yii, igba taa si bẹrẹ si nii sọ fawọn eeyan, ti ẹ ba ti ṣetan, ki ẹ tun ṣe bayii.
Njẹ, ki lo wa fa ija ọkanjua, kẹnimani, afawọn, afawọn, ṣe Eko ni Buhari ti wa? Abi Calabar lo ti wa? Nigba to maa lo ọdun mẹjọ tiẹ, ti ẹyin tun sọ pe ẹyin lo kan, ṣe awa yooku wa ta ẹpa ni?
Ofin orileede yii sọ pe ẹnikẹni to ba fẹẹ jade dupo awọn ko diẹ lọwọ o, ṣugbọn ẹgbẹ tiwa, ki alaafia le wa, ti onikaluku yoo fi gbooro, bi awọn baba yẹn ṣe ṣeto ẹ ni.
Atiku waa sọ pe oun fẹẹ dije, a ko si le sọ pe ko maa dije, amọ ofin wa ninu ẹgbẹ wa, bi wọn ṣe n ṣe si wa, ọrọ yẹn di ọjọ mii-ii, abosi to wa nibẹ ni pe ẹnikan to wa lati oke ọya, o lo ọdun mẹjọ, ẹnikan naa tun wa jade latibẹ, o wa loun yoo tun jade.
Ẹnikan to tilu wọn wa waa sọ pe oun atawọn to tẹle oun wa, ki wọn dibo fun Atiku, oṣelu lo ṣe amọ ọjẹlu ni mo pee, abosi ni, inu mi dun ti mo sọ fun un nigba to wa sibi, iyen Tambuwal, ọmọ mi ni, mo sọ fun pe nnkan to ṣe aṣiṣe nla ni.Ko nii tan nibẹ, wọn ti lẹ nọmba mọ ẹ lẹyin.
Pe ṣe ẹni ti eeyan le gbẹkẹle niyii, ọrẹ ẹ nii, ko dara. Adura ni ko ma gba ki Ọlọrun dariji ẹ, ẹru o bodo lemi nibi ti mo ba a de yii.Bi a ṣe fọ ẹgbẹ niyẹn o, ṣe Atiku nikan ni.
Emi tiẹ tun lọ ba alaga apapọ ẹgbẹ wa nile ẹ ni Abuja, nitori ile mi ko jinna sile ẹ, nigba ti nomba 1 ba ti lọ, iwo to je alaga, o tun le gba a, ko le lọ bẹẹ. Alaga gbọdọ wa silẹ, ohun to fa sababi ni.
Ka nigba ti mo lọ ba Ayu, mo wa nile ẹ lati aago mẹsan an alẹ di aago mẹta oru lati juwọ silẹ, mo tun pe Atiku pe ko pe aburo ẹ lati ba a sọrọ, otubantẹ naa ni.
Nigba ti mo beeere pe ki lọwọ Atike pe ki lo fẹẹ fu n Yoruba, esi to fi da pada fun mi ni pe to ba di ẹyin ibo, haba, ẹyin ibo kẹ, ṣe ki n sọ fawọn temi pe o dẹyin ibo ki Atiku to ṣe nnkan fun yin.
Emi naa wa da a pada fun un pe o dẹyin ibo kawa naa to dibo fun un, ko ju bẹẹ lọ.
Eyi Wike naa ni lati binu, nitori ọrẹ ẹ naa da a ni, ile aye, ile asan, iwọ naa mu suuru ara ẹ, mo nigbagbọ pe awọn agbaagba ti dide si.
Gbogbo eyi to n waye nipinlẹ Rivers, mo fẹẹ sọ pe ki olori oko, ko dide nilẹ o, ilu ti ọrọ ti won pin ni oṣooṣu,ibi to ti n jade niyẹn o, ti yanmuyanmu ba a ba le tibi n kọ, ọrọ di suuru.
Ibẹrẹ la mọ, amọ bi yoo pari o, emi sọ fun Aare orileede yii ko dide nilẹ,ko tete pana ẹ, wọn ti fẹẹ bu bẹntiroolu sibẹ, ati ọtun, ati osi wọn ti sọ pe ko si bawọn ko ṣe je.
