Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nileeṣẹ aṣọbode nipinlẹ Ogun, gbe owo nla kan iyẹn miliọnu mẹtadinlogun naira fun ajọ to n ri si ẹsun iwa ibajẹ iyẹn EFCC le wọn lọwọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, owo ọhun ni wọn lawọn oṣiṣẹ fura si pe ẹnikan ko sinu apo to si gbe pamọ, koda wọn lẹni to ni owo naa ti na papa bora.
Mohammed Shuaib, to jẹ ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun lo gbe owo naa Mosses Oguzi, tiyẹn jẹ adari ẹka to n ṣe iwadii, to tun jẹ igbakeji ọga EFCC ni ẹkun keji, niluu Eko.
O sọ pe iṣẹ takuntakun tawọn ọmọọṣẹ oun ṣe lo jẹ ki wọn ri owo naa. O ni gẹgẹ bi oun ṣe sọ pe ẹni to ni owo ọhun ti salọ, amọ sibẹ, iṣẹ iwadii ti n lọ lọwọ nipa bi ọwọ yoo ṣe tẹ ẹ.
O fikun ọrọ ẹ pe”A ṣiṣẹ pẹlu ofin orileede yii, eyi to sọ pe ẹnikẹni to ba gbe owo to ba kọja dọla mẹwaa ni wọn gbọdọ fihan ajọ ẹṣọ aṣobode, ko to di pe wọn yoo gbe kọja lẹnu bode.
Sugbọn nigba ti ẹni to ni owo naa ko ti fi han ajọ wa iru ẹni bẹe ti ṣe si ofin niyẹn”.
O ṣalaye siwaju pe ” Owo ti ko to miliọnu mẹwaa dọla nikan ni anfaani wa fun lati gbe kọja amọ eyi to ba ti pe miliọnu mẹwaa tabi to le si owo naa ni o ti di ofin to si yẹ kiru ẹni bẹe fihan lẹnu bode”.
Shuaibu waa gboriyin fawon oṣiṣẹ to ri owo naa, o si fi dawọn loju pe oun ko ni figba kankan gba awọn to ma n ṣe fayawọ owo laaye lẹnubode Idiroko.
Nigba to n tẹwọ gba owo naa, Ọgbeni Oguzi Moses to tewogba owo naa lowo kontirola Shuaibu gboriyin fun ajọ ẹṣọ aṣobode fun iṣẹ takuntakun ti won ṣe lati ri iru owo bẹe.
O tẹsiwaju pe ajọ EFCC ma lọ ṣayewo owo naa lati mọ boya ojulowo ni tabi ayederu.
No comments:
Post a Comment