- BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 29 March 2025


 Owo ijọba íbìlẹ ti Sanwo-Olu  n fun wa lo  jẹ  ki  iṣè akanṣe rorun fun mi lati ṣe- Alaga ìjọba ibilẹ̀ Mushin

 

Lara awọn ijọba ibilẹ to ti pẹ lorileede Naijiria nijọba ibilẹ Mushin wa, awọn alaga to ti jẹ tẹlẹ nibẹ si ṣe daadaa ṣugbọn, ara ọtọ ni ti Ọnarebu Emmanuel Bamigboye to n ṣakoso kansu naa lọwọlọwọ, laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn akọroyin lede Yoruba 'League of Yoruba Media Practioners' ṣabewo si i lati mọ ibiti oṣelu de duro ni Mushin ati lorileede Naijiria. Ẹ ka nnkan ti alaga ba wọn sọ.

Ẹ jẹ ka kọkọ sọrọ lori ominira ijọba ibilẹ,kin ni ero yin lori ẹ

Ko si alaga ibilẹ kankan tinu rẹ ko ni i dun sọrọ naa, ka dupẹ lọwọ aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu fun igbesẹ akin to gbe,aarẹ naa lo mọ idi to fi gbe igbesẹ naa nitoripe ki orileede to le tẹsiwaju; o gbọdọ bẹrẹ lati ijọba ibilẹ. Ko si oloṣelu to le di ipo kankan mu bi ko ba wa lati ijọba ibilẹ kọkan toripe wọn maa beere pe wọọdu wo lo ti wa.
Nnkan ti aarẹ ro ni pe, bi owo ba de isalẹ lọdọ alaga gbogbo agbegbe ni idagbasoke yoo de ba.
 
Ẹ jẹ ki n fi asiko yii dupẹ lọwọ gọmina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, bo ṣe ma n jẹ kowo wa tete dọwọ wa iyẹn lo jẹ ki awa alaga ibilẹ naa le ṣiṣẹ akanṣe lasiko. Apẹẹrẹ rere ni iru emi yii,mo ti ṣe ojuna mọto to le laaadọrun un atawọn iṣẹ akanṣe aritọkasi miiran nitoripe owo naa n tete bọ si wa lọwọ.

Irinajo oṣelu, bawo lọkọ ṣe gbe yin sori aga ọga ijọba ibilẹ

Mo ni iriri kan nigba ti mo wa lọmọde ti mo fi pinnu lati depo ti mo wa yii, ohun to ṣẹlẹ ni pe, lọjọ kan ni awọn olukọ wa ko wa lọ sibi kan layajọ awọn ọmọde,ṣe ni wọn sa wa sinu oorun lọjọ yẹn. Wọn ni ẹni ta n duro ko ni ì pe de, ṣugbọn a tun duro fun wakati mẹfa mi-in iyẹn lo mu mi beere lọwọ ẹgbọn mi kan pe ta ni ẹni ti wọn sa wa soorun toriẹ, lo ba ni alaga kansu ni ko si pẹ tẹni naa de, mo ri i bi wọn ṣe n bu ọla fun un. Lojuẹsẹ ni mo pinnu lọjọ yẹn pe emi naa ma di alaga kansu lọjọ kan. 

Bo ti lẹ jẹpe, ọkan lara àwọn ọmọ ileegbimọ aṣofin Eko ni mo fẹẹ ṣe tẹlẹ ṣugbọn ipo alaga lo pada bọ si mi lọwọ. Irin ajo yẹn gun diẹ, ṣugbọn ẹ jẹ ki n dupẹ lọwọ baba wa Bọla Tinubu ati adari wa ni Mushin ati Odi-Olowo,Sẹnetọ Ganiu Ọlanrewaju Solomon ti wọn fa mi lọwọ soke lagbo oṣelu.

Ọmọ lile lawọn ọmọ Mushin,bawo ni ẹ ṣe n kapaa wọn atipe kin ni aṣeyọri yin lori ọrọ aabo

Awọn ọmọ lile gan o ja mọ toripe ọwọ ọlọpaa maa tẹ ọmọ to ba wu iwa ko tọ ọ, a n ṣiṣẹ pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ paapaa julọ nitori awọn ọmọ alapamaṣiṣẹ ti wọn ma n kan ina lu ile onile loru toripe wọn fẹẹ ji dukia wọn. 

Mo ṣe ipade pẹlu awọn obi wọn ki wọn le ba awọn ọmọ wọn sọrọ ko ma lọọ di pe awọn ni wọn maa bẹrẹ si i bẹbẹ kiri bawọn ọmọ wọn ba wa ni ahamọ.
Nigba tọwọ tẹ awọn olori wọn awọn ọmọ ẹyin kari bọnu ṣugbọn, Ọlọrun naa ni ka fọpẹ fun.

Awọn eeyan mọ abuda Mushin mọ ọja latara oriki wọn 'Ọmọ onimushin ajina,onimushin anadoru', ki ni akitiyan yin lati sọ ọja Mushin di ilu mọ ọn ka lagbaaye

Ilu mọ ọn ka ni Ọja Ladipọ ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ ati ọja Dalekọ ti wọn ti n ta irẹsi,ko si ibiti wọn ki i ti wa n na ọja mejeeji yii, awọn eeyan n wa lati ilẹ Kutọnu,Togo ati Ghana lati wa a ra ẹya ara ọkọ ni Ladipọ. 
A ti n gbe awọn igbesẹ kan lati ṣe awọn nnkan igbalode sinu awọn ọja yẹn ki wọn le ba igba mu.