Bawo ni Boko Haram ṣe bẹrẹ, ṣe a ti rii ṣe titi di akoko yii.ẹsọ nigbin maa n gun igi. Adajọ to sọ pe bi wọn ṣe ṣeto ibo ijọba ibilẹ naa ko dara, o sọ ọ daa, ofin niyẹn, ki lo wa kan ẹ lati maa sọ pe wọn ko gbọdọ fun wọn lowo.
Ṣe awọn oṣiṣẹ ijọba to wa nibẹ, wọn kan waa ta ẹja ni? Bawo ni wọn ṣe fẹẹ jẹun,a bi iru ki lele yi ta a kan yii, iru agbako wo niyii, ti wọn ba sọ fun adajọ naa pe ko nii gbowo oṣu, ṣe inu ẹ a dun?
Ẹ jẹ ka fi ọpọlọ ṣe. Suuru leeere fẹni to ba le ṣe, ko kan mi, ko kan mi o ti debẹ o, awọn ọmọ kan tun de, wọn ni mẹtadinlọgbọn,awọn ọmọ ti wọn lawọn ti lọ, wọn lawọn ko lọ, ki wọn lọ gba wọn pada., ti ko ba le gbogbo kọmiṣanna,haa le kọmiṣanna, awọn kọ lawọn fi wọn fi wọn sibẹ. Eṣu niyẹn o.
Ẹ jẹ ka woo daadaa, Wike ati Fubara, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, kan naa ni gbogbo yin, ẹyin gẹgẹ bi agba ẹgbẹ, igbesẹ wo ni ẹ n gbe e?
Ko si eyi ti mi o ti ṣe, emi kan de lati ilu oyinbo, mo gbọ gbogbo wahala wọn, mo waa beere pe ki lo n ṣẹlẹ, mo ba pe Fubara pe ki lo de laarin iwọ ati ọrẹ ẹ, o rojọ tiẹ, mo ba tun pe alaga BOT, nitori bi ọrọ ba di bayii, awọn agbaagba gbọdọ da si, mo ni ko jẹ ka lọ lati yanju ẹ.
Loootọ Olodumare ki i sọkalẹ, eeyan naa lo n lo, ọmoọ ko sọ pe oun fẹẹ ṣe gomina, oga ẹ lo sọ pe oun lo maa ṣe e. Mo waa beere pe ki lo wa fa aawọ, o ni bi ọga oun ṣe de Abuja, toun ba gbe ipinnu tabi gbe igbese, toun kọwọ bọwe, o ni eebu ni wọn bu oun.
Mo tun bẹ olori oko lẹẹkan si, ko dide nilẹ, ko wọ aṣọ ẹtu, o to gẹ ati ọtun, ati osi ki wọn dakẹ ẹnu wọn, ki wọn jẹ ki alaafia jọba.
Baba, o ṣee ṣe ki Aarẹ da wọn lohun pe ṣebi oun loun kọkọ ba wọn da si ọrọ naa, nigba ti wọn ko tii gbọ si oun lẹnu n kọ?.
Haa, nigba ti ogun abẹle bẹrẹ ni Western Region ni 1962, ṣebi Baba wa, Tafawa Balewa ni aarẹ, mo ranti pe nigba to bẹrẹ wọn tun lọ mu Dokita Majẹkodunmi, lati ṣe alakoso ni Western Region, wọn tun bu ina si, n jẹ o daa duro, nigba to fi di wuruwuru 1962, nigba to di 1966 januari, tawọn ṣoja gba jọba, ẹnu ẹ la si wa di oṣu keje, tawọn oloogun tun doju ija kọ ara wọn, iyẹn la ba lọ titi ti Shagari fi de, ti wọn dibo, iyẹn ni Awolọwọ sọ pe ibo ti wọn di abosi ni ti wọn lọ sile ẹjo, lara ẹ ni Ọmọboriwo ati Ajasin tun fi wọ ọ, oun naa ni wọn tun fa tawọn oloogun fi gba . Ko sẹni to ni ibẹru Ọlọrun to le sọ pe ki oloogun gbajọba, nitori ba wa ṣe n ṣe kọ ni alagbada n ṣe.
