Gbogbo eto lo ti to fun ayẹyẹ iwuye nla ti oludije gomina labe ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhodes- Vivour fẹẹ ṣe.
Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, tii ṣe ọjọ kejila, oṣu kẹrin ọdun ni ọkunrin naa yoo wuye Ọbalẹfun, Aṣoju Alaafia tijọ Oloriṣa parapọ.
Ayẹyẹ ọhun ni yoo waye ni 'Ayabot Hotel and Events Centre', to wa lona Ado Odo, Badagry, nipinlẹ Eko.
Awọn ipa ribiribi ti wọn ni ọkunrin naa ti ko fun idagbasoke aṣa ati iṣe, bẹẹ ni wọn ni ki i fọrọ iṣeṣe ṣere ati pe wọn lo tọ lari fi jẹ aṣoju rere.
Ọpọ awọn eeyan jakanjakan ni wọn n reti lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment