Ẹ ṣọra fawọn ayederu to n ta ilẹ onilẹ ni Ketu-Ẹpẹ-Ọmọọba Adefowora - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 10 March 2025

Ẹ ṣọra fawọn ayederu to n ta ilẹ onilẹ ni Ketu-Ẹpẹ-Ọmọọba Adefowora



Ọmọọba Babajide Adekọya Adefowora ti kilọ fawọn araalu ẹ ni Ketu-Ẹpẹ lati sọra fawọn ayederu ti wọn ta ilẹ niluu naa, nitori ki wọn ma gba wọn.

Ninu alaye to ṣe lakooko to n ba oniroyin sọrọ lo tun ti fikun pe titi di akoko yii ko tii si ọba niluu ọhun, ki wọn ma ṣe tẹti sawọn to le maa pe ara wọn ni ọba.

 O fikun ọrọ ẹ pe ohun gbọ pe awọn kan ti wọn jọ dupo ọba fẹẹ lo ayederu iwe ẹri waa sile ẹjọ giga to waa niluu Ẹpẹ lori ẹjọ to n pe lori ọrọ ọlọbade ilu naa.

Nitori idi eyi lo ṣe rọ adajọ to n gbẹjọ lati ṣayẹwo awọn iwe ti wọn ba fi silẹ finnifinni, ki wọn si rii pe wọn fiya to ba tọ ba tọ jẹ ẹnikẹni to ba huwa bẹẹ.

Bakan naa lo mu da awọn eeyan ilu Ketu-Ẹpẹ loju pe ki wọn fọksnbalẹ nitori pe laipẹ yii okodoro yoo foju han, ti wọn yoo si de ade foun gẹgẹ bi ọba ilu naa.

Lati ọdun 2022, ni Babajide Adefowora ti gbe Akimu Oluwo lọ sile ẹjọ giga kan niluu Ẹpẹ, nibi to ti n rawọ ẹbẹ si Adajọ to n gbẹjọ naa lati paṣe pe ki Akimu Oluwo atawọn ọmọlẹyin ẹ ye pe ara wọn ni ọba ilu naa mọ ati pe wọn ko wa lati idile ọba.

Wọn sọ pe idile kan ṣoṣo iyẹn Ọṣọkeji Atẹsinmara nikan ṣoṣo lo n jọba niluu naa, eyi ti Akimu Oluwo, ki i ṣe ara wọn. A gbọ pe igbẹjọ naa si n lọ lọwọ titi di akoko yii.

Bakan naa, awọn ọmọ bibi ilu ọhun atawọn ti wọn ki i ṣe ọmọ ilu naa amọ ti wọn n gbe ilu yii tun ti fatilẹyin wọn han si Babajide Adekọya Adefowora, ẹni ti wọn faa kalẹ gẹgẹ bi ọba ilu yii pe oun lawọn n fẹ nipo ọhun.

Gẹgẹ bi ọrọ ti wọn ba oniroyin wa sọ ni wọn ti ṣapejuwe ẹ gẹgẹ alaanu to ko eeyan mọra ati pe latilẹ lo ti maa n ran awọn araalu lọwọ.

Wọn ni bo ṣe n dide iranlọwọ fawọn nipa ẹkọ bẹẹ lo mu eto ilera wọn lọkunkundun, ti ko si n fẹẹ ki iya jẹ awọn.

Wọn ni idi eyi lawọn ṣe duro ti gbagbagbaa lati rii pe o gba ade gẹgẹ bi Alaketu tilu Ẹpẹ, tawọn si nigbagbọ ninu Ọlọrun pe laipẹ ni ayẹyẹ igbade ọhun yoo waye.

No comments:

Post a Comment

Pages