Nitori lọdọ ti wa, ofin wa, to ba si ti ru ofin, ẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo ṣedajọ é, ko si ọrọ ẹbẹ nibẹ, ọga kan si la ni. Ara abosi ta a sọ pe awọn oloogun gbe fun wa, ilu yii ko le lọ siwaju, gbogbo kan bayii, aarẹ ni, gbogbo awọn ọmọ to dibo, ibẹ lo yẹ ki agbara wa.
Eko ta a si n sọrọ yii nigba ti aarẹ yoo dahun, o sọ pe, ‘’Emi ni mo ni ẹgbẹ’’ haa, mo kọkọ beeere pe asisọ ọrọ, ṣe okoowo aladaani ni APC, wọn ki i sẹgbẹ, wọn ko ni gbongbo tawọn ni, awọn abosi ti wọn se ni a si n ja ija ẹ, Ọlọrun a kọ wa mọ ọn ṣe.
Lẹnu ọjo mẹta yii ni Jandor sọ sita pe oun ti kuro ninu egbe oṣelu PDP, kin ni ẹ ri sii?
Jandor, atawọn ọmọ mi ki i ṣẹgbe ẹ, ki lo mọ nipa oṣelu, ọjọ wo lo de ẹgbe yii, bayii la n ṣe nile e wa eewọ ibo mii-ii ni, ati pe agba kii wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ.
Nigba to de, mi o nii darukọ ẹni to fi ranṣẹ si wa, bi a ṣe gba a niyẹn, a ko yẹ wo rara, efin niwa,ko ṣe boo mọlẹ, ómọ to ba a jade, Gbadebọ, Baba ẹ ati emi, a jọ wa nileewe, ọre mi ni.
Mo pe wọn Gbadebọ sọ pe ọmọ ọdun mọkandinlogoji loun nigba naa, Jandor loun jẹ ẹni ọdun marun-un dinlaadọta, nitori ibi to ti wa, ati ẹni to muu wa, o si dobalẹ ni ọfiisi mi nibi bayii,.
Ọjọ ti wọn yọju sibi gẹgẹ bi awa ṣe maa n ṣe, ko si nnkan to jẹ pe baba sọ pe awọn agba ni o, gbogbo awọn oludije, ta lo ṣe daadaa ju, Gbadebọ ni, mo ti bẹ awọn eeyan pe ki wọn da si mi lara.
A ni lọjọ ti wọn wa sibi gbogbo awọn agbaagba ni wọn sọ pe wọn ko le fi iku we oorun. Ko to ọjọ meji lẹyin ni Faṣọla, gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, de lati Abuja, lo ba lọ sori tẹlifiṣan, lawọn eeyan ba ni baba, ẹ gbọ nnkan ti o n sọ ọ.
O ni ayaworan oun lasan lawa fẹẹ fi ṣe gomina, mo yanu pe kin ni ọkunrin yii sọ, ọjọ ti wọn maa ṣe pamari, iyawo mi lo pe mi latibẹ pe ṣe ba ṣe sọ ni ka ṣe ṣe o, ki Gbadebọ ma dibo, o ni bẹẹ ṣe sọ ni o ṣe ri o.
Iru ẹ ko nii sẹlẹ mọ, iwo wa sọ pe awọn kan ko dibo fun ẹ, ile taa ba fi itọ kọ, iri ni yoo woo. Iro ti pọju. A fi bo ṣe de pada to sọ fun mi pe ki Madam Derele to ku, lo ti sọ foun pe koun lọ mu ọmọ kan lati Ikorodu lati fi ṣe igbakeji, mo ni ki lo n sọ, ṣe o ba mi sọ yẹn tẹlẹ, bi mo ṣe ni ko jade kuro ni ọfiisi mi, pe ko ma wa, emi lo n tan jẹ.
