Ilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun lo ti sọrọ naa nibi idanilekọo ọlọjọ marun-un ti wọn ṣe, eyi to bẹrẹ lana- an, ọjọ Aje, Mọnde.
Minisita ọhun to fi eto naa lelẹ nipinlẹ Ogun,lẹyin Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti kọkọ ṣagbekalẹ ẹ, eyi ti wọn pe ni MIAMII. O ni eto naa ṣe pataki fun ọjọ iwaju orileede wa iyẹn ti a ba fẹe fopin si bawọn alaboyun atawọn ọmọde ṣe n ku iku aitọjọ.
O tun ṣalaye siwaju pe yoo jẹ ki itọju to peye waa fawọn alaboyun atawọn ọmọde ti yoo si jẹ ki wọn tubọ maa dagbasoke.
Mohammed fikun ọrọ ẹ pe ijọba apapọ ko le nikan da nnkan ṣe, o lo da lori bi iru ajọṣepọ ti wọn ṣe yii ba n waye, ti wọn yoo jọ maa jiroro lori bi wọn ṣe le ṣiṣẹ pọ pẹlu araalu, to fi mọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ, eyi nikan lo ni o le mu aṣeyọri to ni idagbasoke waye.
O waa mu da gbogbo awọn olukopa loju pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lorileede, Abuja nikan ko le yanju iṣoro lori iya atọmọ iku aitọjọ yii, bi ko ṣe ki gbogbo wọn jọ ‘ṣiṣẹ pọ, ki gbogbo ẹ le yọri si bi wọn ṣe n fẹẹ.
Minisita waa ṣalaye pe awọn ohun elo bii ẹedẹgbẹrin le mẹrinlelaadọrin ti yoo wulo lawọn ile eto ilera lawọn ti pin kaakiri orileede yii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn ohun elo yii lawọn ti pin de ileeṣẹ to ri si idojutofo ilera lorileede yii iyẹn Nigeria Health Insurance Scheme (NHIA),eyi to ni wọn yoo fi tete pese ilera pajawiri lọfẹẹ.
Ninu ọrọ Gomina Dapọ Abiọdun,tipinlẹ Ogun,ẹni ti igbakeji ẹ, Onimọ-ẹrọ Noimot Salako-Oyedele, ṣoju fun, lo ti sọ pe ọpọ owo ni isakoso oun ti na lori ẹka eto ilera, koda tawọn tun ṣafikun ninu eto isuna ọdun yii.
Bẹẹ lo ni gbogbo igba lawọn rii daju pe awọn ibi eto ilera to wa nipinlẹ Ogun bojumu, ti wọn si gba awọn oṣiṣẹ to dangajia sibẹ pẹlu.
Ko to to akoko yii ni kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker
Earlier in her welcome address, the Commissioner for Health, Dr. Tomi Coker, ti mu sọ pe ohun ti eto ọhun da lori ni pe ko ni si obinrin kankan ti yoo ku lakooko ti wọn ba wa ninu oyun mọ.
Bẹẹ lo fikun un pe agbekalẹ eto ọhun yoo tun ran awọn ẹka eto ilera lọwọ lati pese imayedẹrun atawọn nnkan ti yoo wulo fun iya ati ọmọ tuntun lati gba ẹmi wọn la.
No comments:
Post a Comment