Adijedupo gomina nipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oselu labour party ni ọdun 2023 Gbadebo Rhodes-Vivour ti bu ẹnu atẹ lu iṣakoso gomina Babajide Sanwo-Olu, o ni, pẹlu ogunlọgọ owo Gross Domestic Product ti o igba o le ni aadota bilionu naira, iyen 259bn, ti ìjọba ipinlẹ Eko n ri, ko ye ki ilu Eko wa bo ti ṣe wa yẹn.
Gbadebo salaye pe inu iṣẹ ohun iya ni ọpọlọpọ ara ati ọmọ ipinlẹ Eko wa pẹlu aduru owo to n wọlé si apo ìjọba ipinlẹ naa.
O ni, ohun ti oju awọn ara ilu Eko n ri ko fi ara pẹ owo ti o n wọle sinu apo ipinlẹ naa, o wa ni o yẹ ki iṣakoso Sanwo-Olu ṣe daadaa ju ohun to ṣe yii lọ.
Ni ko pẹ yii nibi ifilọlẹ eto Lagos Economic Development Update (LEDU) ti ọdun 2025 ni wọn ti sọ pe GDP ipinlẹ naa ti to $259bn.
Bakan naa ni ipinlẹ Eko tun jẹ ipinlẹ ti okowo rẹ daraju ni ile Afrika lẹyin ti wọn ba ti mu Cairo to wa ni ilẹ Egypt.
Gbadebo ni pẹlu owo yẹn, ibiti ipinlẹ Eko yẹ ko wa ko ni o wa yii, oni owo na ko han lara idagbasoke ilu Eko ati ninu eto ọrọ aje ipinlẹ naa rara.
Gbadebo ni owo ile ilu Eko, ọwọn gogo ni bi oju ẹja, ati gbe ilu naa gan ko rọrun, koda koto rẹ ni otun ati osi opopona yii, ki wa ni iwuri awọn.
Siwaju si, Gbadebo ni eto abo gan tun mẹyẹ, gbogbo ọna lo dọti lọtun losi yii, awọn si ṣe ajọyọ.
Gbadebo salaye oun ti awọn onile ilu Eko nfi oju awọn ayale gbe ri ti ìjọba ipinlẹ naa ko si ri ikankan ṣe si.
O ni, lotitọ ohun iyi ni pe GDP wa ni $259 biliọnu sugbọn ki wa ni ka ti gbọ pe ko wọn lara awọn olugbe ilu naa.
Gbadebo ni owo oun ko bọ sita ko si ran eto ọrọ aje lọwọ, oni ọwọ awọn aṣayan ni owo naa wa wọn wa ni ki awọn ma ṣe ajọyọ.
O ni, titi di igba ti iya ko ba jẹ mekunnu mọ, ti ọmọ ẹru ba ṣe bi ọba, ti oúnjẹ ba di ọpọ, ti owo ile kuro nj ọwọn gogo, ti gbogbo ikan lọ etoleto, igba yii gan ni oun ṣe le yọ pe ilu Eko n gboro.
Gbadebo rọ awọn eniyan pe ki wọn ni arojinlẹ dada lori eto idibo to n bọ yii.
No comments:
Post a Comment