Ọwọ to ba dilẹ ni eṣu n bẹ lọwẹ, kin lawọn eto irolagbara yin fawọn ọdọ

Ilu ti ko ba ṣiro tawọn ọdọ mọ nnkan ti wọn n ṣe ko le ni ilọsiwaju toripe
bi wọn ba ṣe n gbiyanju ati fa a soke lawọn ọdọ a ma fa a walẹ toripe wọn raaye ṣugbọn tọwọ ọdọ ba di ṣe lo ma gbajumọṣẹ to si maa ronu ilọsiwaju.

A ni eto irolagbara oriṣiriṣii fawọn ọdọ. O di dandan ka tọju awọn ọjọ ọla wa toripe awọn ni Ogo Mushin.

A ṣeto ẹkọṣẹ loriṣiriṣii pẹlu ṣiṣeranwọ irinṣẹ lẹyinti wọn ba kọṣẹyege tan, eto iranlọwọ wa fawọn olokoowo, bakan naa ni ẹkọ ọfẹẹ wa fun ọdọ to ba ṣe daadaa julọ ninu idanwo aṣekagba lati jẹ moriya fawọn miiran ki wọn le ṣe daadaa lẹnu ẹkọ wọn,a tun ma n sanwo ajẹmọnu fawọn ọmọ wa ti wọn wa nileewe giga gẹgẹ bi iranwọ,a n ṣe e lati jẹ ki wọn le kọju si ẹkọ wọn ni.

Igbakeji yin n kọ, kin ni ibaṣepọ to wa laarin yin

Ajọṣepọ to dan mọran wa laarin emi ati igbakeji mi, Ọnarebu Tunbọsun Aruwe koda bi mo ṣe n ba yin sọrọ bayii,o wa ni Umurah to lọọ́ gbadura fun gbogbo wa. 

Igbagbọ temi ni pe ka funra wa laaye lati ọgbọn inu ti Ọlọrun wa kaye le roju.
Ko si ibi tori o le gbeeyan de, ọmọẹyin le di ọga ẹ lọla, iwa taa ba wu sira wa lo maa  sọrọ fun wa lọjọ iwaju. Lọdun ti wọn bura fun Sẹnetọ Ganiyu Ọlanrewaju Solomon gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Mushin, okeere nimo ti n wo
o timo n sọ ninu ọkan mi pe 'Ọkunrin yii raye wa ni tiẹ' .

Emi naa n fẹ oriire fawọn ọmọ mi, bẹẹni mi o gbadura ki ẹnikẹni di wọn lọwọ tori naa emi o le di igbakeji mi lọwọ o toripe emi naa ti wa nipo yẹn ri, irẹpọ wa laaarin wa.

Pẹlu iwa lile tawọn eeyan  mọ ọmọ Mushin si n jẹ ẹ tiẹ le fọwọ sọya loke okun pe ọmọ Mushin ni yìn?

Ko si ibi ti mo lọ ti mi o ki n jẹ ki wọn mọ pe ọmọ Mushin ni mi. Nigba kan ni mo lọ sibi eto kan niluu London, bi mo ṣe sọ pe ọmọ Mushin ni mi bayii lawọn eeyan bẹrẹ si i patẹwọ,inu wọn dun bi mo ṣe ki oriki Mushin ti mo tun sọ itan iṣẹdalẹ rẹ inu gbogbo wọn dun debii pe wọn bẹrẹ si í darukọ awọn adugbo ti wọn mọ ni Mushin. Ẹ wo,ko si ibi ti mo le wa ti mi o ni jẹ ki wọn mọ pe ọmọ Mushin ni mi toripe ilu to ṣe e mu yangan ni.

Ilu Mushin ni awọn oloṣelu ma n peju si nigbayẹn, awọn baba Jakande, baba Solomon atawọn eekan oloṣelu nigba yẹn. Mushin naa la ti n ṣepade lasiko ti
 aarẹ orileede yii,Aṣiwaju Bọla Tinubu fẹ jẹ gomina Eko nigbayẹn. Ko si oludije dupo gomina l'Ekoo to maa ni ti Mushin bawo nitori ibo ti wọn ma ri ni
 Mushin ko ṣe e foju parẹ koda awọn elere to ba fẹ lokiki Mushin ni wọn ma wa bawọn ọmọ Mushin ba ti tẹwọ gba wọn,gbogbo agbaaye lo tẹwọ gba wọn niyẹn,ojulowo ọmọ Mushin ni mi o.

Awọn iṣẹ akanṣe wo lawọn araalu ma fi ranti Ọnarebu Bamigboye

Ki n kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri awọn iṣẹ akanṣe to waye lasiko iṣakoso mi, lakọọkọ naa bawọn eeyan ba n rin awọn ojuna mọto ti mo ṣe, wọn o ni gbagbe mi,a ṣiṣẹ lori ojuna mọto atawọn opopona ladugbo bii aadọrun, a ṣe atunṣe ati atunkọ awọn yaara ikawee lawọn ileewe wa, eto ironilagbara loorekoore, pi pese awọn irinṣẹ ayẹwo ilera sawọn ileewosan alabọọde ati idanilẹkọọ fawọn eleto ilera.

Lara iṣe ti iṣakoso mi ṣe ni ṣiṣe eto irolagbara fawọn ọdọ, iranlọwọ fawọn oniṣowo,owo ajẹmọnu fawọn ọmọ ileewe giga,eto ẹkọ ọfẹẹ, idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ kansu nilẹ yii ati loke okun ati bẹẹbẹẹ lọ

No comments:

Post a Comment

Pages