Gbogbo awọn eeyan to fi de oke ninu ẹgbẹ lo ti mọ iru eeyan to jẹ, lo ba lọ bawọn ni INEC, ko si itu ti ko pa, ni wọn ba pe mi pe awọn mọkanlelogun ninu awọn ọmọ ile igbimọ lawọn ko mọ ibi ti wọn ti jade o. Wọn lawọn ko si nibẹ.
Lori ọrọ Gbadebọ, n jẹ o ṣee ṣe ki ẹ gba a pada sinu ẹgbẹ?
O ti wa sibi, to ba fẹẹ pada o le pada, to ba ṣe wuu lo ṣe maa ṣe, ki i ṣe ọmọde mọ, ibi to ba wu lo le lọ.
Njẹ anfaani wa to ba fẹẹ pada si PDP?
A ni a ti fi ti Jandor ṣe arikọgbọn, ẹnikẹni to ba loun fẹẹ dibo l’Ẹkoo ni akoko yii, nitori a ti ri gbogbo iwa jagbajagba, ti ẹnikan yoo ṣadeede dide, ti wọn yoo maa pariwo pe awọn lawọn mọ igba ati awo. Ki onikaluku lọ di ọmu iya ẹ mu lakooko yii.
Iwo to ba fẹẹ bọ sita, bọ sita jẹ kawọn eeyan mọ ẹ, ti wọn ba fẹ ẹ wọn a sọ, emi ti bebe lori ọrọ Jandor.
To ba fẹẹ pada wa n kọ?
A lọ to ni o, ẹnikẹni to ba fẹ wa yoo lọ to ni.
Ọrọ ile igbimọ aṣofin Eko, ẹ ẹ ti mẹnuba diẹ, o jẹ nnkan to ba ọpọ awọnn eeyan ninu jẹ pupọ, ohun tawọn kan sọ ni pe oṣelu lo waye, n jẹ a le pe bẹẹ?
Ọjẹlu ni ki i ṣe oṣelu, nigba ti gbogbo wọn bẹrẹ, ti wọn lọ sọtun, lọ si osi, baba isalẹ wọn lo yan wọn.
Ta ni ẹ n sọ?
Olori oko, Bọla Tinubu ni, o gbọ nnkan ti wọn lo sọ ni, ẹgbẹ oṣelu mi ni, ti mo di mu, awọn to n sọrọ, ẹnu wo ni wọn ni, oun kọ lo yan wọn sibẹ.Ni mo ṣe sọ pe ẹgbẹ ti wa yatọ si wọn. Igi iroko ni wa. Wọn ko le ṣe ipinnu laiṣẹ pe wọn jẹ ki ẹni to yan wọn sibẹ mọ nipa ẹ.Nnkan temi sọ ni pe ki awọn araalu la eti wọn lakooko yii, ki wọn fi gbọran, ṣe bo ṣe yẹ ki Eko ri niyii, ẹ ẹ wa ni ki Sanwo-Olu sọrọ, ki lo fẹẹ sọ.
Ẹ eẹ wo awọn ọmọ yen, mẹrindinlogoji laarin awọn mẹrin, ẹsun ti wọn ni wọn fi kan-an, n jẹ wọn jẹ ko dahun ẹ?. Ẹ tun wo abosi to n lọ nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, nipa ọmp yẹn Akpoti, ọmọ ẹgbẹ PDP ni, wọn fi ẹsun kan olori wọn, haba, o yẹ ki Akpabio ronu ẹyin pla, ọmọ ẹgbẹ mi ni obinrin yẹn o. Abosi ni o. Aa lẹyin o.
Ninu ọrọ Gbedebo lo ti sọ pe asiko to, lati gbakoso Eko, awọn ko gba ajeji laaye, n jẹ ẹ ṣetan bayii?
Ti ọrp ba delẹ bayii, ka fi suuru wo, awọn ipinlẹ meji lo wa ni orileede wa yii ti wọn fa ajeji mọra, Eko ati Kano, ni Eko, wọn bi oju ko ba ti igbẹti, oju ko le ti Eko ile.
No comments:
Post a Comment